Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí ni “àmì ìdánilójú” àti “èdìdì” tí Ọlọ́run máa fún Kristẹni ẹni àmì òróró kọ̀ọ̀kan?—2 Kọ́r. 1:21, 22; àlàyé ìsàlẹ̀.
Àmì ìdánilójú: Nígbà tí ìwé ìwádìí kan ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ Gírí ìkì tá a tú sí “àmì ìdánilójú” nínú 2 Kọ́ríńtì 1:22, ó pè é ní ọ̀rọ̀ tí “àwọn amòfin àtàwọn oníṣòwò” máa ń lò, èyí tó túmọ̀ sí “ẹ̀jẹ́ tàbí àsansílẹ̀ tẹ́nì kan san láti de ohun kan tó rà mọ́lẹ̀ tàbí àdéhùn tẹ́nì kan ṣe.” Ní tàwọn ẹni àmì òróró, àkọsílẹ̀ tó wà nínú 2 Kọ́ríńtì 5:1-5 fi hàn pé wọ́n máa gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nígbà tí wọ́n bá gbé ara àìdíbàjẹ́ ti ọ̀run wọ̀. Bákan náà, Jèhófà tún máa fún wọn ní ẹ̀bùn àìleèkú.—1 Kọ́r. 15:48-54.
Lóde òní, ọ̀rọ̀ Gírí ìkì míì tí wọ́n ń lò lèyí tí wọ́n fi ń pe òrùka tí ọkùnrin kan máa ń fún àfẹ́sọ́nà rẹ̀ káwọn èèyàn lè mọ̀ pé ó ti lẹ́ni tó ń fẹ́. Ẹ ò rí i pé ìyẹn bá a mu gan-an torí pé àwọn ẹni àmì òróró máa tó di ìyàwó Kristi lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ.—2 Kọ́r. 11:2; Ìfi. 21: 2, 9.
Èdìdì: Láyé àtijọ́, wọ́n sábà máa ń lo èdìdì gẹ́gẹ́ bí òǹtẹ̀ láti fi ẹ̀tọ́ oní-nǹkan hàn, láti fi hàn pé ohun kan jẹ́ ojúlówó tàbí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí àdéhùn. Ní tàwọn ẹni àmì òróró, Ọlọ́run fi “èdìdì” dì wọ́n tàbí pé ó fi òǹtẹ̀ ìṣàpẹẹrẹ lù wọ́n nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ pé wọ́n jẹ́ ti òun. (Éfé. 1:13, 14) Àmọ́, ó ṣe pàtàkì pé kí ẹni àmì òróró kan jẹ́ olóòótọ́ jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ torí pé gẹ́rẹ́ ṣáájú ikú rẹ̀ tàbí gẹ́rẹ́ kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀ ló máa gba èdìdì ìkẹyìn.—Éfé. 4:30; Ìfi. 7:2-4.