Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Pè É Ní “Ọ̀rẹ́ Mi”

Jèhófà Pè É Ní “Ọ̀rẹ́ Mi”

“Ìwọ, Ísírẹ́lì, ni ìránṣẹ́ mi, ìwọ, Jékọ́bù, ẹni tí mo ti yàn, irú-ọmọ Ábúráhámù ọ̀rẹ́ mi.”—AÍSÁYÀ 41:8.

ORIN: 91, 22

1, 2. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé àwa èèyàn lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

LÁTÌGBÀ tí wọ́n bá ti bíni títí dọjọ́ ikú, kòṣeémáàní ni ìfẹ́ jẹ́. Ó máa ń wu àwa èèyàn ká rẹ́ni tá a jọ mọwọ́ ara wa tó sì tún nífẹ̀ẹ́ wa bá ṣọ̀rẹ́. Àmọ́, èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé kí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. Ọ̀pọ̀ èèyàn ò gbà pé àwa èèyàn lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run ká sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀ torí pé a ò lè rí i àti pé agbára rẹ̀ ò láfiwé. Àmọ́, àwa mọ̀ pé èèyàn lè dọ̀rẹ́ Ọlọ́run!

2 A ti rí àpẹẹrẹ àwọn èèyàn tó di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run nínú Bíbélì. Ó yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ lára irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé kò sóhun tá a lè fi wé kéèyàn jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Torí náà, ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Ábúráhámù yẹ̀ wò. (Ka Jákọ́bù 2:23.) Báwo ló ṣe di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run? Ìgbàgbọ́ tí Ábúráhámù ní ló mú kó dọ̀rẹ́ Ọlọ́run, ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe Ábúráhámù ní “baba gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́.” (Róòmù 4:11) Bó o ṣe ń ronú nípa àwọn ohun tí Ábúráhámù ṣe, bi ara rẹ pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Ábúráhámù kí n sì mú kí àjọṣe tí mo ní pẹ̀lú Jèhófà lágbára sí i?’

BÁWO NI ÁBÚRÁHÁMÙ ṢE DI Ọ̀RẸ́ JÈHÓFÀ?

3, 4. (a) Kí ló ṣeé ṣe kó jẹ́ àdánwò ìgbàgbọ́ tó lágbára jù lọ tí Ábúráhámù kojú? (b) Kí ló mú kí Ábúráhámù gbà láti fi Ísákì rúbọ?

3 Fojú inú wo Ábúráhámù, ẹni tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni ọdún márùndínláàádóje [125], bó ṣe rọra ń gorí òkè lọ. [1] (Wo àfikún àlàyé.) Ísákì ọmọ rẹ̀ tóun náà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] ń tẹ̀ lé e. Ísákì ru igi ìdáná, Ábúráhámù sì mú ọ̀bẹ àtàwọn ohun tí wọ́n á fi dáná dání. Àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé ìrìn-àjò tó le jù nígbèésí ayé Ábúráhámù nìyẹn. Àmọ́ kì í ṣe torí pé ó ti darúgbó o, koko lara ẹ̀ le. Ohun tó mú kí ìrìn-àjò yẹn le ni pé Jèhófà ní kó fi ọmọ rẹ̀ rúbọ sí òun!—Jẹ́nẹ́sísì 22:1-8.

Kì í ṣe pé Ábúráhámù ò mọ ohun tó ń ṣe tàbí pé kò ronú kó tó mú ọmọ rẹ̀ láti lọ fi rúbọ

4 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àdánwò ìgbàgbọ́ tó lágbára jù lọ tí Ábúráhámù kojú nìyẹn. Àwọn kan sọ pé ìkà ni Ọlọ́run bó ṣe sọ pé kí Ábúráhámù fi ọmọ rẹ̀ rúbọ. Àwọn míì sì sọ pé torí pé Ábúráhámù pàápàá ò nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀ ló ṣe gbà láti fi rúbọ. Ìdí tí wọ́n fi ń sọ bẹ́ẹ̀ ni pé wọn ò nígbàgbọ́, wọn ò tiẹ̀ mọ ohun tá à ń pè ní ojúlówó ìgbàgbọ́, wọn ò sì mọ ohun tí ìgbàgbọ́ lè súnni ṣe. (1 Kọ́ríńtì 2:14-16) Àmọ́ kì í ṣe pé Ábúráhámù ò mọ ohun tó ń ṣe tàbí pé kò ronú kó tó mú ọmọ rẹ̀ láti lọ fi rúbọ. Ojúlówó ìgbàgbọ́ tó ní ló mú kó ṣègbọràn. Ábúráhámù mọ̀ pé bí òun bá tiẹ̀ fi ọmọ òun rúbọ sí Jèhófà, Jèhófà lè jí i dìde. Ó mọ̀ pé tóun bá ṣègbọràn, Jèhófà á bù kún òun àti ọmọ òun ọ̀wọ́n. Kí ló jẹ́ kí Ábúráhámù ní irú ìgbàgbọ́ tó lágbára bẹ́ẹ̀? Àwọn ohun tó kọ́ nípa Jèhófà àtàwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i ni.

5. Ọ̀nà wo ló ṣeé ṣe kí Ábúráhámù gbà mọ Jèhófà, kí sì làwọn ohun tó kọ́ nípa Jèhófà mú kó ṣe?

5 Àwọn ohun tó kọ́ nípa Jèhófà. Ìlú kan tó ń jẹ́ Úrì ni Ábúráhámù gbé dàgbà. Abọ̀rìṣà làwọn ará ìlú Úrì, òrìṣà sì ni bàbá Ábúráhámù náà ń bọ. (Jóṣúà 24:2) Báwo ni Ábúráhámù ṣe wá mọ Jèhófà? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìbátan Ábúráhámù ni Ṣémù ọmọ Nóà. Ṣémù sì wà láyé títí dìgbà tí Ábúráhámù fi pé nǹkan bí àádọ́jọ [150] ọdún. Ṣémù ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run, ó sì ṣeé ṣe kó sọ nípa Jèhófà fáwọn ìbátan rẹ̀. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí Ábúráhámù ṣe mọ Jèhófà nìyẹn. Ohun tí Ábúráhámù kọ́ nípa Jèhófà mú kó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ìyẹn náà ló sì mú kó ní ìgbàgbọ́.

6, 7. Báwo làwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ábúráhámù ṣe mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára sí i?

6 Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i. Kí làwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ábúráhámù tó mú kí ìgbàgbọ́ tó ní nínú Jèhófà lágbára sí i? Wọ́n máa ń sọ pé ohun tó wà nínú ẹni ni ọtí ń pani pa. Torí náà, ohun tí Ábúráhámù kọ́ nípa Ọlọ́run ló mú kó ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún “Jèhófà Ọlọ́run Gíga Jù Lọ, Ẹni tí Ó Ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 14:22) Bíbélì pe irú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ‘ìbẹ̀rù Ọlọ́run.’ (Hébérù 5:7) A gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, ká tó lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. (Sáàmù 25:14) Ìbẹ̀rù Ọlọ́run tí Ábúráhámù ní yìí ló mú kó ṣègbọràn sí Jèhófà.

7 Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù àti Sárà pé kí wọ́n fi ilé wọn ní ìlú Úrì sílẹ̀, kí wọ́n sì ṣí lọ sí ilẹ̀ àjèjì. Àwọn méjèèjì ti dàgbà, inú àgọ́ ló sì kù tí wọ́n á máa gbé báyìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ábúráhámù mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ewu ló wà nínú ìyẹn, ó pinnu láti ṣègbọràn sí Jèhófà. Ìyẹn ló sì mú kí Jèhófà bù kún un tó sì tún dáàbò bò ó. Bí àpẹẹrẹ, ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ táwọn kan mú Sárà tó jẹ́ arẹwà lọ, tí ẹ̀mí Ábúráhámù ọkọ rẹ̀ sì wà nínú ewu, àmọ́ Jèhófà dáàbò bo Ábúráhámù àti Sárà lọ́nà ìyanu. (Jẹ́nẹ́sísì 12:10-20; 20:2-7, 10-12, 17, 18) Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn mú kí ìgbàgbọ́ Ábúráhámù lágbára sí i.

8. Báwo la ṣe lè ní ìmọ̀ àti ìrírí táá mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára?

8 Ṣé a lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà? Bẹ́ẹ̀ ni! Bíi ti Ábúráhámù, a ní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Àwa náà sì lè ní ìmọ̀ àti ìrírí táá mú kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jèhófà túbọ̀ lágbára. Lónìí, ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà tá a lè mọ̀ nípa Jèhófà. (Dáníẹ́lì 12:4; Róòmù 11:33) Àwọn ohun tó yẹ ká mọ̀ nípa “Ẹni tí Ó Ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé” kún inú Bíbélì. Àwọn ohun tá à ń kọ́ nípa Jèhófà ń mú ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì ń mú ká ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún un. Bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tá a sì ń bọ̀wọ̀ fún un yìí ló ń mú ká máa ṣègbọràn sí i. Bá a sì ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, à ń rí bó ṣe ń bù kún wa tó sì ń dáàbò bò wá, ìyẹn ló ń jẹ́ ká ní ìrírí tó ń mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. Tá a bá fi gbogbo ayé wa sin Jèhófà, ọkàn wa á balẹ̀, àá sì ní àlàáfíà àti ayọ̀. (Sáàmù 34:8; Òwe 10:22) Bá a ṣe ń mọ Jèhófà sí i ni Jèhófà á máa bù kún wa, bẹ́ẹ̀ sì ni àjọṣe tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ á máa lágbára sí i.

KÍ NI ÁBÚRÁHÁMÙ ṢE TÍ ÀJỌṢE TÓ NÍ PẸ̀LÚ ỌLỌ́RUN Ò FI BÀ JẸ́?

9, 10. (a) Kí ni kì í jẹ́ kí okùn ọ̀rẹ́ tètè já? (b) Kí ló fi hàn pé Ábúráhámù mọyì àjọṣe tó ní pẹ̀lú Jèhófà àti pé kò fẹ́ kí àjọṣe náà bà jẹ́?

9 Bí ìṣura iyebíye ni àjọṣe tímọ́tímọ́ rí. (Ka Òwe 17:17.) Kò dà bí àwo òdòdó olówó iyebíye tí wọ́n kàn fi ń ṣe ilé lọ́ṣọ̀ọ́ lásán. Ṣe ló dà bí òdòdó rírẹwà téèyàn á máa bomi rin táá sì máa tọ́jú kó lè dàgbà kó sì máa rẹwà sí i. Ábúráhámù mọyì àjọṣe tó ní pẹ̀lú Jèhófà kò sì jẹ́ kó bà jẹ́. Báwo ló ṣe ṣe é?

Àjọṣe àárín ọ̀rẹ́ méjì dà bí òdòdó rírẹwà téèyàn á máa bomi rin táá sì máa tọ́jú kó lè dàgbà kó sì máa rẹwà sí i

10 Ábúráhámù túbọ̀ ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run ó sì ń mú kí ìbẹ̀rù tó ní fún un lágbára sí i. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí òun àti ìdílé rẹ̀ àtàwọn ẹrú rẹ̀ rìnrìn-àjò lọ sí ìlú Kénáánì, ó ń jẹ́ kí Jèhófà darí gbogbo ìpinnu tó ń ṣe. Nígbà tí Ábúráhámù wà lẹ́ni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún [99], ìyẹn ọdún kan ṣáájú kó tó bí Ísákì, Jèhófà sọ fún un pé kó dádọ̀dọ́ gbogbo ọkùnrin tó wà nínú agbo ilé rẹ̀. Ṣé Ábúráhámù ṣiyè méjì nípa ohun tí Jèhófà sọ fún un àbí ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwáwí kó má bàa ṣe ohun tí Jèhófà ní kó ṣe? Rárá o, ńṣe ló gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ‘ọjọ́ yẹn gan-an’ ló sì ṣe ohun tí Jèhófà ní kó ṣe.—Jẹ́nẹ́sísì 17:10-14, 23.

11. Kí ló fà á tí Ábúráhámù ò fi fẹ́ kí Jèhófà pa ìlú Sódómù àti Gòmórà run, báwo sì ni Jèhófà ṣe ràn án lọ́wọ́?

11 Àjọṣe tí Ábúráhámù ní pẹ̀lú Jèhófà ń lágbára sí i torí pé gbogbo ìgbà ni Ábúráhámù máa ń ṣègbọràn sí Jèhófà. Ábúráhámù gbà pé kò sóhun tóun ò lè bá Jèhófà sọ, ó tiẹ̀ bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ nígbà tí ohun kan ń dùn ún lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, ọkàn Ábúráhámù ò balẹ̀ nígbà tí Jèhófà sọ pé òun máa pa ìlú Sódómù àti Gòmórà run. Kí ló fà á? Ẹ̀rù ń bà á kí àwọn èèyàn rere má lọ bá ìparun náà lọ. Ó sì ṣeé ṣe kí ọkàn rẹ̀ má balẹ̀ torí Lọ́ọ̀tì ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tóun àti ìdílé rẹ̀ ń gbé nílùú Sódómù. Ábúráhámù gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, “Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé,” torí náà, ó bá Jèhófà sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ nípa ohun tó ń dùn ún lọ́kàn. Jèhófà mú sùúrù fún ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó sì jẹ́ kó ṣe kedere sí i pé aláàánú lòun. Jèhófà jẹ́ kó yé e pé bí òun bá tiẹ̀ fẹ́ mú ìdájọ́ wá, òun á wá àwọn èèyàn rere kóun lè gbà wọ́n là.—Jẹ́nẹ́sísì 18:22-33.

12, 13. (a) Ọ̀nà míì wo tún ni àwọn ohun tí Ábúráhámù kọ́ nípa Jèhófà àtàwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i gbà ràn án lọ́wọ́? (b) Kí ló fi hàn pé Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà?

12 Kò sí àní-àní pé gbogbo ohun tí Ábúráhámù kọ́ nípa Jèhófà àtàwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i ni kò jẹ́ kí àjọṣe tó ní pẹ̀lú Jèhófà yingin. Torí náà, nígbà tí Jèhófà ní kí Ábúráhámù fi ọmọ rẹ̀ rúbọ, Ábúráhámù ò gbàgbé pé aláàánú ni Jèhófà, ó mọ̀ pé kò já òun kulẹ̀ rí àti pé ó máa ń mú sùúrù fún òun ó sì máa ń dáàbò bo òun. Ó dá Ábúráhámù lójú pé Jèhófà kì í ṣe ìkà tàbí òǹrorò! Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?

13 Nígbà tí Ábúráhámù sún mọ́ ibi tó ti fẹ́ fi ọmọ rẹ̀ rúbọ, ó sọ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ẹ dúró síhìn-ín ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ṣùgbọ́n èmi àti ọmọdékùnrin náà fẹ́ tẹ̀ síwájú lọ sí ọ̀hún yẹn láti jọ́sìn kí a sì padà wá bá yín.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:5) Kí ni Ábúráhámù ní lọ́kàn? Ṣé irọ́ ló ń pa nígbà tó sọ pé òun àti Ísákì á pa dà wá, nígbà tó mọ̀ pé òun máa fi rúbọ? Rárá. Bíbélì sọ pé Ábúráhámù mọ̀ pé Jèhófà lè jí Ísákì dìde tó bá tiẹ̀ kú. (Ka Hébérù 11:19.) Ábúráhámù mọ̀ pé Jèhófà ló jẹ́ kí òun àti Sárà bímọ lọ́jọ́ ogbó àwọn. (Hébérù 11:11, 12, 18) Torí náà, ó mọ̀ pé kò sí ohun tí Jèhófà ò lè ṣe. Ábúráhámù ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn, àmọ́ ó nígbàgbọ́ pé bí ọmọ òun bá tiẹ̀ kú, Jèhófà máa jí i dìde kí gbogbo ìlérí tí Ọlọ́run ṣe lè nímùúṣẹ. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe Ábúráhámù ní “baba gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́.”

Ábúráhámù nígbàgbọ́ pé bí ọmọ òun bá tiẹ̀ kú, Jèhófà máa jí i dìde kí gbogbo ìlérí tí Ọlọ́run ṣe lè nímùúṣẹ

14. Àwọn àdánwò wo lò ń kojú torí pé ò ń sin Jèhófà, báwo sì ni àpẹẹrẹ Ábúráhámù ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?

14 Jèhófà ò sọ pé ká fàwọn ọmọ wa rúbọ sí òun, àmọ́ ó ní ká pa àwọn àṣẹ òun mọ́. Nígbà míì, a lè máà lóye ìdí tí Jèhófà fi ní ká ṣe ohun kan, ó sì lè má rọrùn fún wa láti ṣègbọràn nígbà míì. Ṣé ó ti ṣe ẹ́ bẹ́ẹ̀ rí? Ó máa ń ṣòro fún àwọn kan láti wàásù. Ojú lè máa tì wọ́n kó má sì rọrùn fún wọn láti bá àwọn tí wọn ò mọ̀ rí sọ̀rọ̀. Àwọn míì ò sì fẹ́ dá yàtọ̀ láàárín àwọn ọ̀rẹ́ wọn níléèwé tàbí níbi iṣẹ́. (Ẹ́kísódù 23:2; 1 Tẹsalóníkà 2:2) Tí wọ́n bá ní kó o ṣe ohun kan tí kò rọrùn fún ẹ láti ṣe, ronú nípa bí Ábúráhámù ṣe lo ìgbàgbọ́ àti ìgboyà. Tá a bá ń ronú lórí àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ìyẹn á mú ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn, á sì mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, Ọ̀rẹ́ wa.—Hébérù 12:1, 2.

ÀJỌṢE TÓ Ń MÚ ÌBÙKÚN WÁ

15. Kí nìdí tó fi lè dá wa lójú pé Ábúráhámù ò kábàámọ̀ bó ṣe ṣègbọràn sí Jèhófà jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀?

15 Ǹjẹ́ Ábúráhámù fìgbà kan rí kábàámọ̀ bó ṣe ṣègbọràn sáwọn àṣẹ Jèhófà? Rárá o. Bíbélì sọ pé Ábúráhámù “kú ní ọjọ́ ogbó gidi gan-an, ó darúgbó, ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn.” (Jẹ́nẹ́sísì 25:8) Nígbà tí Ábúráhámù wà lẹ́ni ọdún márùndínlọ́gọ́sàn-án [175], ó ṣì lè rántí àwọn ohun tó fi ìgbésí ayé ẹ̀ ṣe kínú ẹ̀ sì dùn pé òun ti lo ìgbésí ayé òun lọ́nà tó dára jù lọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé, jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀, àjọṣe tímọ́tímọ́ tó ní pẹ̀lú Jèhófà ló ṣe pàtàkì sí i jù lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì sọ pé Ábúráhámù “darúgbó, ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn,” ìyẹn ò túmọ̀ sí pé Ábúráhámù ò fẹ́ gbé nínú ayé tuntun.

16. Àwọn nǹkan wo ló máa mú kí Ábúráhámù láyọ̀ nínú Párádísè?

16 Bíbélì sọ pé Ábúráhámù “ń dúró de ìlú ńlá tí ó ní àwọn ìpìlẹ̀ tòótọ́, ìlú ńlá tí olùtẹ̀dó àti olùṣẹ̀dá rẹ̀ jẹ́ Ọlọ́run.” (Hébérù 11:10) Ábúráhámù gbà gbọ́ pé, lọ́jọ́ kan, òun á rí ìlú yẹn, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run, nígbà tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ilẹ̀ ayé. Ó sì máa rí i lóòótọ́! Fojú inú wo bí inú Ábúráhámù á ṣe dùn tó nígbà tó bá ń gbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé tó sì ń mú kí àjọṣe tó ní pẹ̀lú Ọlọ́run máa lágbára sí i. Inú rẹ̀ á dùn gan-an láti mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ rẹ̀ ti ń ran àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́! Nínú Párádísè ló ti máa mọ̀ pé ohun ńlá kan ni ẹbọ tóun rú lórí Òkè Móráyà dúró fún. (Hébérù 11:19) Ó sì tún máa mọ bí ẹ̀dùn ọkàn tó ní nígbà tó fẹ́ fi Ísákì ọmọ rẹ̀ rúbọ ṣe ran ọ̀pọ̀ olóòótọ́ èèyàn lọ́wọ́ láti lóye bó ṣe dun Jèhófà tó nígbà tó fi Jésù Kristi Ọmọ Rẹ̀ rúbọ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà fún aráyé. (Jòhánù 3:16) Àpẹẹrẹ Ábúráhámù ti ran gbogbo wa lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọyì ìràpadà tó jẹ́ ọ̀nà pàtàkì jù lọ tí Jèhófà gbà fìfẹ́ hàn sí wa!

17. Kí lo pinnu láti ṣe, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

17 Ǹjẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa pinnu láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Ábúráhámù. Àwa náà nílò ìmọ̀ àti ìrírí bíi tiẹ̀. Bá a ṣe túbọ̀ ń mọ Jèhófà tá a sì ń ṣègbọràn sí i, àá máa rí bó ṣe ń bù kún wa tó sì ń dáàbò bò wá. (Ka Hébérù 6:10-12.) Ǹjẹ́ kí Jèhófà jẹ́ Ọ̀rẹ́ wa títí láé! Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ èèyàn mẹ́ta míì táwọn náà di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.

^ [1] (ìpínrọ̀ 3) Ábúrámù ni Ábúráhámù ń jẹ́ tẹ́lẹ̀, Sáráì sì ni Sárà ìyàwó rẹ̀ náà ń jẹ́ tẹ́lẹ̀. Àmọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí, Ábúráhámù àti Sárà tí Jèhófà sọ wọ́n la máa lò.