Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́​—Báwo Lẹ Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ fún Ìrìbọmi?

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́​—Báwo Lẹ Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ fún Ìrìbọmi?

“Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí.”​—SÁÀMÙ 40:8.

ORIN: 51, 58

1, 2. (a) Ṣàlàyé ìdí tí ìrìbọmi fi gba àròjinlẹ̀. (b) Kí ló yẹ kó dá ẹnì kan lójú kó tó ṣèrìbọmi, kí sì nìdí?

ṢÉ Ọ̀DỌ́ ni ẹ́, tó o sì fẹ́ ṣèrìbọmi? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ohun tó dára jù lọ lo fẹ́ ṣe yẹn. Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ìrìbọmi gba àròjinlẹ̀. Ìrìbọmi ló máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, ìyẹn ni pé, o ti ṣèlérí fún Jèhófà pé òun ni wàá máa sìn títí láé àti pé bó o ṣe máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ lo kà sí pàtàkì jù lọ. Ìlérí tó o ṣe fún Ọlọ́run yẹn gba àròjinlẹ̀, torí náà kó o tó ṣèrìbọmi, rí i dájú pé ó tọkàn rẹ wá, o ti dàgbà dénú tó láti ṣèpinnu, o sì ti lóye ohun tó túmọ̀ sí láti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Ọlọ́run.

2 Àmọ́, ó lè máa ṣé ẹ bíi pé kó o máà tíì ṣèrìbọmi. Ó sì lè wù ẹ́ kó o ṣèrìbọmi ṣùgbọ́n káwọn òbí ẹ rò pé ó yẹ kó o gbọ́njú díẹ̀ sí i. Kí ló yẹ kó o ṣe? Má ṣe rẹ̀wẹ̀sì. Àmọ́ ní báyìí ná, mú kí àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà lágbára sí i, kó o ṣèrìbọmi láìpẹ́. Torí náà, o lè pinnu láti sunwọ̀n sí i tó bá kan: (1) ohun tó o gbà gbọ́, (2) ìwà rẹ àti (3) ìmọrírì tó o ní.

OHUN TÓ O GBÀ GBỌ́

3, 4. Ẹ̀kọ́ wo làwọn ọ̀dọ́ lè rí kọ́ lára Tímótì?

3 Wo àwọn ìbéèrè yìí, kó o sì ronú lórí bó o ṣe máa dáhùn wọn: Kí nìdí tí mo fi gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà? Kí nìdí tó fi dá mi lójú pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì? Kí nìdí tí mo fi ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, dípò kí n máa ṣe ohun táyé ń ṣe? Àwọn ìbéèrè yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fi ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yìí sílò pé: ‘Ẹ ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.’ (Róòmù 12:2) Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀?

Tímótì gba ẹ̀kọ́ òtítọ́ gbọ́ torí pé ó máa ń ronú lórí ohun tó kọ́, ohun tó kọ́ sì yí i lérò pa dà

4 Àpẹẹrẹ Tímótì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ó mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa torí pé màmá rẹ̀ àti màmá rẹ̀ àgbà ti fi Ìwé Mímọ́ kọ́ ọ. Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: “Máa bá a lọ nínú àwọn ohun tí o ti kọ́, tí a sì ti yí ọ lérò padà láti gbà gbọ́.” (2 Tímótì 3:14, 15) ‘Yí lérò pa dà’ tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí túmọ̀ sí pé “kí ohun kan dáni lójú kéèyàn sì gbà gbọ́ pé òótọ́ ni.” Torí náà, ó gbọ́dọ̀ dá Tímótì lójú pé inú Ìwé Mímọ́ lèèyàn ti lè rí òtítọ́. Ó sì gba ohun tó rí nínú Ìwé Mímọ́ gbọ́, kì í ṣe torí pé màmá rẹ̀ àti màmá rẹ̀ àgbà sọ pé kó ṣe bẹ́ẹ̀, bí kò ṣe torí pé òun fúnra rẹ̀ ronú lórí ohun tó kọ́, ohun tó kọ́ sì yí i lérò pa dà.—Ka Róòmù 12:1.

5, 6. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o máa ti kékeré lo “agbára ìmọnúúrò” rẹ?

5 Ìwọ náà ńkọ́? Ó lè ti pẹ́ tó o ti mọ ẹ̀kọ́ òtítọ́. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, rí i dájú pé ò ń ronú lórí àwọn ohun tó o gbà gbọ́ àti ìdí tó o fi gbà wọ́n gbọ́. Ìyẹn á mú kí ìgbàgbọ́ rẹ lágbára sí i, ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe, èrò àwọn èèyàn tàbí èrò ìwọ fúnra rẹ ò sì ní mú kó o ṣe ìpinnu tí kò tọ́.

6 Tó o bá ń ti kékeré lo “agbára ìmọnúúrò” rẹ, wàá lè dáhùn táwọn ojúgbà rẹ bá bi ẹ́ láwọn ìbéèrè bíi: ‘Kí ló mú kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run wà ní ti gidi? Bí Ọlọ́run bá nífẹ̀ẹ́ wa, kí nìdí tó fi fàyè gbà á kí àwọn ohun búburú máa ṣẹlẹ̀? Kí ló mú kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run ti wà látayébáyé?’ Tó o bá ti múra sílẹ̀ dáadáa, irú àwọn ìbéèrè yìí ò ní mú kó o máa ṣiyè méjì, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló máa mú kó o túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

7-9. Sọ bí ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?” tó wà lórí ìkànnì wa, ṣe lè mú kí ohun tó o gbà gbọ́ túbọ̀ dá ẹ lójú.

7 Tó o bá ń fara balẹ̀ dá kẹ́kọ̀ọ́, wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọ́n bá bi ẹ́, o ò ní máa ṣiyè méjì, àwọn ohun tó o gbà gbọ́ á sì túbọ̀ dá ẹ lójú. (Ìṣe 17:11) Ọ̀pọ̀ ìtẹ̀jáde ló wà tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ ti jàǹfààní látinú kíka ìwé pẹlẹbẹ náà The Origin of Life—Five Questions Worth Asking àti ìwé náà, Is There a Creator Who Cares About You? Bákan náà, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ti gbádùn ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?” èyí tó wà lórí ìkànnì jw.org/yo, wọ́n sì ti jàǹfààní látinú ẹ̀. Wàá rí i lábẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àpilẹ̀kọ tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí yìí la ṣe kí àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó o gbà gbọ́ túbọ̀ dá ẹ lójú.

8 Torí pé ìwọ náà ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ṣeé ṣe kó o ti mọ ìdáhùn sáwọn kan lára àwọn ìbéèrè tó wà nínú ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ náà. Àmọ́, ṣé àwọn ìdáhùn yẹn lójú? Ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ yìí máa mú kó o fara balẹ̀ ronú lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀, o sì lè kọ ìdí tó o fi gba àwọn ohun tó o gbà gbọ́ sílẹ̀. Ìyẹn máa jẹ́ kó o mọ bó o ṣe máa ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíì. Tó o bá ní ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?,” o lè lò ó tó o bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn á sì mú kí àwọn ohun tó o gbà gbọ́ túbọ̀ dá ẹ lójú.

9 Ó gbọ́dọ̀ dá ìwọ fúnra rẹ lójú pé òtítọ́ lohun tó o gbà gbọ́. Ìyẹn ló máa mú kó o túbọ̀ múra sílẹ̀ fún ìrìbọmi. Arábìnrin kan tí ò tíì pé ọmọ ogún ọdún sọ pé: “Kí n tó ṣèrìbọmi, mo kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì rí i pé ìsìn tòótọ́ nìyí. Ojoojúmọ́ sì lohun tí mo gbà gbọ́ túbọ̀ ń dá mi lójú.”

ÌWÀ RẸ

10. Kí nìdí tá a fi lè retí pé kí Kristẹni kan tó ti ṣèrìbọmi máa ṣe ohun tó bá ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ mu?

10 Bíbélì sọ pé: “Ìgbàgbọ́, bí kò bá ní àwọn iṣẹ́, jẹ́ òkú nínú ara rẹ̀.” (Jákọ́bù 2:17) Tí àwọn ohun tó o gbà gbọ́ bá dá ọ lójú lóòótọ́, ó máa hàn nínú ìwà rẹ. Wàá ní ohun tí Bíbélì pè ní “ìṣe ìwà mímọ́,” wàá sì máa ṣe “àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run.”​—Ka 2 Pétérù 3:11.

11. Kí ni “ìṣe ìwà mímọ́”?

11 Kí ni “ìṣe ìwà mímọ́”? Kéèyàn ní ìṣe ìwà mímọ́ túmọ̀ sí pé kéèyàn jẹ́ oníwà mímọ́. Bí àpẹẹrẹ, ronú lórí ìwà tó o hù lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Nígbà tó ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o ṣe ohun tí kò tọ́, ǹjẹ́ o fara balẹ̀ ronú kó o lè fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́? (Hébérù 5:14) Ǹjẹ́ o rántí àwọn ìgbà kan tó ò jẹ́ káwọn èèyàn mú ẹ ṣe ohun tí kò tọ́, tó ò sì jẹ́ káwọn ojúgbà rẹ sọ ẹ́ dà bí wọ́n ṣe dà? Ṣé ìwà tó dáa lo máa ń hù níléèwé rẹ? Ṣé o máa ń pa òfin Jèhófà mọ́ ní gbogbo ìgbà, àbí o máa ń hu irú ìwà táwọn ọmọ iléèwé rẹ ń hù kí wọ́n má bàa fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́? (1 Pétérù 4:3, 4) Adára-má-kù-síbì-kan ò sí. Nígbà míì pàápàá, àwọn kan tó ti ń sin Jèhófà láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn lè máa tijú tàbí kó ṣòro fún wọn láti wàásù fáwọn ẹlòmíì. Àmọ́, ẹni tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run máa ń yangàn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun, ó sì máa ń hàn nínú ìwà rẹ̀.

12. Kí ni díẹ̀ lára “àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run,” ojú wo ló sì yẹ kó o máa fi wò wọ́n?

12 Kí ni “àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run”? Àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run ni àwọn ohun tó ò ń ṣe nínú ìjọ, bíi lílọ sí ìpàdé àti òde ẹ̀rí. Àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́ o, àdúrà tó o máa ń gbà sí Jèhófà àti ìdákẹ́kọ̀ọ́ rẹ náà wà lára ẹ̀. Ẹnì kan tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà ò ní máa rò pé gbogbo nǹkan yìí ti nira jù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe lá máa ṣe bíi ti Dáfídì Ọba tó sọ pé: “Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí, òfin rẹ sì ń bẹ ní ìhà inú mi.”—Sáàmù 40:8.

Báwo làdúrà ẹ ṣe máa ń sọ ojú abẹ níkòó tó, kí sì ni àdúrà ẹ ń fi hàn nípa bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà sí

13, 14. Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa ṣe “àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run,” báwo làwọn ọ̀dọ́ kan sì ṣe jàǹfààní látinú ẹ̀?

13 Àwọn ìbéèrè àtàwọn àbá tó wà lójú ìwé 308 àti 309 nínú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ Apá Kejì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa ṣe àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run. Lójú ìwé yìí, o lè kọ ìdáhùn tó o ní sáwọn ìbéèrè bíi: “Báwo làdúrà ẹ ṣe máa ń sọ ojú abẹ níkòó tó, kí sì ni àdúrà ẹ ń fi hàn nípa bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà sí?” “Àwọn nǹkan wo lo máa ń ṣe tó o bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́?” “Ṣó o máa ń lọ sóde ẹ̀rí báwọn òbí ẹ ò bá tiẹ̀ lọ?” Ojú ìwé náà tún ní àlàfo tó o lè kọ àwọn nǹkan tó o fẹ́ ṣe nípa àdúrà rẹ, ìdákẹ́kọ̀ọ́ rẹ àti iṣẹ́ ìwàásù sí.

14 Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó fẹ́ ṣèrìbọmi ni àwọn àbá yìí ti ràn lọ́wọ́. Arábìnrin ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Tilda sọ pé: “Àwọn ìbéèrè àtàwọn àbá náà ràn mí lọ́wọ́ láti pinnu ohun tí mo fẹ́ ṣe. Ọ̀kọ̀ọ̀kan lọwọ́ mi tẹ àwọn àfojúsùn mi, mo sì ṣèrìbọmi ní ọdún kan lẹ́yìn náà.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Patrick náà nìyẹn. Ó sọ pé: “Mo mọ àwọn ohun tí mo fẹ́ ṣe, àmọ́ bí mo ṣe kọ wọ́n sílẹ̀ jẹ́ kí n túbọ̀ sapá kọ́wọ́ mi lè tẹ àwọn àfojúsùn mi.”

Ṣé wàá ṣì máa sin Jèhófà bí dádì àti mọ́mì ẹ bá láwọn ò sìn ín mọ́? (Wo ìpínrọ̀ 15)

15. Kí nìdí tí ìyàsímímọ́ fi jẹ́ ìpinnu téèyàn máa ń dá ṣe?

15 Ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè tó wà lójú ìwé náà ni: “Ṣé wàá ṣì máa sin Jèhófà bí dádì àti mọ́mì ẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ bá láwọn ò sìn ín mọ́?” Tó o bá ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà tó o sì ṣèrìbọmi, wàá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Torí náà, kò yẹ kó jẹ́ àwọn òbí rẹ àbí ẹlòmíì láá máa pinnu ohun tó o máa ṣe fún Jèhófà. Ìṣe ìwà mímọ́ rẹ àtàwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run tó ò ń ṣe ló máa fi hàn pé òtítọ́ tó o gbà gbọ́ dá ọ lójú, á sì fi hàn pé òótọ́ lo fẹ́ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run. Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kò ní pẹ́ tí wàá fi ṣèrìbọmi.

ÌMỌRÍRÌ TÓ O NÍ

16, 17. (a) Kí lohun tó yẹ kó mú kéèyàn fẹ́ di Kristẹni? (b) Àpèjúwe wo lo lè fi ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ kó o mọ rírì ìràpadà?

16 Lọ́jọ́ kan, ọkùnrin kan tó mọ Òfin Mósè dáadáa bi Jésù pé: “Èwo ni àṣẹ títóbi jù lọ nínú Òfin?” Jésù wá dá a lóhùn pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” (Mátíù 22:35-37) Jésù ṣàlàyé pé ìfẹ́ tí ẹnì kan ní fún Jèhófà ló yẹ kó mú kó wù ú láti ṣèrìbọmi kó sì di Kristẹni. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó o lè gbà mú kí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà lágbára sí i ni pé kó o máa fara balẹ̀ ronú lórí ẹ̀bùn tó ga jù lọ ti Ọlọ́run fún aráyé, ìyẹn ìràpadà. (Ka 2 Kọ́ríńtì 5:14, 15; 1 Jòhánù 4:9, 19.) Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á wù ẹ́ láti mọ rírì ẹ̀bùn àgbàyanu tí Ọlọ́run fún wa yìí.

17 Jẹ́ ká wo àpèjúwe kan tó máa jẹ́ kó o rí ìdí pàtàkì tó fi yẹ kó o mọ rírì ìràpadà: Fojú inú wò ó pé omi ń gbé ẹnì kan lọ, àmọ́ ṣàdédé lẹnì kan wá yọ ọ́ jáde. Ṣé á kàn lọ wá aṣọ míì wọ ní tìẹ, táá sì gbà gbé ohun tẹ́ni náà ṣe fún un ni? Ó dájú pé kò ní ṣe bẹ́ẹ̀! Gbogbo ìgbà tó bá ti rí ẹni tí kò jẹ́ kó bómi lọ yẹn láá máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pé ó gbẹ̀mí òun là. Bákan náà, ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà àti Jésù torí ẹ̀bùn ìràpadà náà. Àwọn méjèèjì ni wọ́n jẹ́ ká wà láàyè! Wọ́n gbà wá kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Torí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí wa, a ti wá nírètí láti gbé títí láé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé!

18, 19. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ kó o máa bẹ̀rù láti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà? (b) Báwo ni ìjọsìn Jèhófà ṣe ń mú kí ìgbésí ayé rẹ dára sí i?

18 Ṣé o mọ rírì ohun tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ? Tó o bá mọ rírì ẹ̀, ó yẹ kó o ṣe ìyàsímímọ́, kó o sì ṣèrìbọmi. Tó o bá ya ara rẹ sí mímọ́, ṣe lò ń ṣèlérí fún Ọlọ́run pé ohun tó fẹ́ ni wàá máa ṣe jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ. Ṣó wá yẹ kó o máa bẹ̀rù láti ṣe ìyàsímímọ́? Rárá! Ohun tó dáa jù ni Jèhófà fẹ́ fún ẹ, ó sì máa san èrè fún gbogbo àwọn tó bá ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Hébérù 11:6) Tó o bá ya ara rẹ sí mímọ́ fún Ọlọ́run tó o sì ṣèrìbọmi, ìgbésí ayé rẹ á máa dáa sí i ni, kò ní bà jẹ́! Arákùnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún [24] àmọ́ tó ṣèrìbọmi kó tó pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá sọ pé, “Ká ní mo dàgbà ju bẹ́ẹ̀ yẹn lọ kí n tó ṣèrìbọmi, ó ṣeé ṣe kí n túbọ̀ lóye ọ̀pọ̀ nǹkan, àmọ́ ìpinnu tí mo ṣe láti ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà ti gbà mí lọ́wọ́ ṣíṣe ohun táyé ń fẹ́.”

Bí Sátánì ṣe máa pa ẹ́ jẹ ló ń wá, kò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ rárá

19 Ohun tó dáa jù lọ ni Jèhófà fẹ́ fún ẹ. Àmọ́, bí Sátánì ṣe máa pa ẹ́ jẹ ló ń wá, kò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ rárá. Kò sóhun rere kan tó máa fún ẹ tó o bá tẹ̀ lé e. Báwo ló tiẹ̀ ṣe máa fún ẹ lóhun tí kò ní? Kò ní ìhìn rere, kò sì nírètí kankan. Ọ̀nà ìparun nìkan ló lè sin èèyàn lọ, torí ohun tó máa gbẹ̀yìn òun fúnra ẹ̀ náà nìyẹn!—Ìṣípayá 20:10.

20. Kí ló máa ran ọ̀dọ́ kan tó fẹ́ ṣe ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi lọ́wọ́ kí àjọṣe tó ní pẹ̀lú Jèhófà lè lágbára sí i? (Tún wo àpótí náà “Ohun Tó Máa Mú Kí Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Jèhófà Túbọ̀ Lágbára.”)

20 Ìpinnu tó dáa jù lọ tó o lè ṣe nígbèésí ayé rẹ ni pé kó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ṣé o ti múra tán láti ṣe bẹ́ẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má bẹ̀rù. Àmọ́, tó o bá rò pé o ò tíì ṣe tán, lo àwọn àbá tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí kó o lè mú kí àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára. Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará tó wà ní Fílípì pé kí wọ́n ṣáà máa tẹ̀ síwájú. (Fílípì 3:16) Tó o bá fi ìmọ̀ràn yẹn sílò, kò ní pẹ́ táá fi máa wù ẹ́ pé kó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà kó o sì ṣèrìbọmi.