Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tá A Bá Jẹ́ Olóòótọ́, A Máa Rí Ojúure Ọlọ́run

Tá A Bá Jẹ́ Olóòótọ́, A Máa Rí Ojúure Ọlọ́run

“Kí ẹ jẹ́ aláfarawé àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí náà.”​—HÉBÉRÙ 6:12.

ORIN: 86, 54

1, 2. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jẹ́fútà togun dé?

ỌMỌBÌNRIN kan sáré lọ pà dé bàbá rẹ̀. Inú ẹ̀ dùn gan-an pé bàbá rẹ̀ togun dé ní ayọ̀ àti àlàáfíà. Ó ń jó, ó ń yọ̀, torí pé bàbá rẹ̀ ti ja àjàṣẹ́gun. Àmọ́, ohun tí bàbá rẹ̀ ṣe àtohun tó sọ lẹ́yìn náà yà á lẹ́nu. Ó faṣọ ya mọ́ra ẹ̀ lọ́rùn, ó sì kígbe pé: “Págà, ọmọbìnrin mi! O ti mú mi tẹ̀ ba ní tòótọ́.” Ó wá sọ fún un pé òun ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan fún Jèhófà, ẹ̀jẹ́ náà sì máa yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà pátápátá. Ohun tí ẹ̀jẹ́ yẹn túmọ̀ sí ni pé ọmọbìnrin náà ò ní lọ́kọ, kò sì ní lọ́mọ láyé. Àmọ́, ojú ẹsẹ̀ ló sọ ohun kan tó dùn mọ́ bàbá ẹ̀ nínú, ó ní kó mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Ohun tó sọ yìí fi hàn pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, ó sì gbà pé ohun yòówù tí Jèhófà bá rí pó máa ṣòun láǹfààní ló máa ní kóun ṣe. (Àwọn Onídàájọ́ 11:34-37) Nígbà tí bàbá rẹ̀ rí bí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣe lágbára tó, inú ẹ̀ dùn gan-an torí ó mọ̀ pé ohun tọ́mọ náà fẹ́ ṣe máa múnú Jèhófà dùn.

2 Jẹ́fútà àti ọmọbìnrin rẹ̀ ò ṣiyè méjì kankan nípa Jèhófà àti ọ̀nà tó ń gbà ṣe nǹkan. Bí ò tiẹ̀ rọrùn fún wọn láti ṣe ohun tí Jèhófà ní kí wọ́n ṣe, síbẹ̀ wọ́n ṣègbọràn. Wọ́n fẹ́ rí ojúure Jèhófà, ohunkóhun téèyàn bá sì yááfì kó lè rójú rere Ọlọ́run tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.

3. Kí nìdí tí àpẹẹrẹ Jẹ́fútà àti ọmọbìnrin rẹ̀ fi máa ṣe wá láǹfààní?

3 Kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Àfi ká “máa ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́.” (Júúdà 3) Ká lè máa ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ lára Jẹ́fútà àti ọmọbìnrin rẹ̀, ká sì rí bí wọ́n ṣe fara da àdánwò. Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn?

WỌ́N JẸ́ OLÓÒÓTỌ́ NÍNÚ AYÉ TÓ KÚN FÚN ÌWÀ ÌBÀJẸ́

4, 5. (a) Àṣẹ wo ni Jèhófà pa fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n dé Ilẹ̀ Ìlérí? (b) Bí Sáàmù 106 ṣe sọ, kí ni àìgbọràn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yọrí sí?

4 Kò sí àní-àní pé ojoojúmọ́ ni Jẹ́fútà àti ọmọbìnrin rẹ̀ á máa rántí ohun tó yọrí sí nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣàìgbọràn sí Jèhófà. Ní nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún [300] ọdún ṣáájú ìgbà yẹn, Jèhófà ti pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn abọ̀rìṣà tó wà ní Ilẹ̀ Ìlérí run, àmọ́ wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. (Diutarónómì 7:1-4) Ṣe ni ọ̀pọ̀ lára wọn bẹ̀rẹ̀ sí í fara wé àwọn ọmọ ilẹ̀ Kénáánì tó jẹ́ oníṣekúṣe àti abọ̀rìṣà.—Ka Sáàmù 106:34-39.

5 Torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣàìgbọràn, Jèhófà ò dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. (Àwọn Onídàájọ́ 2:1-3, 11-15; Sáàmù 106:40-43) Kò sí àní-àní pé nígbà yẹn, á nira gan-an fáwọn ìdílé tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà láti máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé àwọn olóòótọ́ kan ṣì wà bíi Jẹ́fútà àti ọmọbìnrin rẹ̀, Ẹlikénà, Hánà àti Sámúẹ́lì. Wọ́n pinnu pé ohun tínú Jèhófà dùn sí làwọn á máa ṣe.—1 Sámúẹ́lì 1:20-28; 2:26.

6. Àwọn nǹkan wo ló lè kéèràn ràn wá lónìí, kí la sì gbọ́dọ̀ ṣe?

6 Lóde òní, ṣe làwọn èèyàn ń ronú tí wọ́n sì ń hùwà bíi tàwọn ọmọ ilẹ̀ Kénáánì. Ṣe ni wọ́n ń hùwà ipá lọ ràì, tí wọ́n ń fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn wá owó kiri, ìṣekúṣe ò sì jẹ́ nǹkan kan lójú wọn. Àmọ́, Jèhófà ti fún wa ní ìkìlọ̀ tó ṣe kedere. Bó ṣe ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó fẹ́ dáàbò bò wá káwọn èèyàn ayé yìí má bàa kéèràn ràn wá. Ǹjẹ́ kò yẹ ká kọ́gbọ́n látinú àṣìṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? (1 Kọ́ríńtì 10:6-11) A gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe ká má bàa lọ bẹ̀rẹ̀ sí í ronú báwọn èèyàn ayé ṣe ń ronú. (Róòmù 12:2) Ṣé a máa sa gbogbo ipá wa láti ṣe bẹ́ẹ̀?

WỌ́N ṢE INÚNIBÍNI SÍ JẸ́FÚTÀ, SÍBẸ̀ Ó JẸ́ OLÓÒÓTỌ́

7. (a) Kí làwọn èèyàn ṣe fún Jẹ́fútà? (b) Kí ni Jẹ́fútà wá ṣe?

7 Nígbà ayé Jẹ́fútà, àwọn Filísínì àtàwọn ọmọ Ámónì fojú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí màbo torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣàìgbọràn sí Jèhófà. (Àwọn Onídàájọ́ 10:7, 8) Ìyẹn nìkan kọ́, àwọn arákùnrin Jẹ́fútà àtàwọn àgbà ọkùnrin ilẹ̀ Ísírẹ́lì náà tún ṣe inúnibíni sí Jẹ́fútà. Torí pé àwọn arákùnrin Jẹ́fútà kórìíra ẹ̀ wọ́n sì ń jowú ẹ̀, wọ́n lé e kúrò ní ilẹ̀ bàbá rẹ̀. (Àwọn Onídàájọ́ 11:1-3) Jẹ́fútà ò jẹ́ kí ìwà ìkà tí wọ́n hù sí i yìí mú kóun náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìdáa sí wọn. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé nígbà táwọn àgbà ọkùnrin ilẹ̀ náà bẹ̀ ẹ́ pé kó ran àwọn lọ́wọ́, kò lọ́ tìkọ̀, ó ràn wọ́n lọ́wọ́. (Àwọn Onídàájọ́ 11:4-11) Kí ló mú kí Jẹ́fútà hùwà tó dáa sí wọn láìka gbogbo ohun tí wọ́n ti fojú rẹ̀ rí sí?

8, 9. (a) Àwọn ìlànà inú Òfin Mósè wo ló ṣeé ṣe kó ran Jẹ́fútà lọ́wọ́? (b) Kí ni Jẹ́fútà kà sí pàtàkì jù?

8 Akin lójú ogun ni Jẹ́fútà, ó sì mọ ìtàn ilẹ̀ Ísírẹ́lì àti Òfin Mósè dáadáa. Ọwọ́ tí Jèhófà fi mú àwọn èèyàn Rẹ̀ jẹ́ kí Jẹ́fútà mọ èrò Ọlọ́run lórí ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. (Àwọn Onídàájọ́ 11:12-27) Jẹ́fútà jẹ́ kí òótọ́ tó mọ̀ yìí darí gbogbo ìpinnu tó ṣe nígbèésí ayé rẹ̀. Ó mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn Rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn, ó sì mọ̀ pé kò fẹ́ kí wọ́n máa bínú síra wọn tàbí kí wọ́n máa gbẹ̀san. Yàtọ̀ síyẹn, Òfin Mósè jẹ́ kó mọ̀ pé ó yẹ kóun nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn títí kan àwọn tó kórìíra òun pàápàá.—Ka Ẹ́kísódù 23:5; Léfítíkù 19:17, 18.

9 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àpẹẹrẹ Jósẹ́fù ló ran Jẹ́fútà lọ́wọ́. Ó ti ní láti gbọ́ bí Jósẹ́fù ṣe fojú àánú hàn sáwọn arákùnrin rẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kórìíra rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 37:4; 45:4, 5) Ó lè jẹ́ pé bí Jẹ́fútà ṣe ronú lórí àpẹẹrẹ Jósẹ́fù ló mú kó ṣe ohun tó múnú Jèhófà dùn. Ohun táwọn arákùnrin rẹ̀ ṣe sí i dùn ún gan-an lóòótọ́, àmọ́ bó ṣe máa jà fórúkọ Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀ ṣe pàtàkì sí i ju ẹ̀dùn ọkàn táwọn èèyàn rẹ̀ kó bá a. (Àwọn Onídàájọ́ 11:9) Ó pinnu pé òun á jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Èyí sì mú kí Jèhófà bù kún òun àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.—Hébérù 11:32, 33.

Kò yẹ ká lá ò ní sin Jèhófà mọ́ torí pé ẹnì kan ṣẹ̀ wá

10. Báwo la ṣe lè máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà inú Bíbélì ká lè máa hùwà tó yẹ Kristẹni?

10 Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára Jẹ́fútà? Kí la máa ṣe táwọn ará wa bá ṣe ohun tó dùn wá tàbí tí wọ́n bá ṣàìdáa sí wa? Kò yẹ ká lá ò ní sin Jèhófà mọ́ torí pé ẹnì kan ṣẹ̀ wá. Má torí ìyẹn sọ pé o ò ní lọ sípàdé mọ́ tàbí pé o ò ní bá àwọn ará ìjọ ṣe mọ́. Ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jẹ́fútà ká sì ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Èyí á mú ká borí àwọn ìṣòro tó le koko, àá sì jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ.—Róòmù 12:20, 21; Kólósè 3:13.

ÀWỌN OHUN TÁ A YÁÁFÌ Ń FI BÍ ÌGBÀGBỌ́ WA ṢE PỌ̀ TÓ HÀN

11, 12. Ẹ̀jẹ́ wo ni Jẹ́fútà jẹ́ fún Jèhófà, kí sì ni ẹ̀jẹ́ náà túmọ̀ sí?

11 Jẹ́fútà mọ̀ pé àfi kí Ọlọ́run ti òun lẹ́yìn kóun tó lè gba Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ámónì. Torí náà, ó ṣèlérí fún Jèhófà pé tó bá jẹ́ kí òun ṣẹ́gun, tí òun sì pa dà sílé ní ayọ̀ àti àlàáfíà, òun á fi ẹni tó bá kọ́kọ́ jáde wá pà dé òun láti inú ilé òun rú “ọrẹ ẹbọ sísun” sí Ọlọ́run. (Àwọn Onídàájọ́ 11:30, 31) Kí nìyẹn túmọ̀ sí?

12 Jèhófà kórìíra fífi èèyàn rúbọ, torí náà, a mọ̀ pé kì í ṣe pé Jẹ́fútà fẹ́ pa èèyàn fi rúbọ ní ti gidi. (Diutarónómì 18:9, 10) Nínú Òfin Mósè, ọrẹ ẹbọ sísun ni ẹ̀bùn pàtàkì téèyàn fún Jèhófà pátápátá. Torí náà, ohun tí Jẹ́fútà ní lọ́kàn ni pé ẹni tóun máa fi fún Jèhófà á máa sìn nínú àgọ́ ìjọsìn jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. Jèhófà gbọ́ ẹ̀bẹ̀ Jẹ́fútà, ó sì mú kó ṣẹ́gun. (Àwọn Onídàájọ́ 11:32, 33) Àmọ́ ta wá ni Jẹ́fútà máa fi fún Jèhófà báyìí?

13, 14. Kí làwọn ọ̀rọ̀ tí Jẹ́fútà sọ nínú Àwọn Onídàájọ́ 11:35 jẹ́ ká mọ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀?

13 Tiẹ̀ ronú nípa ohun tá a sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ná. Nígbà tí Jẹ́fútà togun dé, ọmọbìnrin rẹ̀ ọ̀wọ́n lẹni àkọ́kọ́ tó jáde wá pà dé rẹ̀, òun sì lọmọ kan ṣoṣo tó bí! Ṣé Jẹ́fútà á wá lè mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ báyìí? Ṣó máa yọ̀ǹda ọmọ rẹ̀ fún Jèhófà kó lè máa sìn títí gbére nínú àgọ́ ìjọsìn?

14 Ó ní láti jẹ́ pé àwọn ìlànà inú Òfin Ọlọ́run ló tún ran Jẹ́fútà lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó tọ́. Ó ṣeé ṣe kó rántí ohun tí Jèhófà sọ fáwọn èèyàn rẹ̀ nínú Ẹ́kísódù 23:19, pé kí wọ́n máa fínnúfíndọ̀ fi àwọn ohun ìní wọn tó dára jù lọ fún òun. Òfin tún sọ pé tẹ́nì kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Jèhófà, “kò gbọdọ̀ yẹ ọ̀rọ̀ rẹ̀, bí ó ti wí ni ó gbọdọ̀ ṣe.” (Númérì 30:2, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀) Bíi ti Hánà olóòótọ́, tó ṣeé ṣe kó gbáyé nígbà ayé Jẹ́fútà, Jẹ́fútà mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ ohun tó máa ná òun àtọmọ òun. Ọmọ rẹ̀ yìí ò ní lọ́mọ láyé torí pé inú àgọ́ ìjọsìn lá ti máa sin Jèhófà. Torí náà, kò ní sẹ́ni táá jogún àwọn ilẹ̀ tí Jẹ́fútà ní, orúkọ rẹ̀ á sì pa rẹ́. (Àwọn Onídàájọ́ 11:34) Síbẹ̀, Jẹ́fútà sọ pé: “Èmi sì ti la ẹnu mi sí Jèhófà, èmi kò sì lè yí padà.” (Àwọn Onídàájọ́ 11:35) Jèhófà gba ẹbọ tí Jẹ́fútà fínnúfíndọ̀ rú yìí, ó sì bù kún un. Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni Jẹ́fútà, ṣé wàá mú ìlérí rẹ ṣẹ?

15. Ẹ̀jẹ́ wo ni ọ̀pọ̀ lára wa jẹ́ fún Jèhófà, báwo la sì ṣe lè mú ẹ̀jẹ́ náà ṣẹ?

15 Nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, a jẹ́jẹ̀ẹ́ pé ìfẹ́ rẹ̀ la ó máa ṣe ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. A mọ̀ pé ìyẹn ò lè fìgbà gbogbo rọrùn. Àmọ́, kí la máa ṣe bí ètò Ọlọ́run bá ní ká ṣe ohun kan, tí nǹkan ọ̀hún ò sì rọrùn? Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, tá a sì fínnúfíndọ̀ ṣe ohun tó ní ká ṣe, ṣe là ń mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ. Ó lè nira fún wa gan-an láti yááfì àwọn ohun tá a yááfì, àmọ́ ìbùkún Jèhófà ju gbogbo ohun tá a lè yááfì lọ. (Málákì 3:10) Ọmọbìnrin Jẹ́fútà ńkọ́? Kí ló ṣe nígbà tó gbọ́ ìlérí tí bàbá rẹ̀ ṣe yìí?

Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ bíi tí Jẹ́fútà àti ọmọbìnrin rẹ̀? (Wo ìpínrọ̀ 16, 17)

16. Kí ni ọmọbìnrin Jẹ́fútà sọ nígbà tó gbọ́ ìlérí tí bàbá rẹ̀ ṣe? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

16 Ẹ̀jẹ́ tí Jẹ́fútà jẹ́ fún Jèhófà yàtọ̀ sí ti Hánà. Hánà jẹ́jẹ̀ẹ́ pé Sámúẹ́lì ọmọ òun á di Násírì, á sì máa sìn nínú àgọ́ ìjọsìn. (1 Sámúẹ́lì 1:11) Násírì Ọlọ́run lè gbéyàwó kó sì bímọ. Àmọ́ ṣe ni Jẹ́fútà fi ọmọbìnrin rẹ̀ rú “ẹbọ sísun” sí Jèhófà, ìyẹn ni pé ó fi í fún Jèhófà pátápátá, torí náà, kò ní lọ́kọ, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé á bímọ. (Àwọn Onídàájọ́ 11:37-40) Tiẹ̀ rò ó wò ná! Ọkùnrin tó dáa jù nílẹ̀ náà ni ì bá fẹ́ torí pé bàbá rẹ̀ ni aṣáájú nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Àmọ́ ní báyìí, á máa ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú àgọ́ ìjọsìn. Báwo lèyí ṣe rí lára ọmọbìnrin Jẹ́fútà? Ó sọ ohun tó fi hàn pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ló ṣe pàtàkì sí i jù, ó sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Ṣe sí mi ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ó ti ẹnu rẹ jáde.” (Àwọn Onídàájọ́ 11:36) Ó yàn láti má ṣe lọ́kọ tàbí bímọ kó lè máa sin Jèhófà. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?

Ọmọbìnrin Jẹ́fútà yàn láti má ṣe lọ́kọ tàbí bímọ kó lè sin Jèhófà

17. (a) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Jẹ́fútà àti ọmọbìnrin rẹ̀? (b) Báwo lọ̀rọ̀ inú Hébérù 6:10-12 ṣe fún ẹ níṣìírí láti máa yááfì àwọn nǹkan torí iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run?

17 Ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jèhófà lọ́kùnrin àti lóbìnrin ti pinnu pé àwọn ò ní tíì lọ́kọ tàbí láya, àwọn míì sì pinnu pé àwọn ò ní tíì bímọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n fẹ́ túbọ̀ gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn àgbàlagbà kan ti pinnu pé àwọn á máa lò lára àkókò tó yẹ kí àwọn fi wà pẹ̀lú àwọn ọmọ àtàwọn ọmọ ọmọ àwọn fún Jèhófà. A rí lára wọn tó ń bá ètò Ọlọ́run ṣiṣẹ́ ìkọ́lé, a sì rí àwọn tó lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n sì ṣí lọ sí ìjọ tá a ti nílò àwọn akéde púpọ̀ sí i. Àwọn míì sì máa ń pinnu pé àwọn á ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà nígbà Ìrántí Ikú Kristi. Jèhófà mọyì báwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ yìí ṣe ń yááfì àwọn nǹkan torí kí wọ́n lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Ka Hébérù 6:10-12.) Ìwọ ńkọ́? Ṣé wàá lè yááfì àwọn nǹkan kan kó o lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?

KÍ LA RÍ KỌ́?

18, 19. Kí la rí kọ́ látinú ohun tí Bíbélì sọ nípa Jẹ́fútà àti ọmọbìnrin rẹ̀, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn?

18 Kí ló mú kí Jẹ́fútà borí àwọn àdánwò tó kojú? Ó jẹ́ kí Jèhófà darí gbogbo ìpinnu tó ṣe. Kò jẹ́ kí ìwàkiwà táwọn èèyàn ń hù kéèràn ran òun. Ó sì ṣe ohun tó tọ́ kódà nígbà táwọn èèyàn ṣàìdáa sí i. Jèhófà bù kún Jẹ́fútà àti ọmọbìnrin rẹ̀ torí àwọn ohun tí wọ́n fínnúfíndọ̀ yááfì, Ó sì lo àwọn méjèèjì láti gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ. Kódà nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá kọ̀ láti ṣe ohun tó tọ́, ohun tí Jèhófà fẹ́ ni Jẹ́fútà àti ọmọbìnrin rẹ̀ ń ṣe ní tiwọn.

19 Bíbélì sọ pé ká “jẹ́ aláfarawé àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí náà.” (Hébérù 6:12) Ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jẹ́fútà àti ọmọbìnrin rẹ̀, ká jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà á bù kún wa tá a bá jẹ́ olóòótọ́ títí dé òpin.