Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Nígbà tí Sátánì sọ fún Éfà pé kò ní kú tó bá jẹ nínú igi ìmọ̀ rere àti búburú, ṣé ohun tó ń sọ fún un ni pé ọkàn rẹ̀ ò ní kú gẹ́gẹ́ bí èrò tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní lónìí?

Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Èṣù ò sọ fún Éfà pé tó bá jẹ èso tí Ọlọ́run ní kí wọ́n má jẹ, ó kàn máa dà bíi pé ó kú ni àmọ́ kò kú, bẹ́ẹ̀ ni kò sọ fún un pé ohun kan tí kò ṣeé fojú rí máa jáde lára rẹ̀ lọ gbé níbòmíì (èyí tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí àìleèkú ọkàn). Nígbà tí Sátánì lo ejò láti bá Éfà sọ̀rọ̀, ó jẹ́ kó mọ̀ pé tó bá jẹ nínú èso igi náà, ‘ó dájú pé kò ní kú’ rárá. Ó ń dọ́gbọ́n sọ fún Éfà pé tó bá gbọ́ tòun tó sì kẹ̀yìn sí Ọlọ́run, ayé rẹ̀ á túbọ̀ ládùn á sì wà láàyè títí láé.​—Jẹ́n. 2:17; 3:​3-5.

Tó bá jẹ́ pé inú ọgbà Édẹ́nì kọ́ ni ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn táwọn èèyàn fi ń kọ́ni lónìí ti bẹ̀rẹ̀, ibo ló ti wá bẹ̀rẹ̀? A ò lè sọ. Ohun tá a mọ̀ ni pé gbogbo ìjọsìn èké ló pa run nígbà Ìkún Omi ọjọ́ Nóà. Torí pé Nóà àti ìdílé rẹ̀ tó jẹ́ olùjọsìn Jèhófà nìkan ló la Ìkún Omi yẹn já, kò sí ìsìn èké kankan tó là á já.

Ó ṣe kedere nígbà náà pé ẹ̀yìn Ìkún Omi ni ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn táwọn èèyàn fi ń kọ́ni lónìí bẹ̀rẹ̀. Àmọ́ báwo ló ṣe tàn kálẹ̀? Kò sí àní-àní pé ìgbà tí Ọlọ́run da èdè àwọn èèyàn rú ní Bábélì tí wọ́n sì tú ká “sí gbogbo ayé” ni wọ́n tan ẹ̀kọ́ èké nípa àìleèkú ọkàn kálẹ̀. (Jẹ́n. 11:​8, 9) Ibi yòówù kí ẹ̀kọ́ èké náà ti bẹ̀rẹ̀, ó dájú pé Sátánì tó jẹ́ “baba irọ́” ló wà lẹ́yìn ẹ̀, inú ẹ̀ sì ń dùn bó ṣe ń tàn kálẹ̀.​—Jòh. 8:44.