Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Jèhófà Ti Jẹ́ Kí N Ṣàṣeyọrí Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Rẹ̀

Jèhófà Ti Jẹ́ Kí N Ṣàṣeyọrí Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Rẹ̀

Mo sọ fún sójà náà pé mo ti lọ sẹ́wọ̀n rí torí mo kọ̀ jálẹ̀ pé mi ò ní jagun. Mo bi í pé, “Ṣé ẹ tún fẹ́ rán mi lọ sẹ́wọ̀n ni?” Ìgbà kejì tí wọ́n máa pàṣẹ fún mi pé kí n wá di ọ̀kan lára àwọn Ọmọ Ogun Ilẹ̀ Amẹ́ríkà rèé.

ÌLÚ Crooksville, ìpínlẹ̀ Ohio lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n bí mi sí lọ́dún 1926. Bàbá àti ìyá wa ò fẹ́ràn ìsìn, àmọ́ wọ́n máa ń sọ fáwa ọmọ wọn mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ pé ká máa lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Ṣọ́ọ̀ṣì Mẹ́tọ́díìsì ni mò ń lọ. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá, pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì wa fún mi lẹ́bùn torí jálẹ̀ gbogbo ọdún yẹn ni mo fi lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì láìpa Sunday kankan jẹ.

Margaret Walker (arábìnrin kejì láti apá òsì) ló kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́

Láàárín àkókò yẹn, obìnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wà tá a jọ ń gbé ládùúgbò, Margaret Walker lorúkọ ẹ̀, ó máa ń wá wàásù fún màmá mi nílé wa. Lọ́jọ́ kan, mo lọ jókòó tì wọ́n níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. Màmá mi rò pé mo fẹ́ pàkúta sí ìjíròrò àwọn ni, wọ́n bá lé mi jáde. Àmọ́ mo fara pa mọ́ síbì kan, mò ń fetí kọ́ ohun tí wọ́n ń sọ. Lẹ́yìn ìgbà mélòó kan tí Margaret ti ń wá, ó bi mí pé, “Ǹjẹ́ o mọ orúkọ Ọlọ́run?” Mo ní, “Hábà, ta ni ò mọ̀yẹn, Ọlọ́run ni kẹ̀!” Ó ní, “Lọ gbé Bíbélì ẹ, kó o ka Sáàmù 83:18.” Mo kà á lóòótọ́, mo wá rí i pé Jèhófà lorúkọ Ọlọ́run. Mo bá sáré lọ bá àwọn ọ̀rẹ́ mi, mo sọ fún wọn pé, “Tẹ́ ẹ bá délé lálẹ́ yìí, ẹ ṣí Bíbélì yín, kẹ́ ẹ ka Sáàmù 83:18, ẹ máa rí orúkọ Ọlọ́run níbẹ̀.” Ẹ̀ ẹ́ ní mo ti yáa bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù nìyẹn.

Wọ́n kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1941. Kò pẹ́ sígbà yẹn tí wọ́n fi ní kí n máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ. Mo ní kí ìyá mi, àwọn ẹ̀gbọ́n àtàwọn àbúrò mi náà máa wá sí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ tí mò ń darí. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá, àmọ́ Dádì kì í wá ní tiwọn.

OHUN TÓJÚ MI RÍ NÍLÉ

Wọ́n fún mi ní iṣẹ́ púpọ̀ sí i láti bójú tó nínú ìjọ, mo sì gba ọ̀pọ̀ lára ìtẹ̀jáde táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe. Lọ́jọ́ kan, Dádì nawọ́ sáwọn ìwé mi, wọ́n ní: “Ṣó o rí gbogbo ìwé tó o kó jọ síbí? Mi ò fẹ́ rí wọn nínú ilé yìí mọ́, ìwọ náà sì lè kó jáde tó bá wù ẹ́.” Mo kó jáde lóòótọ́, mo sì lọ ń gbé nílùú kan tí ò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sílé, ìyẹn ìlú Zanesville, ìpínlẹ̀ Ohio, àmọ́ mo máa ń wá sílé lọ́pọ̀ ìgbà kí n lè máa fún àwọn ará ilé mi níṣìírí.

Dádì fojú Mọ́mì han èèmọ̀ kí wọ́n má bàa lọ sípàdé mọ́. Nígbà míì, tí Mọ́mì bá ń lọ sípàdé, Dádì á sáré lé wọn mú, wọ́n á sì fà wọ́n pa dà sílé. Àmọ́ Mọ́mì á yọ́ gba ẹ̀yìnkùlé ní tiwọn, wọ́n á sì gbabẹ̀ lọ sípàdé. Mo sọ fún Mọ́mì pé: “Ẹ fọkàn balẹ̀, ó máa tó sú wọn.” Nígbà tó yá, ó sú wọn lóòótọ́, wọn ò da Mọ́mì láàmú mọ́, Mọ́mì sì ń lọ sípàdé bó ṣe wù wọ́n.

Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run nígbà tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1943. Ìmọ̀ràn tí wọ́n máa ń fún mi nígbà tí mo bá ṣiṣẹ́ nílé ẹ̀kọ́ yìí mú kí n di sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńtọ́.

MO KỌ̀ JÁLẸ̀ PÉ MI Ò NÍ JAGUN

Lọ́dún 1944, nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, wọ́n ní kí n wá wọṣẹ́ ológun. Mo lọ sí Fort Hayes, ìyẹn ọgbà àwọn sójà tó wà nílùú Columbus, ìpínlẹ̀ Ohio, wọ́n ṣe àwọn àyẹ̀wò kan fún mi, wọ́n sì ní kí n kọ̀rọ̀ kún àwọn fọ́ọ̀mù kan. Mo wá sọ fáwọn sójà tó wà níbẹ̀ pé èmi ò ní wọṣẹ́ ológun ní tèmi o. Wọ́n bá ní kí n máa lọ. Àmọ́ ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, sójà kan wá sílé mi, ó sì sọ fún mi pé, “Ọ̀gbẹ́ni Corwin Robison, ìjọba ti fún mi láṣẹ láti mú ẹ.”

Ní ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà, wọ́n gbé mi lọ sílé ẹjọ́. Adájọ́ sọ fún mi pé: “Tí wọ́n bá fi dídàá mi, ẹ̀wọ̀n gbére ni màá dá fún ẹ. Ṣó o ní ohunkóhun láti sọ?” Mo ní: “Olúwa Mi, òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni mí. Ṣe ni mo máa ń wàásù láti ilé dé ilé, mo sì ti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ èèyàn.” Adájọ́ wá sọ fún ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ pé: “Kì í ṣe torí ká lè mọ̀ bóyá òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí tàbí kì í ṣe òjíṣẹ́ lẹ ṣe wà níbí. Ohun tẹ́ ẹ wá ṣe níbí ni pé kẹ́ ẹ sọ bóyá ó lọ síbi tí wọ́n ti ní kó wá wọṣẹ́ ológun àbí kò lọ.” Kò pé ọgbọ̀n ìṣẹ́jú tí ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ náà fi sọ pé mo jẹ̀bi. Adájọ́ wá ní kí n lọ ṣẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún gbáko ní ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà nílùú Ashland, ìpínlẹ̀ Kentucky.

JÈHÓFÀ DÁÀBÒ BÒ MÍ LỌ́GBÀ Ẹ̀WỌ̀N

Ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà nílùú Columbus ní ìpínlẹ̀ Ohio ni mo ti lo ọ̀sẹ̀ méjì àkọ́kọ́, inú ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi mí sí ni mo wà ṣúlẹ̀ ọjọ́ tí mo kọ́kọ́ débẹ̀. Mo gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Mi ò lè wà nínú ẹ̀wọ̀n fún ọdún márùn-ún. Mi ò mọ ohun tí màá ṣe o.”

Lọ́jọ́ kejì, àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ṣí mi sílẹ̀ kí n lè rìn yí ká ọgbà náà. Mo rìn lọ síbi tí ọkùnrin kan wà, Paul lorúkọ ẹ̀, ó ga gan-an, ó sì tún nígẹ̀, a jọ dúró sójú fèrèsé kan. Ó ní, “Kúrú-n-béte! Kí lo wá ṣe ńbí?” Mo ní, “Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí.” Ó ní, “Ṣé pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́? Kí ló wá gbé ẹ débí?” Mo ní, “Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í jagun, a kì í sì í pààyàn.” Ó ní, “Ẹ̀-ẹ́n! Wọ́n jù ẹ́ sẹ́wọ̀n torí pé o ò fẹ́ pààyàn. Torí pé àwọn míì pààyàn ni wọ́n sì ṣe jù wọ́n sẹ́wọ̀n. Ṣé ohun tí wọ́n ṣe yẹn mọ́gbọ́n dání ṣá?” Mo ní, “Rárá, kò mú ọpọlọ dání.”

Ó wá sọ fún mi pé, “Mo ti lo ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] lọ́gbà ẹ̀wọ̀n kan, ibẹ̀ ni mo sì ti ka àwọn kan lára àwọn ìwé yín.” Bí mo ṣe gbọ́ ìyẹn ni mo bá bẹ Jèhófà pé, “Jèhófà, jọ̀ọ́ jẹ́ kí n rójú rere ọ̀gbẹ́ni yìí o.” Lójú ẹsẹ̀, Paul sọ pé: “Bí èyíkéyìí nínú àwọn ọkùnrin yìí bá fọwọ́ kàn ẹ́ pẹ́nrẹ́n, ìwọ ṣáà lọgun pè mí. Màá ṣe wọ́n bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú.” Torí náà, ní gbogbo ìgbà tí mo fi wà níbẹ̀, ẹnikẹ́ni nínú àwọn àádọ́ta [50] ẹlẹ́wọ̀n tó wà níbẹ̀ ò fọwọ́ kàn mí.

Mo wà lára àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n nílùú Ashland, ìpínlẹ̀ Kentucky torí pé a ò wọṣẹ́ ológun

Nígbà táwọn aláṣẹ gbé mi lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà nílùú Ashland, mo bá àwọn arákùnrin kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn pà dé níbẹ̀. Wọ́n ran èmi àtàwọn míì lọ́wọ́ kí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà má bàa bà jẹ́. Wọ́n máa ń yan Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ fún wa, á tún máa ń múra àwọn ìbéèrè àti ìdáhùn tá a máa jíròrò nígbà tá a bá kóra jọ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Inú ẹ̀wọ̀n kan tó tóbi tó sì tún ní àwọn bẹ́ẹ̀dì tí wọ́n tò sẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri la wà. Arákùnrin kan wà tó máa ń ṣètò ìpínlẹ̀ ìwàásù fún wa. Á sọ fún mi pé: “Robison, ìwọ lo máa wàásù fáwọn tó ń lo bẹ́ẹ̀dì báyìí báyìí. Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá ní kó máa lo bẹ́ẹ̀dì yẹn ni ìpínlẹ̀ ìwàásù rẹ. Rí i dájú pé o wàásù fún un kó tó lọ.” Bá a ṣe ṣètò iṣẹ́ ìwàásù wa lọ́nà tó wà létòlétò nìyẹn.

ÀWỌN ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO RÍ LẸ́YÌN TÍ MO KÚRÒ LỌ́GBÀ Ẹ̀WỌ̀N

Ogun Àgbáyé Kejì parí lọ́dún 1945, àmọ́ mo ṣì wà lẹ́wọ̀n fúngbà díẹ̀ lẹ́yìn náà. Mò ń ronú nípa màmá mi, àwọn ẹ̀gbọ́n mi àtàwọn àbúrò mi, torí Dádì ti sọ fún mi pé, “Tí mo bá ṣáà ti rọ́gbọ́n dá sọ́rọ̀ tìẹ, kékeré ni tàwọn tó kù.” Àmọ́, ìròyìn ayọ̀ kan ni mo bá nílé lẹ́yìn tí wọ́n dá mi sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ó sì yà mí lẹ́nu gan-an. Láìka gbogbo kùkùfẹ̀fẹ̀ Dádì sí, méje lára àwọn tó wà nínú ìdílé wa ló ti ń lọ sípàdé, ọ̀kan lára wọn sì ti ṣèrìbọmi.

Èmi àti Arákùnrin Demetrius Papageorge tó jẹ́ ẹni àmì òróró jọ ń lọ sóde ẹ̀rí, ọdún 1913 ló bẹ̀rẹ̀ sí í sin Jèhófà

Nígbà tí Ogun Kòríà bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1950, wọ́n tún ní kí n wá wọṣẹ́ ológun. Wọ́n ní kí n tún máa bọ̀ ní Fort Hayes. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣe ìdánwò ráńpẹ́ kan fún wa, sójà kan sọ fún mi pé, “O wà lára àwọn tó ṣe dáadáa jù.” Mo ní, “Ìyẹn dáa, àmọ́ mi ò ní wọṣẹ́ ológun.” Mo sọ ohun tó wà nínú 2 Tímótì 2:3 fún un, mo wá sọ fún un pé, “Ọmọ ogun Kristi ni mí.” Ó kọ́kọ́ dákẹ́ lọ gbári, lẹ́yìn náà, ó wá sọ pé, “O lè máa lọ.”

Ní àkókò díẹ̀ lẹ́yìn náà, mo lọ sí ìpàdé tí wọ́n máa ń ṣe pẹ̀lú àwọn tó fẹ́ láti sìn ní Bẹ́tẹ́lì ní àpéjọ àgbègbè tó wáyé ní ìlú Cincinnati, ìpínlẹ̀ Ohio. Arákùnrin Milton Henschel sọ fún wa pé wọ́n nílò àwọn ará tó múra tán láti ṣiṣẹ́ kára fún Ìjọba Ọlọ́run ní Bẹ́tẹ́lì. Mo gba fọ́ọ̀mù Bẹ́tẹ́lì, wọ́n sì pè mí. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ sìn ní oríléeṣẹ́ wa ní Brooklyn lọ́dún 1954, àtìgbà yẹn ni mo sì ti wà ní Bẹ́tẹ́lì.

Oríṣiríṣi iṣẹ́ ni mo ti ṣe ní Bẹ́tẹ́lì. Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi ṣiṣẹ́ nídìí àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń pèsè omi gbígbóná, mo sì máa ń tún àwọn ẹ̀rọ àti kọ́kọ́rọ́ ṣe. Mo tún ṣiṣẹ́ láwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó wà nílùú New York City.

Ìgbà tí mò ń ṣiṣẹ́ nídìí àwọn ẹ̀rọ tó ń pèsè omi gbígbóná ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn

Mo fẹ́ràn ètò tó wà fún kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Bẹ́tẹ́lì, irú bí ìjọsìn òwúrọ̀ àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tí ìdílé Bẹ́tẹ́lì máa ń ṣe, mo sì tún fẹ́ràn láti máa jáde òde ẹ̀rí pẹ̀lú àwọn ará ìjọ mi. Tá a bá wò ó dáadáa, gbogbo ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló yẹ kó máa ṣe àwọn nǹkan yìí déédéé. Táwọn òbí àtàwọn ọmọ wọn bá jọ ń ṣàyẹ̀wò ìkẹ́kọ̀ọ́ ojoojúmọ́, tí wọ́n ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé wọn déédéé, tí wọ́n ń dáhùn nípàdé, tí wọ́n sì ń fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé náà á ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.

Mo ti láwọn ọ̀rẹ́ rẹpẹtẹ ní Bẹ́tẹ́lì àti nínú ìjọ. Ẹni àmì òróró làwọn kan lára wọn, wọ́n sì ti lọ sọ́run. Àwọn tó kù kì í ṣe ẹni àmì òróró. Àmọ́, aláìpé ni gbogbo àwa ìránṣẹ́ Jèhófà títí kan àwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì. Tí n bá ní èdèkòyédè pẹ̀lú ẹnì kan, mo máa ń wá bá a ṣe máa tètè yanjú ẹ̀. Mo máa ń ronú nípa ohun tó wà nínú Mátíù 5:23, 24 àti bó ṣe yẹ ká máa yanjú èdèkòyédè. Kò rọrùn láti sọ pé, “Ẹ máà bínú,” àmọ́ ohun tó ń yanjú ọ̀pọ̀ èdèkòyédè nìyẹn.

IṢẸ́ ÌSÌN MI MÉRÈ WÁ

Ara ti di ara àgbà báyìí, kò sì rọrùn fún mi láti máa wàásù láti ilé dé ilé bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, síbẹ̀ náà, mo ṣì ń wàásù. Mo gbọ́ èdè Mandarin Chinese díẹ̀, mo sì máa ń wàásù fáwọn ọmọ ilẹ̀ Ṣáínà tó ń kọjá ní òpópónà. Láwọn àárọ̀ ọjọ́ míì, mo máa ń fi ìwé ìròyìn tó tó ọgbọ̀n [30] tàbí ogójì [40] síta.

Èmi rèé ní ìlú Brooklyn, ìpínlẹ̀ New York, níbi tí mo ti ń wàásù fáwọn ọmọ ilẹ̀ Ṣáínà

Mo tiẹ̀ ti ṣe ìpadàbẹ̀wò rí ní orílẹ̀-èdè Ṣáínà! Lọ́jọ́ kan, ọmọbìnrin kan ń polówó àtẹ́ tí wọ́n fi ń ta èso, ó rẹ́rìn-ín músẹ́ sí mi, èmi náà rẹ́rìn-ín sí i pa dà, mo sì fún un ní ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lédè Ṣáínà. Ó gbà á, ó wá sọ pé Katie lorúkọ òun. Látìgbà yẹn, ó máa ń yà lọ́dọ̀ mi tó bá ń kọjá lọ. Mo kọ́ ọ lórúkọ tí wọ́n ń pe àwọn èso lóríṣiríṣi àtàwọn ewébẹ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì, ó sì máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ náà tẹ̀ lé mi. Mo tún máa ń ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Bíbélì fún un, ó sì gba ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àmọ́ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mélòó kan, mi ò rí i mọ́.

Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, mo fún ọmọbìnrin míì tó ń polówó ọjà ní ìwé ìròyìn, ó sì gbà á. Ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, ó yà lọ́dọ̀ mi bó ti ń kọjá lọ, ó gbé fóònú rẹ̀ fún mi, ó ní, “Ẹ bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ ní Ṣáínà.” Mo ní, “Mi ò mọ èèyàn kankan ní Ṣáínà.” Àmọ́, ó ní kí n ṣáà gbà, mo bá gba fóònù náà, mo ní, “Ẹ ǹlẹ́ o, Robison ló ń sọ̀rọ̀ o.” Ẹni tó wà lórí fóònù náà wá sọ pé, “Robby, èmi Katie ni. Mo ti pa dà sí Ṣáínà.” Mo ní, “Ṣáínà kẹ̀?” Katie dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni. Robby, ṣó o rí ọmọbìnrin tó gbé fóònú fún ẹ yẹn, àbúrò mi ni. Mi ò jẹ́ gbàgbé àwọn nǹkan tó o kọ́ mi. Jọ̀ọ́ bá mi kọ́ òun náà bó o ṣe kọ́ mi.” Mo ní, “Katie, fọkàn balẹ̀, màá ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe. O ṣeun tó o jẹ́ kí n mọ ibi tó o wà.” Mo bá àbúrò Katie sọ̀rọ̀, àmọ́ kò pẹ́ lẹ́yìn náà, kó tó di pé mi ò rí i mọ́. Ibikíbi tí àwọn ọmọbìnrin méjèèjì bá wà báyìí, mo gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa òun.

Ọdún mẹ́tàléláàádọ́rin [73] ni mo ti ń sin Jèhófà bọ̀ báyìí, inú mi dùn pé Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ tí mi ò fi wọṣẹ́ ológun, kò sì jẹ́ kí àjọṣe tí mo ní pẹ̀lú òun bà jẹ́ ní gbogbo ọdún tí mo lò lẹ́wọ̀n. Bákan náà, àwọn ẹ̀gbọ́n mi àtàwọn àbúrò mi máa ń sọ fún mi pé bí mi ò ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Dádì sú mi wú àwọn lórí gan-an. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Màámi àti mẹ́fà lára àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò mi ṣèrìbọmi. Kódà, ìwà Dádì yí pa dà nígbà tó yá, àwọn náà bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé kí wọ́n tó kú.

Tó bá jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà, àwọn mẹ́ńbà ìdílé mi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi tó ti kú máa pa dà wà láàyè nínú ayé tuntun. Ó dájú pé ayọ̀ ọ̀hún á pọ̀ nígbà tí àwa àtàwọn èèyàn wa bá jọ ń sin Jèhófà títí láé! *—Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.

^ ìpínrọ̀ 32 Arákùnrin Corwin Robison kú nígbà tá à ń ṣètò láti tẹ àpilẹ̀kọ yìí jáde, àmọ́ ó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà títí dójú ikú.