Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Ń Tọ́ Wa Sọ́nà Ká Lè Jogún Ìyè

Jèhófà Ń Tọ́ Wa Sọ́nà Ká Lè Jogún Ìyè

“Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.”—AÍSÁYÀ 30:21.

ORIN: 65, 48

1, 2. (a) Ìkìlọ̀ wo ló ti gba ọ̀pọ̀ ẹ̀mí là? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Ìtọ́sọ́nà tó ń gbẹ̀mí là wo ni Ọlọ́run ń fún àwọn èèyàn rẹ̀?

“DÚRÓ, WỌ̀TÚN WÒSÌ, FETÍ SÍLẸ̀.” Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún táwọn àkọlé gàdàgbà bí èyí ti máa ń wà láwọn ojú irin tó wà ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà ti Àríwá. Kí nìdí táwọn àkọlé yìí fi máa ń wà níbẹ̀? Torí kí ọkọ̀ ojú irin tó ń sáré bọ̀ má bàa gbá àwọn mọ́tò tó ń sọdá ojú irin ni wọ́n ṣe gbé àwọn àkọlé náà síbẹ̀. Àkọlé yìí sì ti gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn là.

2 Ohun tí Jèhófà ń ṣe fún wa jùyẹn lọ fíìfíì. Ó ń tọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ sọ́nà kí wọ́n lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun, ó sì máa ń tọ́ wọn sọ́nà kí wọ́n má bàa kó sí yọ́ọ́yọ́ọ́. Ṣe ni Jèhófà dà bí olùṣọ́ àgùntàn kan tó nífẹ̀ẹ́ àwọn àgùntàn rẹ̀, tó ń tọ́ wọn sọ́nà, tó sì ń dáàbò bò wọ́n kí wọ́n má bàa kó sí kòtò.—Ka Aísáyà 30:20, 21.

ỌJỌ́ PẸ́ TÍ JÈHÓFÀ TI Ń TỌ́ ÀWỌN ÈÈYÀN RẸ̀ SỌ́NÀ

3. Kí ló ti aráyé sọ́nà ìparun?

3 Látijọ́ táláyé ti dáyé ni Jèhófà ti ń tọ́ àwọn èèyàn sọ́nà tó sì máa ń fún wọn láwọn ìtọ́ni pàtó. Bí àpẹẹrẹ, nínú ọgbà Édẹ́nì, Jèhófà fún àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ní ìtọ́ni kedere táá mú kí wọ́n wà láàyè títí láé kí wọ́n sì máa láyọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:15-17) Àmọ́ Ádámù àti Éfà kò tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Baba wọn onífẹ̀ẹ́ fún wọn. Éfà gba ìmọ̀ràn tí ejò fún un, Ádámù náà sì wá fetí sí ohùn aya rẹ̀. Kí nìyẹn wá yọrí sí? Àwọn méjèèjì jẹ palaba ìyà, wọ́n sì kú láìnírètí láti tún pa dà wà láàyè mọ́. Àìgbọràn wọn ló sì ti gbogbo aráyé sọ́nà ìparun.

4. (a) Kí nìdí tó fi pọn dandan pé kí Ọlọ́run fún àwọn èèyàn ní ìtọ́ni tuntun lẹ́yìn Ìkún-omi? (b) Báwo ni ìtọ́ni tuntun tí Ọlọ́run fáwọn èèyàn lẹ́yìn Ìkún-omi ṣe jẹ́ ká mọ ojú tó fi ń wo ẹ̀mí?

4 Ọlọ́run fún Nóà ní àwọn ìtọ́ni tó gbẹ̀mí òun àti ìdílé rẹ̀ là. Lẹ́yìn Ìkún-omi, Jèhófà pàṣẹ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n má ṣe jẹ ẹ̀jẹ̀, kí wọ́n má sì ṣe mu ún. Kí nìdí tí Jèhófà fi pàṣẹ yìí fún wọn? Ìdí ni pé Jèhófà fẹ́ kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ ẹran, torí náà, ó fún wọn ní ìtọ́ni tuntun náà pé: “Kìkì ẹran pẹ̀lú ọkàn rẹ̀—ẹ̀jẹ̀ rẹ̀—ni ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ.” (Jẹ́nẹ́sísì 9:1-4) Àṣẹ yìí jẹ́ ká mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ẹ̀mí. Òun ni Ẹlẹ́dàá wa, òun ló sì jẹ́ ká wà láàyè, torí náà òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti fún wa ní ìtọ́ni nípa ọwọ́ tó yẹ ká fi mú ẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, ó pàṣẹ pé a kò gbọ́dọ̀ pààyàn. Ohun ọ̀wọ̀ ni Ọlọ́run ka ẹ̀mí àti ẹ̀jẹ̀ sí, ó sì máa fìyà jẹ ẹnikẹ́ni tó bá ṣì í lò.—Jẹ́nẹ́sísì 9:5, 6.

5. Kí la máa gbé yẹ̀ wò, kí sì nìdí?

5 Lẹ́yìn Ìkún-omi, Ọlọ́run ń bá a nìṣó láti máa tọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ sọ́nà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò nípa bí Ọlọ́run ṣe tọ́ wọn sọ́nà. Èyí á sì mú ká túbọ̀ máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni Jèhófà títí tá a fi máa dénú ayé tuntun.

ORÍLẸ̀-ÈDÈ TUNTUN, ÀWỌN ÌTỌ́NI TUNTUN

6. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa Òfin Mósè mọ́, ọwọ́ wo ló sì yẹ kí wọ́n fi mú un?

6 Nígbà ayé Mósè, Jèhófà fáwọn èèyàn rẹ̀ ní ìtọ́ni tó ṣe kedere nípa irú ìwà tó yẹ kí wọ́n máa hù àti bí wọ́n á ṣe máa jọ́sìn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ipò táwọn èèyàn rẹ̀ wà nígbà yẹn ti yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀. Ó lé ní igba [200] ọdún táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi jẹ́ ẹrú nílẹ̀ Íjíbítì, àwọn tó yí wọn ká ń jọ́sìn àwọn baba ńlá wọn tó ti kú, wọ́n ń bọ̀rìṣà, wọ́n sì ń ṣe onírúurú nǹkan tí inú Ọlọ́run ò dùn sí. Nígbà tí Ọlọ́run sì wá dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì, wọ́n nílò àwọn ìtọ́ni tuntun. Èyí tó máa sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo tó ń tẹ̀ lé Òfin Jèhófà. Àwọn ìwé kan táwọn èèyàn máa ń ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tí wọ́n máa ń lò fún “òfin” tún lè túmọ̀ sí “darí, tọ́ sọ́nà tàbí gbà nímọ̀ràn.” Òfin dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lọ́wọ́ ìsìn èké àti ìṣekúṣe táwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká ń ṣe. Nígbàkigbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ó máa ń bù kún wọn. Àmọ́ bí wọ́n bá kọ̀ láti ṣe ohun tó fẹ́, wọ́n máa ń jìyà rẹ̀.—Ka Diutarónómì 28:1, 2, 15.

7. (a) Ṣàlàyé ìdí tí Jèhófà fi fáwọn èèyàn rẹ̀ ní ìtọ́sọ́nà. (b) Ọ̀nà wo ni Òfin gbà jẹ́ amọ̀nà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

7 Ìdí míì tún wà tó fi pọn dandan pé kí Jèhófà fáwọn èèyàn rẹ̀ láwọn ìtọ́ni tuntun. Òfin múra àwọn ọmọ Ísírẹ́lì de ohun pàtàkì kan, ìyẹn dídé Jésù Kristi tí í ṣe Mèsáyà. Òfin yìí jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀ pé aláìpé làwọn. Ó tún jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé wọ́n nílò ìràpadà, ìyẹn ẹbọ pípé táá mú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò pátápátá. (Gálátíà 3:19; Hébérù 10:1-10) Yàtọ̀ síyẹn, Òfin dáàbò bo ìlà ìdílé tí Mèsáyà ti wá, ó sì tún jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá a mọ̀ nígbà tó dé. Ní ti gidi, ṣe ni Òfin dà bí amọ̀nà tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi.—Gálátíà 3:23, 24.

8. Kí nìdí tó fi yẹ ká ka àwọn ìlànà tó wà nínú Òfin Mósè sí pàtàkì?

8 Àwọn ìtọ́ni tó wà nínú Òfin tí Jèhófà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè ṣe àwa Kristẹni náà láǹfààní. Lọ́nà wo? Àwa náà lè fara balẹ̀ ronú lórí àwọn ìlànà tí Òfin náà dá lé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Òfin Mósè kọ́ ló ń darí àwa Kristẹni, àwọn ìlànà inú rẹ̀ ṣì wúlò fún wa, nígbèésí ayé wa àti lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Jèhófà jẹ́ kí wọ́n kọ àwọn òfin yẹn sínú Bíbélì ká lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀, kí àwọn ìlànà inú rẹ̀ lè máa tọ́ wa sọ́nà, ká sì lè túbọ̀ mọyì bí Jésù ṣe kọ́ wa ní ohun tó ju Òfin lọ. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ pé: “Ẹ gbọ́ pé a sọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà.’ Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” Torí náà, kì í ṣe pé ó yẹ ká máa sá fún ìṣekúṣe nìkan ni, a ò tún gbọ́dọ̀ gba èròkerò tàbí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ láyè nínú ọkàn wa.—Mátíù 5:27, 28.

9. Ohun mìíràn wo ló mú kí Ọlọ́run fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní àwọn ìtọ́ni tuntun?

9 Lẹ́yìn tí Mèsáyà dé, Jèhófà fún àwọn èèyàn rẹ̀ láwọn ìtọ́ni tuntun, ó sì tún jẹ́ kí wọ́n mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe. Kí nìdí? Ìdí ni pé lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, Jèhófà kọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sílẹ̀, ó sì yan Ísírẹ́lì tẹ̀mí láti jẹ́ èèyàn rẹ̀. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ipò táwọn èèyàn Ọlọ́run wà tún ti yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀.

JÈHÓFÀ Ń TỌ́ ÍSÍRẸ́LÌ TẸ̀MÍ SỌ́NÀ

10. Kí nìdí tí Jèhófà fi fún ìjọ Kristẹni ní òfin tuntun, kí ni òfin tuntun yìí sì fi yàtọ̀ sí èyí tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

10 Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin Mósè kí wọ́n lè mọ bí wọ́n á ṣe máa gbé ìgbé ayé wọn àti bí wọ́n á ṣe máa jọ́sìn Rẹ̀. Àmọ́, láti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, kì í tún ṣe orílẹ̀-èdè kan làwọn èèyàn Ọlọ́run ti wá mọ́, wọ́n wá láti onírúurú ẹ̀yà àti orílẹ̀-èdè, Ísírẹ́lì tẹ̀mí la sì ń pè wọ́n. Wọ́n di ìjọ Kristẹni, Jèhófà sì bá wọn dá májẹ̀mú tuntun. Jèhófà fún wọn láwọn ìtọ́ni tuntun nípa bí wọ́n á ṣe máa jọ́sìn rẹ̀ àti bí wọ́n á ṣe máa gbé ìgbé ayé wọn. Ó wá ṣe kedere pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) “Òfin Kristi” ni wọ́n ń tẹ̀ lé, ìyẹn òfin tó dá lórí àwọn ìlànà tá a kọ sínú ọkàn wọn kì í ṣe èyí tí wọ́n kọ sórí òkúta. Ibi yòówù káwọn Kristẹni máa gbé, òfin yìí á ṣe wọ́n láǹfààní, á sì máa tọ́ wọn sọ́nà.—Gálátíà 6:2.

11. Ohun méjì wo ni “òfin Kristi” dá lé?

11 Ísírẹ́lì tẹ̀mí ti jàǹfààní gan-an látinú àwọn ìtọ́ni tí Jèhófà tipasẹ̀ Jésù fún wọn. Kí Jésù tó dá májẹ̀mú tuntun sílẹ̀, ó pa àṣẹ pàtàkì méjì kan fún wọn. Ọ̀kan dá lórí iṣẹ́ ìwàásù. Ìkejì dá lórí bó ṣe yẹ káwa Kristẹni máa ṣe síra wa. Kò sí Kristẹni tí ìtọ́ni yìí ò kàn, torí náà, gbogbo wa ni wọ́n wà fún, yálà a nírètí láti bá Jésù jọba lọ́run tàbí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé.

12. Ìtọ́ni tuntun wo ni Jésù fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù?

12 Nígbà kan, káwọn èèyàn tó lè jọ́sìn Jèhófà àfi kí wọ́n wá sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì. (1 Àwọn Ọba 8:41-43) Àmọ́, nígbà tó yá, Jésù pa àṣẹ tó wà nínú Mátíù 28:19, 20 fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. (Kà á.) Ó ní kí wọ́n “lọ” sọ́dọ̀ gbogbo èèyàn. Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33, Jèhófà mú kó ṣe kedere pé òun fẹ́ kí wọ́n wàásù ìhìn rere jákèjádò ayé. Lọ́jọ́ yẹn, Jèhófà tú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ dà sórí nǹkan bí ọgọ́fà [120] lára àwọn tó di ìjọ tuntun náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi onírúurú èdè wàásù fáwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe. (Ìṣe 2:4-11) Lẹ́yìn ìyẹn, ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn gbòòrò dé ọ̀dọ̀ àwọn ará Samáríà. Nígbà tó sì di ọdún 36, ó gbòòrò dé ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́. Èyí wá fi hàn pé àwọn Kristẹni ní láti lọ wàásù fún gbogbo èèyàn kárí ayé!

13, 14. (a) Kí ni ìtumọ̀ “àṣẹ tuntun” tí Jésù pa fún wa? (b) Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jésù?

13 Jésù tún fún wa ní “àṣẹ tuntun kan” tó dá lórí bó ṣe yẹ ká máa ṣe sí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa. (Ka Jòhánù 13:34, 35.) A gbọ́dọ̀ máa fìfẹ́ hàn sí wọn nígbà gbogbo, ìyẹn nìkan kọ́ o, a tún gbọ́dọ̀ ṣe tán láti kú fún wọn. Ìyẹn ò sì sí nínú Òfin Mósè.—Mátíù 22:39; 1 Jòhánù 3:16.

14 Jésù ló fi àpẹẹrẹ tó dára jù lọ lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ irú ìfẹ́ tó lágbára bẹ́ẹ̀. Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ débi pé ó fínnúfíndọ̀ kú fún wọn. Ohun tó sì retí pé kí gbogbo àwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀ náà ṣe nìyẹn. Torí náà, ó yẹ ká ṣe tán láti jìṣẹ́ jìyà nítorí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, kódà, ká kú fún wọn.—1 Tẹsalóníkà 2:8.

ÀWỌN ÌTỌ́NI TÒDE ÒNÍ ÀTI TỌJỌ́ IWÁJÚ

15, 16. Ipò wo làwa èèyàn Ọlọ́run bára wa lónìí, báwo sì ni Jèhófà ṣe ń tọ́ wa sọ́nà?

15 Jésù ti yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti máa fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní “oúnjẹ” tẹ̀mí “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Mátíù 24:45-47) Àwọn ìtọ́ni pàtàkì táwa èèyàn Ọlọ́run ń rí gbà tí ìyípadà bá wáyé nínú ètò Ọlọ́run tún wà lára oúnjẹ tẹ̀mí náà. Kí ló mú káwa èèyàn Ọlọ́run nílò irú àwọn ìtọ́ni bẹ́ẹ̀?

16 “Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí, ìpọ́njú ńlá tí ò tíì sírú ẹ̀ rí sì máa tó bẹ̀rẹ̀. (2 Tímótì 3:1; Máàkù 13:19) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà ti lé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò lọ́run, ó ti lé wọn jù sáyé, wàhálà ńlá sì nìyẹn fà bá aráyé. (Ìṣípayá 12:9, 12) Ohun mìíràn sì tún ni pé à ń pa àṣẹ Jésù mọ́ pé ká wàásù fáwọn èèyàn jákèjádò ayé ní èdè tó pọ̀ sí i!

17, 18. Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn ìtọ́ni tá à ń rí gbà?

17 Ètò Ọlọ́run ń fún wa ní ọ̀pọ̀ ohun tá a nílò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ṣé ò ń lò wọ́n? Láwọn ìpàdé wa, a máa ń gba ìtọ́ni tó dá lórí bá a ṣe lè lò wọ́n lọ́nà tó dára jù lọ. Ṣó o máa ń wo àwọn ìtọ́ni yẹn bí èyí tó ń wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run?

18 Kí Ọlọ́run lè bù kún wa, a gbọ́dọ̀ máa fiyè sí gbogbo ìtọ́ni tí Ọlọ́run ń tipasẹ̀ ètò rẹ̀ fún wa. Tó bá ti mọ́ wa lára láti máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yẹn nísinsìnyí, á rọrùn fún wa láti máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tá ó máa rí gbà nígbà “ìpọ́njú ńlá” tí Jèhófà máa pa ayé búburú tí Sátánì ń darí yìí run. (Mátíù 24:21) Lẹ́yìn ìyẹn, a tún máa nílò àwọn ìtọ́ni tuntun tá ó máa tẹ̀ lé nínú ayé tuntun òdodo Ọlọ́run, níbi tí Sátánì ò ti ní ṣini lọ́nà mọ́.

Nínú ayé tuntun, Jèhófà máa fún wa ní àwọn àkájọ ìwé tó ní àwọn ìtọ́ni tuntun tá ó máa tẹ̀ lé (Wo ìpínrọ̀ 19, 20)

19, 20. Àwọn àkájọ ìwé wo la máa ṣí sílẹ̀, báwo la sì ṣe máa jàǹfààní nínú wọn?

19 Nígbà ayé Mósè, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nílò àwọn ìtọ́ni tuntun, Ọlọ́run sì fún wọn ní Òfin. Nígbà tó yá, “òfin Kristi” làwọn Kristẹni ń tẹ̀ lé. Bákan náà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé nínú ayé tuntun, Jèhófà máa fún wa ní àwọn àkájọ ìwé tó máa ní àwọn ìtọ́ni tuntun. (Ka Ìṣípayá 20:12.) Ó ní láti jẹ́ pé àwọn àkájọ ìwé yìí ló máa jẹ́ káráyé mọ àwọn ohun tí Jèhófà fẹ́ kí wọ́n máa ṣe. Àwọn àkájọ ìwé yìí máa jẹ́ kí gbogbo èèyàn, títí kan àwọn tó jíǹde, mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún wọn. Àwọn àkájọ ìwé náà máa jẹ́ ká túbọ̀ lóye àwọn ohun tí Jèhófà fẹ́. A máa túbọ̀ lóye Bíbélì, torí náà, nínú Párádísè, gbogbo wa á nífẹ̀ẹ́ ara wa, àá máa bọ̀wọ̀ fúnra wa, àá sì máa buyì kúnra wa. (Aísáyà 26:9) Ẹ sì wo bí àwọn ohun tá a máa mọ̀ nígbà ìṣàkóso Jésù Kristi Ọba náà á ṣe pọ̀ tó, tá ò sì tún fi kọ́ àwọn míì!

20 Tá a bá tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni “tí a kọ sínú àwọn àkájọ ìwé náà,” tá a sì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà nígbà àdánwò ìkẹyìn, Jèhófà máa kọ orúkọ wa sínú “àkájọ ìwé ìyè.” Àá wá wà láàyè títí láé! Torí náà, ó yẹ ká DÚRÓ, ìyẹn ni pé ká máa ka Bíbélì, ká WỌ̀TÚN WÒSÌ ká lè lóye ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe, ká sì FETÍ SÍLẸ̀ nípa títẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí Ọlọ́run ń fún wa báyìí. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, àá la ìpọ́njú ńlá já, títí láé la ó sì máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà, Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ tó jẹ́ ọlọgbọ́n.—Oníwàásù 3:11; Róòmù 11:33.