Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà Tó Jẹ́ Adúróṣinṣin
“Kí . . . ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí o sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?”—MÍKÀ 6:8.
ORIN: 63, 43
1, 2. Báwo ni Dáfídì ṣe fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
SỌ́Ọ̀LÙ àti àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọmọ ogun rẹ̀ ń wá Dáfídì nínú aginjù Júdà kí wọ́n lè pa á. Àmọ́ lálẹ́ ọjọ́ kan, Dáfídì àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ rí ibi tí Sọ́ọ̀lù àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ pàgọ́ sí. Gbogbo wọn ti sùn lọ fọnfọn, bí Dáfídì àti Ábíṣáì ṣe yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ gba àárín àwọn ọmọ ogun náà kọjá títí wọ́n fi dé ibi tí Sọ́ọ̀lù sùn sí nìyẹn. Ábíṣáì rọra sọ fún Dáfídì pé: “Jẹ́ kí n fi ọ̀kọ̀ gún un mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo péré, èmi kì yóò sì ṣe é sí i lẹ́ẹ̀mejì.” Àmọ́, Dáfídì ò jẹ́ kí Ábíṣáì pa Sọ́ọ̀lù. Dáfídì wá sọ fún Ábíṣáì pé: “Má ṣe run ún, nítorí ta ni ó na ọwọ́ rẹ̀ sí ẹni àmì òróró Jèhófà tí ó sì wà ní aláìmọwọ́-mẹsẹ̀?” Lẹ́yìn náà Dáfídì sọ fún un pé: “Kò ṣeé ronú kàn, níhà ọ̀dọ̀ mi, ní ojú ìwòye Jèhófà, láti na ọwọ́ mi sí ẹni àmì òróró Jèhófà!”—1 Sámúẹ́lì 26:8-12.
2 Dáfídì mọ bóun ṣe lè fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Ó mọ̀ pé ó pọn dandan kóun bọ̀wọ̀ fún Sọ́ọ̀lù, kò sì ronú láti pa á. Kí nìdí? Torí pé Ọlọ́run ti yan Sọ́ọ̀lù láti jẹ́ ọba ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Lónìí, bíi ti àtijọ́, Jèhófà fẹ́ kí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ òun jẹ́ adúróṣinṣin sí òun kí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún àwọn tí òun ti fi sípò àṣẹ.—Ka3. Báwo ni Ábíṣáì ṣe jẹ́ adúróṣinṣin sí Dáfídì?
3 Ábíṣáì bọ̀wọ̀ fún Dáfídì torí ó mọ̀ pé Ọlọ́run ti yan Dáfídì láti di ọba. Síbẹ̀, Dáfídì dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì lẹ́yìn tó di ọba. Ó bá ìyàwó Ùráyà sùn, ó sì sọ fún Jóábù pé kó rí i dájú pé Ùráyà kú sójú ogun. (2 Sámúẹ́lì 11:2-4, 14, 15; 1 Kíróníkà 2:16) Arákùnrin Jóábù ni Ábíṣáì, torí náà ó ṣeé ṣe kí Ábíṣáì gbọ́ nípa ohun tí Dáfídì ṣe yẹn, àmọ́ kò fìyẹn pè, ó ṣì ń bọ̀wọ̀ fún Dáfídì. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀gágun ni Ábíṣáì, ó sì lè pinnu láti sọ ara rẹ̀ di ọba, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sin Dáfídì, ó sì dáàbò bò ó lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.—2 Sámúẹ́lì 10:10; 20:6; 21:15-17.
4. (a) Kí ló mú kí Dáfídì jẹ́ àpẹẹrẹ ìdúróṣinṣin? (b) Àwọn àpẹẹrẹ míì wo la máa jíròrò?
4 Dáfídì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. Nígbà tó wà lọ́mọdé, ó pa Gòláyátì òmìrán tó ń sọ̀rọ̀ òdì sí Jèhófà àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (1 Sámúẹ́lì 17:23, 26, 48-51) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọba ni Dáfídì, wòlíì Jèhófà tó ń jẹ́ Nátánì bá a wí nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Dáfídì gbà pé òun ti ṣẹ̀, ó sì ronú pìwà dà. (2 Sámúẹ́lì 12:1-5, 13) Nígbà tí Dáfídì darúgbó, ó fi ọ̀pọ̀ nǹkan iyebíye ṣètọrẹ kí wọ́n lè fi kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà. (1 Kíróníkà 29:1-5) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì ṣe àwọn àṣìṣe tó burú jáì, ó ṣe kedere pé ó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. (Sáàmù 51:4, 10; 86:2) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àpẹẹrẹ Dáfídì àtàwọn míì tó gbé ayé nígbà yẹn, a sì máa mọ bá a ṣe lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà ju ẹnikẹ́ni míì lọ. A tún máa jíròrò àwọn ànímọ́ míì táá mú ká jẹ́ adúróṣinṣin.
ṢÉ WÀÁ JẸ́ ADÚRÓṢINṢIN SÍ JÈHÓFÀ?
5. Kí la rí kọ́ látinú àṣìṣe tí Ábíṣáì ṣe?
5 Ńṣe ni Ábíṣáì ń fi hàn pé ti Dáfídì lòun ń ṣe nígbà tó fẹ́ pa Sọ́ọ̀lù. Àmọ́ torí pé Dáfídì mọ̀ pé kò tọ́ kí òun pa “ẹni àmì òróró Jèhófà,” kò jẹ́ kí Ábíṣáì pa Sọ́ọ̀lù Ọba. (1 Sámúẹ́lì 26:8-11) Ẹ̀kọ́ pàtàkì lèyí kọ́ wa, ìyẹn ni pé tó bá di pé ká pinnu ẹni tá a máa kọ́kọ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí, ó yẹ ká ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́.
Ó ṣe pàtàkì ká jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà ju ká jẹ́ adúróṣinṣin sí ẹnikẹ́ni míì
6. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a máa ń fẹ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí àwọn mẹ́ńbà ìdílé wa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa, kí nìdí tó fi yẹ ká ṣọ́ra?
6 A máa ń fẹ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí àwọn tó sún mọ́ wa, bí àwọn ọ̀rẹ́ wa tàbí àwọn mẹ́ńbà ìdílé wa. Àmọ́, torí pé aláìpé ni wá, a máa ń ronú lọ́nà tí kò tọ́ nígbà míì. (Jeremáyà 17:9) Torí náà, bí ẹnì kan tó sún mọ́ wa bá ń ṣàìtọ́, tó sì fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀, ó yẹ ká rántí pé ó ṣe pàtàkì ká jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà ju ká jẹ́ adúróṣinṣin sí ẹnikẹ́ni míì.—Ka Mátíù 22:37.
7. Báwo ni arábìnrin kan ṣe jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà nígbà tí nǹkan le koko?
7 Tí wọ́n bá ti yọ ẹnì kan nínú ìdílé rẹ lẹ́gbẹ́, ìwọ náà lè ṣe ohun tó fi hàn pé o jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, Màmá Anne tí wọ́n ti yọ lẹ́gbẹ́ pe Anne lórí fóònù, ó sì sọ pé òun fẹ́ wá kí i nílé. [1] (Wo àfikún àlàyé.) Màmá Anne sọ pé inú òun ò dùn torí pé gbogbo wọn kì í bá òun sọ̀rọ̀. Ọ̀rọ̀ yìí ba Anne nínú jẹ́, ó wá sọ pé òun máa kọ lẹ́tà sí màmá òun nípa ọ̀rọ̀ náà. Kó tó kọ lẹ́tà náà, ó ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì kan. (1 Kọ́ríńtì 5:11; 2 Jòhánù 9-11) Nínú lẹ́tà náà, Anne ṣàlàyé lọ́nà pẹ̀lẹ́ pé ìyá òun gan-an ló pa gbogbo mẹ́ńbà ìdílé tì nígbà tó ṣẹ̀ tó sì kọ̀ láti ronú pìwà dà. Anne wá jẹ́ kí ìyá rẹ̀ mọ̀ pé ohun kan ṣoṣo tó lè mú kó tún láyọ̀ ni pé kó pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.—Jákọ́bù 4:8.
8. Àwọn ànímọ́ wo ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run?
8 Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nígbà ayé Dáfídì tún jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, onínúure àti onígboyà. Ẹ jẹ́ ká jíròrò bí àwọn ànímọ́ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà.
A GBỌ́DỌ̀ JẸ́ ONÍRẸ̀LẸ̀
9. Kí nìdí tí Ábínérì fi gbìyànjú láti pa Dáfídì?
9 Ó dájú pé Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù àti Ábínérì olórí ọmọ ogun Ísírẹ́lì rí Dáfídì nígbà tó gbé orí Gòláyátì wá fún Sọ́ọ̀lù Ọba. Jónátánì di ọ̀rẹ́ Dáfídì ó sì dúró tì í nígbà ìṣòro. (1 Sámúẹ́lì 17:57–18:3) Àmọ́, Ábínérì ò ṣe bẹ́ẹ̀ ní tiẹ̀. Kódà, Ábínérì tún ran Sọ́ọ̀lù lọ́wọ́ nígbà tó ń wá ọ̀nà láti pa Dáfídì. (1 Sámúẹ́lì 26:1-5; Sáàmù 54:3) Jónátánì àti Ábínérì mọ̀ pé Dáfídì ni Ọlọ́run ti yàn láti jẹ́ ọba Ísírẹ́lì lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù. Àmọ́, lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù kú, Ábínérì ò ti Dáfídì lẹ́yìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló gbìyànjú láti fi Iṣibóṣẹ́tì, ọmọ Sọ́ọ̀lù, jọba. Lẹ́yìn náà, ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí Ábínérì fúnra rẹ̀ fẹ́ di ọba, bóyá torí ẹ̀ ló ṣe bá ọ̀kan lára àwọn ìyàwó Sọ́ọ̀lù Ọba sùn. (2 Sámúẹ́lì 2:8-10; 3:6-11) Kí nìdí tí èrò tí Jónátánì ní nípa Dáfídì fi yàtọ̀ sí ti Ábínérì? Ìdí ni pé Jónátánì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà ó sì lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, àmọ́ Ábínérì ò lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ kì í sì í ṣe adúróṣinṣin.
10. Kí ló fi hàn pé Ábúsálómù ò jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run?
10 Ábúsálómù ọmọ Dáfídì Ọba jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run torí pé kò lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Ó fẹ́ di ọba, torí náà ó ṣe “kẹ̀kẹ́ ẹṣin kan fún ara rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ẹṣin àti pẹ̀lú àádọ́ta ọkùnrin tí ń sáré níwájú rẹ̀.” (2 Sámúẹ́lì 15:1) Ó tiẹ̀ yí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lérò pa dà kí wọ́n lè tì í lẹ́yìn. Kódà, ó tún gbìyànjú láti pa bàbá rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ pé Jèhófà ti fi Dáfídì jẹ ọba Ísírẹ́lì.—2 Sámúẹ́lì 15:13, 14; 17:1-4.
11. Kí la kọ́ látinú ohun tí Bíbélì sọ nípa Ábínérì, Ábúsálómù àti Bárúkù?
11 Tí ẹnì kan ò bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tó sì fẹ́ dé ipò ńlá, ó máa ṣòro fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run. Lóòótọ́, a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a ò sì fẹ́ jẹ́ onímọtara ẹni nìkan àti ìkà bíi ti Ábínérì àti Ábúsálómù. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ wà lójúfò kí ìfẹ́ owó má lọ kó sí wa lórí tàbí ká máa lé iṣẹ́ táá jẹ́ káwọn èèyàn máa fojú pàtàkì wò wá. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa ba àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà jẹ́. Láwọn àkókò kan, Bárúkù tó jẹ́ akọ̀wé Jeremáyà ń fi gọ̀gọ̀ fa ohun tọ́wọ́ rẹ̀ kò tó, kò sì wá láyọ̀ mọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Jèhófà wá sọ fún Bárúkù pé: “Wò ó! Ohun ti mo kọ́ ni èmi yóò ya lulẹ̀, ohun tí mo sì gbìn ni èmi yóò fà tu, àní gbogbo ilẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n ní tìrẹ, ìwọ ń wá àwọn ohun ńláńlá fún ara rẹ. Má ṣe wá wọn mọ́.” (Jeremáyà 45:4, 5) Bárúkù tẹ́tí sí Jèhófà. Àwa náà sì gbọ́dọ̀ tẹ́tí sí i, torí láìpẹ́ Jèhófà máa pa ayé búburú yìí run.
12. Kí nìdí tá ò fi lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run tá a bá jẹ́ onímọtara ẹni nìkan?
12 Ó di dandan fún Arákùnrin Daniel tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò láti pinnu ẹni tó máa jẹ́ adúróṣinṣin sí. Ó fẹ́ fẹ́ obìnrin kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Arákùnrin Daniel sọ pé: “Mo ṣì ń kọ lẹ́tà sí i kódà lẹ́yìn tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.”
Àmọ́, ó wá rí i pé tinú òun lòun ń ṣe, òun ò jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, òun sì gbọ́dọ̀ rẹ ara òun sílẹ̀. Torí náà, ó sọ fún alàgbà kan nípa ọmọbìnrin náà. Arákùnrin Daniel wá sọ pé: “Alàgbà náà jẹ́ kí n mọ̀ pé tí mo bá máa jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run, mi ò ní kọ lẹ́tà sí i mọ́. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ àdúrà àti ẹkún, ohun tí mo ṣe gan-an nìyẹn. Ayọ̀ tí mo ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn mi wá pọ̀ sí i.” Arákùnrin Daniel ti di alábòójútó àyíká báyìí, ó sì ti fẹ́ ìyàwó tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.JẸ́ ADÚRÓṢINṢIN SÍ JÈHÓFÀ KÓ O SÌ JẸ́ ONÍNÚURE
13. Nígbà tí Dáfídì ṣẹ̀, báwo ni Nátánì ṣe jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run àti sí Dáfídì?
13 Tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, a lè ran àwọn míì lọ́wọ́ ká sì dúró tì wọ́n bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Wòlíì Nátánì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà àti sí Dáfídì. Lẹ́yìn tí Dáfídì gba ìyàwó Ùráyà tó sì pa ọkọ rẹ̀, Jèhófà ní kí Nátánì lọ bá Dáfídì wí. Nátánì lo ìgboyà ó sì ṣe ohun tí Jèhófà ní kó ṣe. Àmọ́, ó fọgbọ́n sọ̀rọ̀, ó sì fi ohùn pẹ̀lẹ́ bá Dáfídì wí. Ó fẹ́ kí Dáfídì rí bí ohun tó ṣe ṣe burú tó, torí náà ó sọ ìtàn nípa ọkùnrin olówó kan tó jí àgùntàn kan ṣoṣo tí tálákà kan ní fún un. Nígbà tí Dáfídì gbọ́ ìtàn náà, inú bí i gidigidi sí ohun tí ọkùnrin olówó náà ṣe. Nátánì wá sọ fún un pé: “Ìwọ fúnra rẹ ni ọkùnrin náà!” Dáfídì wá rí i pé òun ti ṣẹ̀ sí Jèhófà.—2 Sámúẹ́lì 12:1-7, 13.
14. Báwo lo ṣe lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà àtàwọn ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí rẹ?
14 Ìwọ náà lè kọ́kọ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, kó o sì tún jẹ́ onínúure sáwọn tó sún mọ́ ẹ. Bí àpẹẹrẹ, o lè ní ẹ̀rí tó dájú pé arákùnrin kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì. O lè máà fẹ́ tú àṣírí rẹ̀ pàápàá tó bá jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ tàbí mẹ́ńbà ìdílé rẹ. Síbẹ̀, o mọ̀ pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Torí náà, bíi ti Nátánì, ṣègbọràn sí Jèhófà kó o sì jẹ́ onínúure sí arákùnrin rẹ. Sọ fún un pé kó tètè lọ sọ ohun tó ṣe fáwọn alàgbà kí wọ́n lè ràn án lọ́wọ́. Tó bá kọ̀, kí ìwọ fúnra rẹ lọ sọ fáwọn alàgbà. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá fi hàn pé o jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Lẹ́sẹ̀ kan náà, o ti fi inú rere hàn sí arákùnrin rẹ torí àwọn alàgbà máa ràn án lọ́wọ́ kó lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Àwọn alàgbà náà á sì fìfẹ́ tọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ sọ́nà.—Ka Léfítíkù 5:1; Gálátíà 6:1.
A GBỌ́DỌ̀ JẸ́ ONÍGBOYÀ TÁ A BÁ FẸ́ JẸ́ ADÚRÓṢINṢIN SÍ ỌLỌ́RUN
15, 16. Kí nìdí tí Húṣáì fi gbọ́dọ̀ jẹ́ onígboyà tó bá fẹ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà?
15 Ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ Dáfídì Ọba tó jẹ́ adúróṣinṣin ni Húṣáì. Nígbà táwọn èèyàn fẹ́ fi Ábúsálómù jọba, Húṣáì nílò ìgboyà kó lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Dáfídì àti 2 Sámúẹ́lì 15:13; 16:15) Àmọ́, kí ni Húṣáì ṣe? Ṣé ńṣe ló pa Dáfídì tì tó wá ń ti Ábúsálómù lẹ́yìn? Rárá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì ti darúgbó tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì ń fẹ́ pa á, Húṣáì jẹ́ adúróṣinṣin sí i torí pé òun ni Jèhófà yàn láti jẹ́ ọba. Torí náà, Húṣáì lọ bá Dáfídì lórí Òkè Ólífì.—2 Sámúẹ́lì 15:30, 32.
sí Ọlọ́run. Húṣáì mọ̀ pé Ábúsálómù ti wá sí Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ àti pé Dáfídì ti sá lọ. (16 Dáfídì ní kí Húṣáì pa dà lọ sí Jerúsálẹ́mù kó sì díbọ́n bíi pé ọ̀rẹ́ Ábúsálómù lòun kó wá rí i dájú pé nǹkan tí òun bá sọ ni Ábúsálómù ṣe dípò ti Áhítófẹ́lì. Húṣáì lo ìgboyà, ó sì fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu kó lè ṣe ohun tí Dáfídì fẹ́ kó sì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Dáfídì bẹ Jèhófà pé kó ran Húṣáì lọ́wọ́, Jèhófà sì ṣe bẹ́ẹ̀. Húṣáì ni Ábúsálómù fetí sí dípò Áhítófẹ́lì.—2 Sámúẹ́lì 15:31; 17:14.
17. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ jẹ́ onígboyà tá a bá fẹ́ jẹ́ adúróṣinṣin?
17 A nílò ìgboyà ká lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà ká sì ṣègbọràn sí i dípò ká máa ṣe ohun tí àwọn ìdílé wa, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí ohun tí ìjọba ń fẹ́ ká ṣe. Bí àpẹẹrẹ, látìgbà tí Taro tó wà lórílẹ̀-èdè Japan ti wà lọ́mọdé ló ti ń múnú àwọn òbí rẹ̀ dùn. Ó máa ń gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu, ó sì máa ń ṣe ohun tí wọ́n bá fẹ́. Kì í ṣe torí pé ó jẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ló ṣe ń gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu bí kò ṣe torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn. Àmọ́, nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́, àwọn òbí rẹ̀ fẹ́ kó dá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dúró. Inú Taro ò dùn rárá, ó wá ṣòro fún un láti sọ fún wọn pé òun ò ní lè dá ìpàdé lílọ dúró. Taro sọ pé: “Inú bí àwọn òbí mi débi pé ọ̀pọ̀ ọdún ni wọn ò fi gbà kí n wá kí àwọn nílé. Mo bẹ Jèhófà pé kó fún mi nígboyà kí n lè dúró lórí ìpinnu tí mo ṣe. Ìwà wọn ti yí pa dà báyìí, mo sì lè lọ kí wọn nígbà tí mo bá fẹ́.”—Ka Òwe 29:25.
18. Kí lo ti kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí?
18 Bíi ti Dáfídì, Jónátánì, Nátánì àti Húṣáì, ǹjẹ́ kí àwa náà ní ìbàlẹ̀ ọkàn téèyàn máa ń ní téèyàn bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. A ò sì fẹ́ dà bí Ábínérì àti Ábúsálómù tí wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́. Òótọ́ ni pé aláìpé ni wá, a sì máa ń ṣàṣìṣe, àmọ́ ẹ jẹ́ ká máa gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó fi hàn pé jíjẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà lohun tó ṣe pàtàkì jù sí wa.
^ [1] (ìpínrọ̀ 7) A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
Tó o bá ní kí arákùnrin rẹ lọ bá àwọn alàgbà kí wọ́n lè ràn án lọ́wọ́, ìyẹn fi hàn pé onínúure ni ẹ́, o sì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà