Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀RỌ̀ ỌGBỌ́N TÓ WÚLÒ LÓDE ÒNÍ

Má Ṣe Máa Ṣàníyàn

Má Ṣe Máa Ṣàníyàn

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ẹ dẹ́kun ṣíṣàníyàn nípa ọkàn yín.” —Mátíù 6:25.

Ohun tó túmọ̀ sí Jésù ló sọ̀rọ̀ yìí nínú Ìwàásù Orí Òkè. Ìwé kan tó ń túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ pé, ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “ṣíṣe àníyàn” lè túmọ̀ sí “bó ṣe máa ń ṣèèyàn tá a bá ní ìṣòrò owó, ebi àtàwọn ìṣòrò míì tá a máa ń bá pàdé lójoojúmọ́.” Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ló sábà máa ń fa àníyàn. Kò sóhun tó burú nínú kéèyàn máa ronú nípa ohun tó fẹ́ àtohun táwọn èèyàn rẹ̀ nílò. (Fílípì 2:20) Àmọ́ nígbà tí Jésù sọ pé, “ẹ má ṣàníyàn láé,” ńṣe ló ń gba àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nímọ̀ràn pé kí wọ́n má ṣe máa kó ọkàn sókè jù. Ìdí ni pé tí wọ́n bá ń kọ́kàn sókè torí ohun tí kò tíì ṣẹlẹ̀, wọn ò ní láyọ̀ rárá.—Mátíù 6:31, 34.

Ṣé ìmọ̀ràn yìí wúlò lóde òní? Ọlọgbọ́n ni wá tá a bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Jésù fún wa yìí. Kí nìdí? Àwọn ìwé ìwádìí kan sọ pé tí èèyàn bá ń ṣàníyàn jù, tó sì ń kó ọkàn sókè, ó lè mú káwọn iṣan kan nínú ara bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ gbòdì. Ìyẹn sì lè fa àwọn àìsàn bí ọgbẹ́ inú, àrùn ọkàn àti ikọ́ fée.

Jésù sọ ìdí tí kò fi yẹ ká máa ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ, ó ní: Kò sí èrè níbẹ̀. Jésù béèrè pé: “Ta ni nínú yín, nípa ṣíṣàníyàn, tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ìwọ̀n gígùn ìwàláàyè rẹ̀?” (Mátíù 6:27) Tá a bá ń kọ́kàn sókè, a ò lè fi ìṣẹ́jú kan kún ìgbésí ayé wa, kódà kò lè yanjú ìṣòro tó wà nílẹ̀. Àti pé, nǹkan kì í sábà burú tó bá a ṣe máa ń rò. Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé: “Ńṣe la kàn ń fàkókò ṣòfò tá a bá ń ṣàníyàn nípa ọ̀la, lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀la kì í sábà burú tó bá a ṣe lérò.”

Báwo la ṣe lè gbé àníyàn kúrò lọ́kàn? Lákọ̀ọ́kọ́, ó yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Tí Ọlọ́run bá ń pèsè oúnjẹ fáwọn ẹyẹ, tó sì ń faṣọ iyì bu ẹwà kún àwọn òdòdó, ṣé kò wá ní pèsè gbogbo ohun tá a nílò tá a bá fi ìjọsìn rẹ̀ ṣe àkọ́kọ́ láyé wa? (Mátíù 6:25, 26, 28-30) Ìkejì, má ṣe da àníyàn tòní pọ̀ mọ́ tọ̀la. Jésù sọ pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, nítorí ọ̀la yóò ní àwọn àníyàn tirẹ̀.” Ṣé ìwọ náà gbà pé “búburú ti ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tó fún un”?—Mátíù 6:34.

Tá a bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí Jésù fún wa, a ò ní fi ìrònú ṣe ara wa léṣe. Àti pé, a máa ní ìbàlẹ̀ ọkàn tí Bíbélì pè ní “àlàáfíà Ọlọ́run.”—Fílípì 4:6, 7.