Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Pé Jọ Láti Jọ́sìn?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Pé Jọ Láti Jọ́sìn?

“Kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀.”—HÉBÉRÙ 10:24, 25.

ORIN: 20, 119

1-3. (a) Báwo làwọn Kristẹni ṣe fi hàn pé àwọn ò fọ̀rọ̀ ìpàdé lílọ ṣeré? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

NÍGBÀ TÍ Corinna wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17], wọ́n mú màmá rẹ̀, wọ́n sì rán an lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ kan tó jìnnà gan-an. Nígbà tó yá, wọ́n mú Corinna náà lọ sí Siberia, ibẹ̀ sì jìnnà gan-an sílé. Oko ló ti ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, ìlò ẹrú ni wọ́n sì ń lò ó. Nígbà míì, wọ́n á ní kó lọ ṣiṣẹ́ ní gbangba níbi tí òtútù ti ń mú gan-an, wọn ò sì ní fún un láṣọ tó lè gba òtútù dúró. Síbẹ̀, Corinna àti arábìnrin kan pinnu pé àwọn á ṣe gbogbo ohun tí àwọn lè ṣe káwọn lè kúrò lóko náà lọ sípàdé.

2 Corinna sọ pé: “A kúrò lóko nírọ̀lẹ́, a sì rìn lọ sí ojú irin kan tó wà ní kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25], ìyẹn ibùsọ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] sí oko náà. Aago méjì òru ni ọkọ̀ ojú irin náà gbéra, wákàtí mẹ́fà la sì lò nínú rẹ̀, lẹ́yìn náà la wá fẹsẹ̀ rin ìrìn kìlómítà mẹ́wàá, ìyẹn ibùsọ̀ mẹ́fà lọ síbi tá a ti fẹ́ ṣe ìpàdé náà.” Inú Corinna dùn pé òun lọ sípàdé náà. Ó wá sọ pé: “A kọrin, a sì ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Ìpàdé yẹn fún mi lókun, ó sì gbé ìgbàgbọ́ mi ró.” Ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà làwọn arábìnrin yìí pa dà sóko, kò sì sẹ́ni tó mọ̀ pé wọ́n lọ síbì kankan.

3 Tipẹ́tipẹ́ ló ti máa ń wu àwọn èèyàn Jèhófà pé kí wọ́n wà pa pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, inú àwọn Kristẹni máa ń dùn láti pé jọ kí wọ́n lè jọ́sìn Jèhófà kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀. (Ìṣe 2:42) Ó dájú pé ìwọ náà máa ń fojú sọ́nà fún lílọ sí ìpàdé ìjọ. Bíi ti àwọn ará wa kárí ayé, ó lè má rọrùn fún ẹ láti máa lọ sípàdé déédéé. Ó lè jẹ́ pé o máa ń pẹ́ níbiiṣẹ́, ọ̀pọ̀ nǹkan lè wà tó o fẹ́ ṣe, ó sì lè jẹ́ pé ìgbà gbogbo ló máa ń rẹ̀ ọ́. Torí náà, kí ló máa mú ká lè máa sa gbogbo ipá wa ká lè máa wà nípàdé nígbà gbogbo? [1] (Wo àfikún àlàyé.) Báwo la ṣe lè ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa wá sípàdé déédéé? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa ṣàlàyé (1) ìdí tí lílọ sípàdé fi máa ń ṣe wá láǹfààní, (2) ìdí tó fi máa ń ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ àti (3) ìdí tó fi máa ń múnú Jèhófà dùn. [2]—Wo àfikún àlàyé.

ÌPÀDÉ MÁA Ń ṢE WÁ LÁǸFÀÀNÍ

4. Ọ̀nà wo ni bá a ṣe máa ń pàdé pọ̀ ń gbà ràn wá lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà?

4 A máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nípàdé. Gbogbo ìpàdé la ti máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, kò tíì pẹ́ tí ọ̀pọ̀ ìjọ parí kíka ìwé Sún Mọ́ Jèhófà tán ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ. Báwo ló ṣe rí lára rẹ nígbà tá à ń jíròrò àwọn ànímọ́ Jèhófà, tó o sì tún gbọ́ báwọn ará ṣe ń sọ bó ṣe rí lára wọn? Ó dájú pé ṣe nìyẹn mú kó o túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Láwọn ìpàdé ìjọ, a túbọ̀ máa ń lóye Bíbélì nípa títẹ́tí sí àwọn àsọyé, Bíbélì kíkà àti wíwo àwọn àṣefihàn. (Nehemáyà 8:8) Tiẹ̀ tún ronú nípa àwọn ohun tuntun tá a máa ń kọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nígbà tá a bá ń múra Bíbélì kíkà wa sílẹ̀ tá a sì tún wá ń gbọ́ ohun táwọn míì ti rí kọ́ nínú ẹ̀.

5. Báwo làwọn ìpàdé ìjọ ṣe ń ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti lo àwọn ohun tó o ti kọ́ nínú Bíbélì, kó o sì tún mú kí bó o ṣe ń wàásù sunwọ̀n sí i?

5 Àwọn ìpàdé tá à ń ṣe, irú bí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ń kọ́ wa pé ká máa fi àwọn nǹkan tá à ń kọ́ nínú Bíbélì ṣèwà hù. (1 Tẹsalóníkà 4:9, 10) Bí àpẹẹrẹ, ṣó o ti wà níbi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ kan rí tó o sì wá rí i pé ó yẹ kó o ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, pé ó yẹ kó o túbọ̀ mú kí àdúrà rẹ sunwọ̀n sí i tàbí pé o gbọ́dọ̀ dárí ji arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan tó ṣẹ̀ ọ́? Ìpàdé tá a máa ń ṣe láàárín ọ̀sẹ̀ máa ń kọ́ wa láwọn ọ̀nà tá a lè gbà wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì.—Mátíù 28:19, 20.

6. Báwo la ṣe ń rí ìṣírí gbà láwọn ìpàdé ìjọ, báwo ni wọ́n sì ṣe ń fún wa lókun?

6 Ìpàdé máa ń gbé wa ró. Ayé Sátánì yìí máa ń fẹ́ sọ ìgbàgbọ́ wa di ahẹrẹpẹ, ó sì lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì tàbí kí gbogbo nǹkan tojú sú wa nígbà míì. Àmọ́, àwọn ìpàdé wa máa ń fún wa lókun wọ́n sì máa ń fún wa níṣìírí ká lè máa sin Jèhófà nìṣó. (Ka Ìṣe 15:30-32.) Ọ̀pọ̀ ìgbà la tún máa ń jíròrò bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì ṣe ń ṣẹ. Èyí sì lè mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe nípa ọjọ́ iwájú máa ṣẹ. Kì í ṣe ìgbà táwọn ará bá ń ṣiṣẹ́ nípàdé nìkan ni wọ́n máa fún wa níṣìírí, ìdáhùn wọn àti orin ìyìn tí wọ́n ń kọ sí Jèhófà látọkàn wá tún máa ń gbé wa ró. (1 Kọ́ríńtì 14:26) Ọ̀rọ̀ tá a máa ń bára wa sọ ṣáájú àti lẹ́yìn ìpàdé sì máa ń mú kára tù wá torí a mọ̀ pé àwọn tó fẹ́ràn wa là ń bá sọ̀rọ̀.—1 Kọ́ríńtì 16:17, 18.

Àwọn ìpàdé wa máa ń fún wa lókun, wọ́n sì máa ń fún wa níṣìírí ká lè máa sin Jèhófà nìṣó

7. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa lọ sípàdé?

7 Jèhófà máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láwọn ìpàdé wa. Ẹ̀mí mímọ́ ni Jésù fi ń darí ìjọ. Kódà, ó sọ fún wa pé ká “gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.” (Ìṣípayá 2:7) Ẹ̀mí mímọ́ lè jẹ́ ká borí ìdẹwò ká sì máa fi ìgboyà wàásù. Ó tún máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká máa sa gbogbo ipá wa ká lè wà nípàdé kí Jèhófà lè fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́.

A MÁA Ń RAN ÀWỌN MÍÌ LỌ́WỌ́ NÍPÀDÉ

8. Táwọn ará bá ń rí wa nípàdé, tí wọ́n ń tẹ́tí sí ìdáhùn wa, tí wọ́n sì ń gbọ́ bá a ṣe ń kọrin, báwo nìyẹn ṣe máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́? (Tún wo àpótí náà “ Ara Máa Ń Tù Ú Lẹ́yìn Ìpàdé.”)

8 Láwọn ìpàdé wa, a láǹfààní láti jẹ́ kí àwọn ará mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló ń fara da ìṣòro líle koko. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ . . . jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì.” (Hébérù 10:24, 25) Tá a bá ń fún àwọn ará níṣìírí bá a ṣe ń pé jọ pọ̀, wọ́n á mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn. Tá a bá ń lọ sípàdé, ìyẹn á fi hàn pé ó ń wù wá láti wà pẹ̀lú àwọn ará ká sì bára wa fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀ àti pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lógún. Orin ìyìn tá à ń fìtara kọ àti ìdáhùn wa tún máa ń fún wọn níṣìírí.—Kólósè 3:16.

9, 10. (a) Ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Jòhánù 10:16 ṣe mú ká lóye ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa pàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará wa. (b) Tá a bá ń lọ sípàdé déédéé, báwo la ṣe lè ran ẹnì kan tí ìdílé rẹ̀ ti pa tì lọ́wọ́?

9 Bá a ṣe ń lọ sípàdé ń mú ká wà níṣọ̀kan. (Ka Jòhánù 10:16.) Jésù sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun dà bí agbo àgùntàn kan, ó sì sọ pé òun ni olùṣọ́ àgùntàn agbo náà. Rò ó wò ná: Bí àgùntàn méjì bá wà lórí òkè, tí méjì míì wà níbi àfonífojì, tí ẹyọ kan wá wà ní ibòmíì, ṣé a lè sọ pé inú agbo kan làwọn àgùntàn márààrún yẹn wà? Rárá, torí pé ṣe làwọn àgùntàn tó wà nínú agbo kan máa ń wà pa pọ̀, wọn kì í fira wọn sílẹ̀, olùṣọ́ àgùntàn wọn ni wọ́n sì máa ń tẹ̀ lé. Torí náà, ká lè máa wà pẹ̀lú àwọn ará wa, ó yẹ ká máa lọ sípàdé déédéé. Tá a bá fẹ́ wà lára “agbo kan,” tá a sì fẹ́ máa tẹ̀ lé “olùṣọ́ àgùntàn kan,” àfi ká máa wá sípàdé déédéé.

10 Ìpàdé wa máa ń mú ká wà pa pọ̀ bí ìdílé kan tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn. (Sáàmù 133:1) Àwọn kan wà nínú ìjọ tí ìdílé wọn ti pa tì, ó lè jẹ́ àwọn òbí wọn tàbí àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò wọn. Àmọ́, Jésù ti ṣèlérí pé òun máa fún wọn ní ìdílé kan tó máa nífẹ̀ẹ́ wọn táá sì máa tọ́jú wọn. (Máàkù 10:29, 30) Tó o bá ń wá sípàdé déédéé, o lè di bàbá, ìyá, ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Tá a bá ń ronú nípa irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, àá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè máa wà ní gbogbo ìpàdé.

A MÁA MÚNÚ JÈHÓFÀ DÙN

11. Tá a bá ń lọ sípàdé, báwo nìyẹn ṣe máa mú ká fún Jèhófà lóhun tó tọ́ sí i?

11 Bá a ṣe ń wá sípàdé, à ń fún Jèhófà lóhun tó tọ́ sí i. Torí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa, ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ká máa bọlá fún un, ká sì máa yìn ín. (Ka Ìṣípayá 7:12.) Àwọn ohun tá a sì máa ń ṣe nípàdé nìyẹn, à ń gbàdúrà sí Jèhófà, à ń kọrin ìyìn sí i, a sì ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá la ní láti máa jọ́sìn Jèhófà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀!

Jèhófà ń rí gbogbo ipá tá à ń sà ká lè wà ní gbogbo ìpàdé, ó sì mọyì rẹ̀

12. Tá a bá ń ṣègbọràn sí àṣẹ Jèhófà pé ká máa lọ sípàdé, báwo ló ṣe máa rí lára rẹ̀?

12 Jèhófà ló dá wa, torí náà ó yẹ ká máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. Òun ló pa á láṣẹ pé ká máa pà dé pọ̀ déédéé, pàápàá bí àkókò òpin ṣe ń sún mọ́lé. Torí náà, tá a bá ń pa àṣẹ yìí mọ́, inú Jèhófà máa dùn sí wa. (1 Jòhánù 3:22) Ó máa ń rí gbogbo bá a ṣe ń sapá láti wà ní gbogbo ìpàdé, ó sì mọyì rẹ̀.—Hébérù 6:10.

13, 14. Ọ̀nà wo là ń gbà sún mọ́ Jèhófà àti Jésù nípàdé?

13 Tá a bá ń lọ sípàdé, à ń fi hàn pé a fẹ́ sún mọ́ Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀. Ní ìpàdé, a máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Jèhófà sì máa ń kọ́ wa lóhun tó fẹ́ ká ṣe àti bó ṣe fẹ́ ká máa gbé ìgbé ayé wa. (Aísáyà 30:20, 21) Kódà, táwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá wá sípàdé, wọ́n máa ń rí i pé Ọlọ́run ló ń darí wa. (1 Kọ́ríńtì 14:23-25) Ọ̀dọ̀ Jèhófà làwọn ohun tá à ń kọ́ ti ń wá, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ló sì fi ń darí àwọn ìpàdé wa. Torí náà, tá a bá lọ sípàdé, ọ̀rọ̀ Jèhófà la lọ gbọ́, à ń rí bó ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó, àá sì túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀.

14 Jésù tó jẹ́ Orí ìjọ sọ pé: “Níbi tí ẹni méjì tàbí mẹ́ta bá kóra jọ pọ̀ sí ní orúkọ mi, èmi wà níbẹ̀ láàárín wọn.” (Mátíù 18:20) Bíbélì tún sọ pé Jésù “ń rìn ní àárín” àwọn ìjọ. (Ìṣípayá 1:20–2:1) Ó ṣe kedere nígbà náà pé Jèhófà àti Jésù wà pẹ̀lú wa, wọ́n sì ń gbé wa ró láwọn ìpàdé wa. Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára Jèhófà tó bá rí gbogbo ohun tó ò ń ṣe láti túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú òun àti Ọmọ rẹ̀?

15. Tá a bá ń lọ sípàdé, báwo nìyẹn ṣe ń fi hàn pé a fẹ́ máa pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́?

15 Tá a bá ń lọ sípàdé, à ń fi hàn pé àṣẹ Jèhófà la fẹ́ máa pa mọ́. Jèhófà kì í fipá mú wa ṣe ohun tó fẹ́. (Aísáyà 43:23) Torí náà, tá a bá pa àṣẹ rẹ̀ mọ́ tá a sì ń lọ sípàdé, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ a sì gbà pé ó láṣẹ láti sọ ohun tá a máa ṣe fún wa. (Róòmù 6:17) Bí àpẹẹrẹ, kí la máa ṣe tí ọ̀gá wa bá gbé iṣẹ́ tí ò ní jẹ́ ká máa wà nípàdé déédéé fún wa? Ìjọba sì lè sọ pé àwọn á mú ẹnikẹ́ni tó bá ń pé jọ pọ̀ láti jọ́sìn Jèhófà, onítọ̀hún á san owó ìtanràn, tàbí kó lọ sẹ́wọ̀n tàbí kí wọ́n fìyà míì tó ju ìyẹn lọ jẹ ẹ́. Ó sì lè jẹ́ pé nǹkan míì ló wù ẹ́ pé kó o ṣe lásìkò ìpàdé. Ipò yòówù ká bára wa, àwa fúnra wa la máa pinnu ohun tá a máa ṣe. (Ìṣe 5:29) Àmọ́, ohun kan tó dájú ni pé gbogbo ìgbà tá a bá ṣègbọràn sí Jèhófà là ń múnú rẹ̀ dùn.—Òwe 27:11.

MÁA PÉ JỌ PẸ̀LÚ ÀWỌN ARÁ

16, 17. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé ọwọ́ pàtàkì làwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní fi mú pípé jọ pọ̀ déédéé? (b) Báwo ló ṣe máa ń wu Arákùnrin George Gangas tó pé kó wà pẹ̀lú àwọn ará nípàdé?

16 Lẹ́yìn ìpàdé tó wáyé nígbà Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33, àwọn Kristẹni ṣì máa ń pà dé pọ̀ déédéé láti jọ́sìn Jèhófà. Wọn ‘kì í kọ ìpéjọpọ̀ ara wọn sílẹ̀.’ (Hébérù 10:24, 25) Kódà nígbà tí ìjọba ilẹ̀ Róòmù àtàwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù ṣe inúnibíni sí wọn, wọn ò yé pé jọ pọ̀ láti jọ́sìn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún wọn, wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n lè máa jọ́sìn pa pọ̀.

17 Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà mọrírì àǹfààní tí wọ́n ní láti máa pé jọ pọ̀, wọ́n sì máa ń gbádùn rẹ̀. Arákùnrin George Gangas tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí fún ohun tó lé ní ọdún méjìlélógún [22] sọ pé: “Ní tèmi, kò sóhun tó dùn bíi kéèyàn máa wà pẹ̀lú àwọn ará nípàdé, ó sì máa ń mórí mi wú. Tí kò bá sídìí míì, ó máa ń wù mí pé kí n wà lára àwọn tó kọ́kọ́ dé Gbọ̀ngàn Ìjọba, kí n sì tún wà lára àwọn tó máa gbẹ̀yìn síbẹ̀. Mo máa ń ní ayọ̀ àtọkànwá tí mo bá ń bá àwọn ará sọ̀rọ̀. Tí mo bá wà láàárín wọn, ara mi máa ń balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, àfi bíi pé àárín ìdílé mi gan-an ni mo wà, nínú Párádísè tẹ̀mí. Gbogbo ohun tó wù mí láyé mi ni pé kí n ṣáà máa lọ sípàdé.”

18. Báwo ló ṣe máa ń wù ẹ́ tó pé kó o wà nípàdé, kí lo sì ti pinnu pé wàá ṣe?

18 Ṣé bí ìjọsìn Jèhófà ṣe rí lára tìẹ náà nìyẹn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kó o lè máa wà nípàdé pẹ̀lú àwọn ará, kódà bí ò bá tiẹ̀ rọrùn. Jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé bó ṣe rí lára Dáfídì Ọba ló rí lára ìwọ náà, nígbà tó sọ pé: “Jèhófà, mo nífẹ̀ẹ́ ibùgbé ilé rẹ.”—Sáàmù 26:8.

^ [1] (ìpínrọ̀ 3) Àwọn ará kan ò lè lọ sípàdé déédéé torí ipò tí wọ́n wà. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè máa ṣàìsàn tó le koko. Ó dájú pé Jèhófà lóye ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn, ó sì mọyì gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe láti jọ́sìn òun. Àwọn alàgbà lè ṣètò bí wọ́n á ṣe máa gbádùn ìpàdé náà lórí fóònù tàbí kí wọ́n bá wọn gbohùn ẹ̀ sílẹ̀.

^ [2] (ìpínrọ̀ 3) Wo àpótí náà, “ Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Lọ Sípàdé.”