Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ JẸ́ OLÓÒÓTỌ́?

Ṣé Jíjẹ́ Olóòótọ́ Ṣì Bóde Mu?

Ṣé Jíjẹ́ Olóòótọ́ Ṣì Bóde Mu?

Ọ́fíìsì àkáǹtì ni Hitoshi ti ń ṣiṣẹ́ ní iléeṣẹ́ kan tó máa bá àwọn èèyàn wáṣẹ́ ní Japan. Lọ́jọ́ kan, òun àti ọ̀gá rẹ̀ jọ ń ṣàyẹ̀wò àkáǹtì, ni ọ̀gá rẹ̀ bá sọ fún un pé ó yẹ kó máa yí ìwé nídìí iṣẹ́ náà. Hitoshi ṣàlàyé fún ọ̀gá rẹ̀ pé ẹ̀rí ọkàn òun kò lè jẹ́ kí òun ṣe màdàrú. Ni ọ̀gá rẹ̀ bá halẹ̀ mọ́ ọn pé òun máa lé e lẹ́nu iṣẹ́, kò sì pẹ́ tí iṣẹ́ náà fi bọ́ lọ́wọ́ Hitoshi.

Láwọn oṣù tó tẹ̀ lé e, ẹ̀dùn ọkàn bá Hitoshi pé bóyá lòun máa rí iṣẹ́ míì. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó lọ ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún iṣẹ́ kan, Hitoshi sọ pé òun kò lè ṣe iṣé tó bá gba pé kí òun ṣe àìṣòótọ́. Ẹni tó ń fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò sọ pé, “Ìrònú tìẹ yìí kò bá tayé mu!” Àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ Hitoshi sọ fún un pé bó ṣe jẹ́ olóòótọ́ nídìí iṣẹ́ rẹ̀ ló dáa jù, síbẹ̀ ọkàn Hitoshi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kámi-kàmì-kámi. Bi àpẹẹrẹ, ó ní: “Mi ò rò pé bí mo ṣe ń ṣòótọ́ yìí máa gbè mí.”

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Hitoshi jẹ́ ká rí i pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló mọyì jíjẹ́ olóòótọ́. Kódà, àwọn kan gbà pé wàhálà lèèyàn ń wá tó bá jẹ́ olóòótọ́, pàápàá nídìí iṣẹ́ ajé. Obìnrin kan ní orílẹ̀-èdè South Africa sọ pé: “Àwọn aláìṣòótọ́ ló yí mi ká níbi iṣé, nígbà míì ó máa ń ṣe mí bíi pé kí èmi náà hùwà àìṣòótọ́.”

Irọ́ pípa jẹ́ ọkàn lára ìwà àìṣòótọ́ tó gbòde kan lóde òní. Láwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ń jẹ́ Robert S. Feldman láti yunifásítì Massachusetts Amherst ṣe ìwádìí kan. Ìwádìí náà fi hàn pé èèyàn mẹ́fà nínú mẹ́wàá ló jẹ́ pé tí wọ́n bá bá èèyàn sọ̀rọ̀ fún ìṣẹ́jú mẹ́wàá, ó kéré tán irọ́ kan á wà níbẹ̀. Feldman sọ pé: “Èyí yani lẹ́nu púpọ̀, a ò mọ̀ pé irọ́ pípa ti máa jingíri sáwọn èèyàn lára tó bẹ́ẹ̀.” Ó jọni lójú pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn kì í fẹ́ kí wọ́n parọ́ fáwọn, síbẹ̀ ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máa sì ìwà àìṣòótọ́ míì tó gbòde kan tó irọ́ pípa.

Kí nìdí tí irọ́ pípa, olè jíjà àtàwọn ìwà àìṣòótọ́ míì fi gbòde kan lóde òní? Báwo ni ìwà àìṣòótọ́ ṣe ń ṣàkóbá fún gbogbo èèyàn? Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé kí la lè ṣe tí a kò fi ní máa lọ́wọ́ sí ìwà àìṣòótọ́ yìí?