Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Bí Ìrì Ni Iṣẹ́ Ìwàásù Rẹ Rí?

Ṣé Bí Ìrì Ni Iṣẹ́ Ìwàásù Rẹ Rí?

IṢẸ́ ìwàásù wa ṣe pàtàkì gan-an, ó sì ń ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo àwọn tá à ń wàásù fún ló mọ̀ bẹ́ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọn ò rò pé ó ṣe pàtàkì pé ká kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Àpẹẹrẹ kan ni ti Gavin. Ó ti ń lọ sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, àmọ́ kò gbà kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó sọ pé òun ò fi bẹ́ẹ̀ mọ Bíbélì, òun ò sì fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀. Ó rò pé wọ́n máa ní kóun wá di ara wọn ni, kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni tan òun jẹ. Kí lèrò ẹ? Ṣé o rò pé Gavin á ṣeé ràn lọ́wọ́? Jẹ́ ká wo bí ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe lè nípa rere lórí ẹnì kan. Jèhófà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Àsọjáde mi yóò máa sẹ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ bí ìrì, bí òjò winniwinni sára koríko.” (Diutarónómì 31:19, 30; 32:2) Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa ìrì, ká wá fi wé iṣẹ́ ìwàásù wa ká lè ran “gbogbo onírúurú ènìyàn” lọ́wọ́ lọ́nà tó máa ṣe wọ́n láǹfààní.—1 Tímótì 2:3, 4.

BÁWO NI IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ WA ṢE LÈ DÀ BÍ ÌRÌ?

Ìrì rọra máa ń sẹ̀. Bí ọ̀rinrin inú afẹ́fẹ́ ṣe ń di omi bẹ́ẹ̀ láá máa rọra sẹ̀ sílẹ̀ bí ìrì. Báwo ni ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣe ń “sẹ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ bí ìrì”? Ó máa ń fìfẹ́ bá àwọn èèyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó sì máa ń gba tiwọn rò. Ọ̀nà kan tá a lè gbà fìwà jọ Jèhófà ni pé ká má máa fipá mú àwọn èèyàn gba èrò wa, ká mọ̀ pé wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti gba ohun tó wù wọ́n gbọ́. Ká jẹ́ káwọn fúnra wọn ronú lórí ohun tí Bíbélì sọ, kí wọ́n sì dá ṣèpinnu. Tá a bá ń gba tàwọn èèyàn rò lọ́nà yìí, àwọn náà á gba ọ̀rọ̀ wa, iṣẹ́ ìwàásù wa á sì túbọ̀ sèso rere.

Ìrì máa ń tuni lára. Ọ̀rọ̀ wa á tu àwọn èèyàn lára tá a bá ń ronú oríṣiríṣi ọ̀nà tá a lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Arákùnrin Chris tó kọ́kọ́ fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ Gavin kò fipá mú Gavin láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló wá oríṣiríṣi ọ̀nà tó lè gbà mú kí ìjíròrò Bíbélì máa wọnú ọ̀rọ̀ wọn. Chris sọ fún Gavin pé àwọn kókó pàtàkì kan wà nínú Bíbélì tó máa mú kí Gavin túbọ̀ lóye àwọn ohun tó ń kọ́ nípàdé. Chris wá sọ fún un pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì ló mú kóun fúnra òun gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ inú Bíbélì. Ìyẹn mú káwọn méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí í jíròrò bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe ṣẹ. Ìyẹn tu Gavin lára gan-an, ó sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.

Ìrì ń gbẹ̀mí là. Tó bá di àsìkò ẹ̀rùn tójú ọjọ́ máa ń gbóná nílẹ̀ Ísírẹ́lì, ọ̀pọ̀ oṣù lè kọjá lọ kí wọ́n máà gbúròó òjò rárá. Láìsí ìrì tó máa ń mú kójú ọjọ́ tutù, ṣe ni àwọn ewéko máa gbẹ tí wọ́n á sì rẹ̀ dà nù. Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ṣe làwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí máa dà bí ìgbà tí ọ̀dá dá, ìyẹn ni pé òùngbẹ “gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà” á máa gbẹ àwọn èèyàn. (Ámósì 8:11) Ó ṣèlérí pé àwọn ẹni àmì òróró á “dà bí ìrì láti ọ̀dọ̀ Jèhófà” bí wọ́n ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáráyé, àti pé “àwọn àgùntàn mìíràn” náà á máa kọ́wọ́ ti iṣẹ́ náà. (Míkà 5:7; Jòhánù 10:16) Iṣẹ́ ìwàásù wa wà lára ohun tí Jèhófà pèsè káwọn tí òùngbẹ òtítọ́ ń gbẹ lè rí ìyè. Ǹjẹ́ a ka iṣẹ́ náà sí pàtàkì?

Ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìrì. (Diutarónómì 33:13) Ìbùkún tàbí ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni iṣẹ́ ìwàásù wa náà jẹ́ fáwọn tó bá gbọ́ ọ. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe Gavin láǹfààní torí ó mú kó rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó ti ń jẹ ẹ́ lọ́kàn látọdún yìí wá. Ó tètè lóye ohun tó ń kọ́, ó ṣèrìbọmi, òun àti Joyce ìyàwó ẹ̀ sì ti wá ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn báyìí.

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé

MÁ FOJÚ KÉRÉ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ RẸ

Bá a bá fi iṣẹ́ ìwàásù wa wé ìrì, ìyẹn tún máa jẹ́ ká rí bí ìsapá ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ti ṣe pàtàkì tó. Lọ́nà wo? Ẹ̀kán omi tó-tò-tó mélòó kan ò lè mú kí ilẹ̀ rin gbingbin, àmọ́ bí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìrí bá sẹ̀ sílẹ̀, ó máa mú kí ilẹ̀ rin gbingbin. Bákan náà, ohun tá à ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lè má fi bẹ́ẹ̀ jọ wá lójú. Àmọ́ tá a bá pa gbogbo ìsapá tí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ń ṣe pọ̀, àá rí i pé a ti wàásù “fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 24:14) Ṣé àwọn míì máa rí iṣẹ́ ìwàásù wa bí ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà? Tí wọ́n bá rí i bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé iṣẹ́ ìwàásù wa dà bí ìrì, tó rọra ń sẹ̀, tó ń tuni lára, tó sì ń gbẹ̀mí là nìyẹn!