Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 30

Bá A Ṣe Lè Wàásù fún Àwọn Tí Kò Ṣe Ẹ̀sìn Kankan

Bá A Ṣe Lè Wàásù fún Àwọn Tí Kò Ṣe Ẹ̀sìn Kankan

“Mo ti di ohun gbogbo nítorí gbogbo èèyàn, kí n lè gba àwọn kan là ní gbogbo ọ̀nà tí mo bá lè gbé e gbà.”​—1 KỌ́R. 9:22.

ORIN 82 Ẹ Jẹ́ “Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn”

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, èrò wo làwọn èèyàn ní báyìí nípa ẹ̀sìn?

NÍ ẸGBẸẸGBẸ̀RÚN ọdún sẹ́yìn, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe ẹ̀sìn kan tàbí òmíì. Àmọ́ láti bí ọdún mélòó kan báyìí, wọ́n ti ń yí èrò wọn pa dà nípa ẹ̀sìn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò ṣe ẹ̀sìn kankan mọ́. Kódà láwọn orílẹ̀-èdè kan, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn ibẹ̀ máa ń sọ pé àwọn ò ní ẹ̀sìn tàbí pé àwọn ò gba Ọlọ́run gbọ́. *​—Mát. 24:12.

2. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò fi ṣe ẹ̀sìn kankan mọ́?

2 Kí nìdí táwọn tí ò ṣe ẹ̀sìn kankan fi túbọ̀ ń pọ̀ sí i? * Ìgbádùn tàbí àníyàn ìgbésí ayé ló fà á fún àwọn kan. (Lúùkù 8:14) Àwọn kan tiẹ̀ wà tó sọ pé kò sí Ọlọ́run. Àwọn míì ní tiwọn gbà pé Ọlọ́run wà, àmọ́ wọ́n gbà pé kò sí àǹfààní kankan nínú ẹ̀sìn, pé kò bá ọgbọ́n tàbí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu, bẹ́ẹ̀ ni kò bóde mu mọ́. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n gbọ́ tí àwọn ọ̀rẹ́, àwọn olùkọ́ tàbí àwọn oníròyìn máa sọ pé kò sẹ́ni tó ṣẹ̀dá àwọn nǹkan tó wà láyé, pé ṣe ni wọ́n ṣàdédé wà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, wọ́n lè má rí àwọn táá jẹ́ kí wọ́n rídìí tó fi yẹ kí wọ́n gba Ọlọ́run gbọ́. Ohun tó mú kọ́rọ̀ ẹ̀sìn sú àwọn míì ni ìwàkiwà tó kún ọwọ́ àwọn olórí ẹ̀sìn àti bí wọ́n ṣe nífẹ̀ẹ́ owó, tí wọ́n sì ń ṣi agbára wọn lò. Láwọn ilẹ̀ kan, ìjọba ò fàyè gba káwọn ẹlẹ́sìn máa jọ́sìn Ọlọ́run fàlàlà.

3. Kí ni àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ̀?

3 Jésù pàṣẹ pé ká “máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mát. 28:19) Báwo la ṣe lè mú kí àwọn tí kò ṣe ẹ̀sìn kankan nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kí wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn Kristi? Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé ibi tẹ́nì kan gbé dàgbà máa ń nípa lórí bóyá á tẹ́tí sí ìwàásù wa tàbí kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìṣarasíhùwà àwọn ọmọ ilẹ̀ Yúróòpù sí ìwàásù wa lè yàtọ̀ sí tẹni tó wá láti ilẹ̀ Éṣíà. Kí nìdí? Nílẹ̀ Yúróòpù, ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ̀ nípa Bíbélì tí wọ́n sì ti kọ́ wọn pé Ọlọ́run ló ṣẹ̀dá àwọn nǹkan. Àmọ́ láwọn orílẹ̀-èdè kan ní Éṣíà, èyí tó pọ̀ jù níbẹ̀ ni kò mọ ohunkóhun nípa Bíbélì, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò gbà pé Ẹlẹ́dàá kan wà. Torí náà, àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè wàásù fún gbogbo èèyàn láìka ibi tí wọ́n ti wá sí.

Ó YẸ KÁ GBÀ PÉ WỌ́N LÈ YÍ PA DÀ

4. Kí nìdí tó fi yẹ ká gbà pé wọ́n lè yí pa dà?

4 Gbà Pé Wọ́n Lè Yí Pa Dà. Lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀sìn tẹ́lẹ̀ ló ń di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àtilẹ̀ lọ̀pọ̀ wọn ti kórìíra ìwàkiwà àti àgàbàgebè tó kúnnú ẹ̀sìn. Onírúurú ìwàkiwà làwọn míì ń hù tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ti ń wá bí wọ́n ṣe máa jáwọ́ nínú wọn. Torí náà pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ó dájú pé a máa rí “àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun.”​—Ìṣe 13:48; 1 Tím. 2:​3, 4.

Wá ọ̀nà míì láti bá àwọn tí kò gba Bíbélì gbọ́ sọ̀rọ̀ (Wo ìpínrọ̀ 5 àti 6) *

5. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ fi máa ń gbọ́rọ̀ wa?

5 Fi Hàn Pé O Nífẹ̀ẹ́ Wọn, Kó O sì Fọgbọ́n Bá Wọn Sọ̀rọ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, kì í ṣe ohun tá a bá àwọn èèyàn sọ ló máa ń mú kí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, bí kò ṣe ọ̀nà tá a gbà bá wọn sọ̀rọ̀. Wọ́n máa ń mọrírì bá a ṣe ń fìfẹ́ hàn sí wọn, tá à ń gba tiwọn rò, tá a sì ń sọ̀rọ̀ tó mọ́gbọ́n dání. Yàtọ̀ síyẹn, a kì í fipá mú wọn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe la máa ń sapá láti mọ èrò wọn nípa ẹ̀sìn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan kì í fẹ́ bá ẹni tí wọn ò mọ̀ rí sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn. Àwọn míì sì gbà pé kò bójú mu pé ká máa béèrè ohun táwọn rò nípa Ọlọ́run. Ohun ìtìjú làwọn míì kà á sí pé káwọn máa ka Bíbélì ní gbangba, pàápàá pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Èyí ó wù kó jẹ́, ẹ jẹ́ ká gbìyànjú láti mọ èrò wọn, ká sì gba tiwọn rò.​—2 Tím. 2:​24, àlàyé ìsàlẹ̀.

6. Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá onírúuru èèyàn mu, báwo la ṣe lè fara wé e?

6 Tá a bá ń bẹ́nì kan sọ̀rọ̀ tá a wá kíyè sí i pé ọ̀rọ̀ bíi “Bíbélì,” “ìṣẹ̀dá,” “Ọlọ́run” tàbí “ẹ̀sìn” kò bá a lára mu, kí la lè ṣe? A lè ṣe bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ká wá ọ̀nà míì láti bá ẹni náà sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, Ìwé Mímọ́ ni Pọ́ọ̀lù lò nígbà tó ń bá àwọn Júù sọ̀rọ̀. Àmọ́ nígbà tó ń bá àwọn Gíríìkì onímọ̀ ọgbọ́n orí sọ̀rọ̀ ní Áréópágù, kò tọ́ka sí Bíbélì ní tààràtà. (Ìṣe 17:​2, 3, 22-31) Báwo la ṣe lè fara wé Pọ́ọ̀lù? Tá a bá pàdé ẹnì kan tí kò gba Bíbélì gbọ́, á dáa ká má ṣe mẹ́nu kan Bíbélì ní tààràtà nínú ìjíròrò wa pẹ̀lú rẹ̀. Tó o bá kíyè sí i pé ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ kò fẹ́ káwọn míì rí i pé òun ń ka Bíbélì, á dáa kó o ka Bíbélì fún un látinú fóònù rẹ.

7. Bó ṣe wà nínú 1 Kọ́ríńtì 9:​20-23, tá a bá fẹ́ ṣe bíi ti Pọ́ọ̀lù, kí la gbọ́dọ̀ ṣe?

7 Tẹ́tí Sí Wọn Kó O sì Rí I Pé O Lóye Wọn. Ká rí i pé a lóye ìdí táwọn tá à ń wàásù fún fi ní irú èrò tí wọ́n ní. (Òwe 20:5) Lórí kókó yìí, ẹ jẹ́ ká tún wo àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù. Júù ni, àárín wọn náà ló sì dàgbà sí. Torí náà, ó máa gba pé kó mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá àwọn tí kì í ṣe Júù mu torí pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa Jèhófà àti Ìwé Mímọ́. Káwa náà lè lóye àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, ó lè gba pé ká ṣèwádìí tàbí ká sún mọ́ àwọn ará ìjọ tó ní ìrírí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.​—Ka 1 Kọ́ríńtì 9:​20-23.

8. Sọ ọ̀nà kan tá a lè gbà bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì.

8 Ohun tó jẹ wá lógún ni bá a ṣe máa rí àwọn “ẹni yíyẹ.” (Mát. 10:11) Ká lè dá àwọn ẹni yíyẹ mọ̀, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n sọ èrò wọn, ká sì tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa. Arákùnrin kan lórílẹ̀-èdè England máa ń ní káwọn èèyàn sọ èrò wọn nípa bá a ṣe lè ní ìdílé aláyọ̀, bá a ṣe lè tọ́ àwọn ọmọ yanjú àti bá a ṣe lè fara da ìwà ìrẹ́jẹ. Lẹ́yìn tó bá ti gbọ́ èrò wọn, á wá sọ pé, “Kí lèrò yín nípa ìmọ̀ràn tí wọ́n kọ sílẹ̀ lóhun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún ọdún méjì (2,000) sẹ́yìn?” Láì mẹ́nu ba Bíbélì, á wá fi àwọn ẹsẹ Bíbélì hàn wọ́n lórí fóònù rẹ̀.

BÓ O ṢE LÈ JẸ́ KÍ Ọ̀RỌ̀ RẸ WỌ ÀWỌN ÈÈYÀN LỌ́KÀN

9. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa dé ọkàn àwọn tí kì í fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run?

9 Tá a bá fẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa wọ àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́kàn, a lè bá wọn sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tí wọ́n ń rí láyìíká wọn. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń nífẹ̀ẹ́ sí ìṣẹ̀dá. Torí náà, a lè sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kẹ́ ẹ ti mọ̀ pé àwọn ìṣẹ̀dá tó wà láyé làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń wò fi ṣe ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí etí ṣe ń ṣiṣẹ́, ìyẹn ló sì jẹ́ kí wọ́n lè ṣe ẹ̀rọ makirofóònù. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò bí ojú ṣe ń ṣiṣẹ́ kí wọ́n tó lè ṣe kámẹ́rà. Kí ló máa ń wá sí yín lọ́kàn tẹ́ ẹ bá ń ronú nípa ìṣẹ̀dá? Ṣé ẹ rò pé èèyàn kan tàbí agbára kan ló wà lẹ́yìn rẹ̀, àbí nǹkan míì lẹ rò pé ó dá àwọn nǹkan náà?” Lẹ́yìn tá a bá ti tẹ́tí sí wọn dáadáa, a lè sọ pé: “Nígbà tó jẹ́ pé etí àti ojú làwọn ẹnjiníà wò fínífíní kí wọ́n tó lè ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe, iṣẹ́ ọwọ́ ta ni wọ́n wò ṣe ohun tí wọ́n ṣe? Ohun tí mo kà nínú ìwé àtijọ́ kan wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, ó ní: ‘Ẹni tó dá etí, ṣé kò lè gbọ́ràn ni? Ẹni tó dá ojú, ṣé kò lè ríran ni? . . . Òun ló ń fún àwọn èèyàn ní ìmọ̀!’ Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, wọ́n sì gbà pé ẹnì kan ló dá gbogbo ohun tó wà láyé.” (Sm. 94:​9, 10) Lẹ́yìn ìyẹn, a lè fi fídíò kan hàn wọ́n lórí ìkànnì jw.org® ní èdè Yorùbá lórí www.pr418.com/yo lábẹ́ “Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àti Ìrírí” nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Èrò Àwọn Èèyàn Nípa Ìṣẹ̀dá.” (Wo abẹ́ ÀWỌN ÌTẸ̀JÁDE > ÀWỌN FÍDÍÒ.) A sì lè fún wọn ní ìwé pẹlẹbẹ Was Life Created? tàbí The Origin of Life​—Five Questions Worth Asking.

10. Báwo la ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú ẹnì kan tí kò fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run?

10 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la wọn dáa. Àmọ́, ọ̀pọ̀ wọn ló tún ń bẹ̀rù pé ayé máa pa rẹ́ tàbí kó má ṣe é gbé mọ́. Alábòójútó arìnrìn àjò kan lórílẹ̀-èdè Nọ́wè sọ pé lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tí kì í fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run máa ń fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé. Lẹ́yìn tó bá ti kí àwọn èèyàn, ó máa ń sọ pé: “Báwo lẹ ṣe rò pé ọjọ́ ọ̀la wa máa rí? Ṣé ẹ rò pé àwọn olóṣèlú tàbí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ló máa yanjú gbogbo ìṣòro wa àbí ẹlòmíì ló máa ṣe é?” Tó bá ti tẹ́tí sí wọn dáadáa, á ka ẹsẹ Bíbélì kan tó sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ fún wọn tàbí kó tọ́ka sí i. Inú àwọn kan máa ń dùn gan-an tí wọ́n bá mọ̀ pé ayé yìí ò ní pa run àti pé àwọn èèyàn rere lá máa gbé inú rẹ̀ títí láé.​—Sm. 37:29; Oníw. 1:4.

11. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lo onírúurú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀, báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù bó ṣe wà nínú Róòmù 1:​14-16?

11 Oríṣiríṣi ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ ló yẹ ká máa lò bá a ṣe ń bá onírúurú èèyàn pàdé. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn èèyàn yàtọ̀ síra, wọn ò sì rí bákan náà. Tẹ́nì kan bá nífẹ̀ẹ́ sí kókó ọ̀rọ̀ kan, ẹlòmíì lè má fẹ́ gbọ́ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ rárá. Àwọn kan lè tẹ́tí sí wa tá a bá ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run tàbí Bíbélì, síbẹ̀ ara àwọn kan kì í yá láti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, àfi kéèyàn fọgbọ́n sọ ọ́. Èyí ó wù kó jẹ́, ẹ jẹ́ ká lo gbogbo àǹfààní tá a bá ní láti wàásù fún onírúurú èèyàn. (Ka Róòmù 1:​14-16.) Síbẹ̀, a ò ní gbàgbé pé Jèhófà ló ń mú kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ọkàn àwọn ẹni yíyẹ.​—1 Kọ́r. 3:​6, 7.

BÁ A ṢE LÈ WÀÁSÙ FÚN ÀWỌN TÓ WÁ LÁTI ILẸ̀ ÉṢÍÀ

Àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run máa ń fìfẹ́ hàn sáwọn tó wá láti ilẹ̀ tí wọn ò ti gba ẹ̀sìn Kristẹni, wọ́n sì máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ń ṣeni láǹfààní (Wo ìpínrọ̀ 12 àti 13)

12. Báwo la ṣe lè ran àwọn tó wá láti ilẹ̀ Éṣíà lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá kan wà?

12 Kárí ayé làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń pàdé àwọn tó wá láti ilẹ̀ Éṣíà, títí kan àwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè tí ìjọba ò ti fàyè gba káwọn ẹlẹ́sìn máa jọ́sìn fàlàlà. Láwọn orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Éṣíà, ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò tiẹ̀ ronú ẹ̀ rí pé Ẹlẹ́dàá kan wà. Táwọn kan bá gbọ́ pé Ẹnì kan ló dá gbogbo nǹkan, wọ́n máa ń fẹ́ mọ̀ sí i nípa ẹ̀, wọ́n á sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́, àwọn míì lè kọ́kọ́ máa lọ́ tìkọ̀ láti mọ̀ sí i. Torí náà, kí la lè ṣe kí ọ̀rọ̀ wa lè wọ̀ wọ́n lọ́kàn? Àwọn akéde kan tó ní ìrírí ti rí i pé ó máa ń rọrùn láti bá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ tí wọ́n bá kọ́kọ́ sọ nǹkan míì tó ṣeé ṣe kẹ́ni náà fẹ́ràn. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n á fìfẹ́ hàn sí i, wọ́n á sì sọ bí àwọn ìlànà Bíbélì kan ṣe ń ṣe àwọn láǹfààní.

13. Kí ló lè mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Bíbélì? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

13 Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì ló kọ́kọ́ máa ń fa ọ̀pọ̀ èèyàn mọ́ra. (Oníw. 7:12) Nílùú New York, arábìnrin kan tó máa ń wàásù fáwọn tó ń sọ èdè Mandarin sọ pé: “Mo máa ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, mo sì máa ń tẹ́tí sí wọn. Tí mo bá gbọ́ pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kó wá síbẹ̀, mo lè bi wọ́n pé: ‘Báwo ni nǹkan, ṣé ara ti ń mọlé? Ṣé o ti ríṣẹ́? Báwo làwọn ará ìlú yìí ṣe ń ṣe sí ẹ?’ ” Nígbà míì, àwọn ìbéèrè yìí máa ń ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún un láti wàásù. Tó bá rí i pé ó bọ́gbọ́n mu, arábìnrin náà tún máa ń béèrè pé: “Kí lo rò pé ó lè mú kí àárín àwọn èèyàn gún? Jẹ́ kí n fi òwe inú Bíbélì kan hàn ẹ́. Ó ní: ‘Ìbẹ̀rẹ̀ ìjà dà bí ìgbà téèyàn ṣí ibú omi sílẹ̀; kí ìjà tó bẹ́, fi ibẹ̀ sílẹ̀.’ Ṣé o rò pé ìmọ̀ràn yìí lè mú kí àárín àwa èèyàn gún régé?” (Òwe 17:14) Irú ìjíròrò yìí lè jẹ́ ká mọ àwọn táá fẹ́ ká pa dà wá kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́.

14. Báwo ni arákùnrin kan ṣe máa ń wàásù fún àwọn tó sọ pé àwọn ò gba Ọlọ́run gbọ́?

14 Báwo la ṣe lè wàásù fáwọn tó sọ fún wa pé àwọn ò gba Ọlọ́run gbọ́? Arákùnrin kan tó mọ béèyàn ṣe ń bá irú wọn sọ̀rọ̀ láwọn ilẹ̀ tó wà ní Ìlà Oòrùn ayé sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, tẹ́nì kan lórílẹ̀-èdè yìí bá sọ pé, ‘Mi ò gba Ọlọ́run gbọ́,’ ohun tó ní lọ́kàn ni pé òun ò gbà gbọ́ nínú kéèyàn máa jọ́sìn àwọn òòṣà táwọn èèyàn ń bọ. Mo sábà máa ń sọ pé àtọwọ́dá làwọn òòṣà yẹn àti pé wọn ò lágbára kankan. Màá wá ka Jeremáyà 16:​20, tó sọ pé: ‘Ǹjẹ́ èèyàn lè ṣe àwọn ọlọ́run fún ara rẹ̀ nígbà tí wọn kì í ṣe ọlọ́run ní ti gidi?’ Lẹ́yìn náà, màá béèrè pé: ‘Báwo la ṣe lè dá Ọlọ́run tòótọ́ mọ̀?’ Mo máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn, màá sì ka ohun tó wà nínú Àìsáyà 41:​23, tó sọ pé: ‘Ẹ sọ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú fún wa, ká lè mọ̀ pé ọlọ́run ni yín.’ Ẹ̀yìn náà ni màá wá tọ́ka sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà ti sọ tó sì ní ìmúṣẹ nínú Bíbélì.”

15. Kí la rí kọ́ látinú ìrírí arákùnrin kan ní Ìlà Oòrùn Éṣíà?

15 Arákùnrin kan ní Ìlà Oòrùn Éṣíà ṣàlàyé ohun tó máa ń ṣe tó bá lọ ṣèpadàbẹ̀wò. Ó sọ pé: “Mo máa ń tọ́ka sí àwọn ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó wà nínú Bíbélì, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ti nímùúṣẹ àtàwọn òfin ìṣẹ̀dá tó ń darí nǹkan láyé àti lọ́run. Lẹ́yìn náà ni màá wá jẹ́ kó mọ̀ pé gbogbo nǹkan yìí fi hàn pé Ẹlẹ́dàá kan wà, ó sì jẹ́ orísun ọgbọ́n. Tẹ́ni náà bá ti gbà pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run wà, màá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ohun tí Bíbélì sọ nípa Jèhófà hàn án.”

16. Bó ṣe wà nínú Hébérù 11:​6, kí nìdí tó fi yẹ káwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti Bíbélì, báwo la sì ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀?

16 Tá a bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn tí kò ṣe ẹ̀sìn kankan tàbí tí wọn ò gbà pé Ọlọ́run wà, a gbọ́dọ̀ máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn nínú Ọlọ́run túbọ̀ lágbára. (Ka Hébérù 11:6.) Ó sì yẹ ká tún ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fọkàn tán Bíbélì. Èyí lè gba pé ká sọ àwọn kókó kan ní àsọtúnsọ. Ní gbogbo ìgbà tá a bá ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, ó lè gba pé ká tún jíròrò àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì. A lè jíròrò ní ṣókí nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ti nímùúṣẹ, àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Bíbélì bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu àtàwọn ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó wà nínú Bíbélì.

17. Tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, kí ló máa mú kí wọ́n ṣe?

17 A lè mú káwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn Kristi tá a bá ń fìfẹ́ hàn sí wọn, yálà wọ́n jẹ́ onísìn tàbí wọn ò tiẹ̀ ṣe ẹ̀sìn kankan. (1 Kọ́r. 13:1) Bá a ṣe ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, àfojúsùn wa ni pé kí wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wọn, ó sì fẹ́ káwọn náà nífẹ̀ẹ́ òun. Ọdọọdún ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀sìn máa ń kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n ń ṣèrìbọmi, wọ́n sì ń dẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Torí náà, gbà pé wọ́n lè yí pa dà, fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ wọn láìka ibi tí wọ́n ti wá sí. Máa tẹ́tí sí wọn kó o sì gbìyànjú láti lóye wọn. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn Kristi.

ORIN 76 Báwo Ló Ṣe Máa Ń Rí Lára Rẹ?

^ ìpínrọ̀ 5 Ó ṣeé ṣe ká máa bá àwọn tí kò ṣe ẹ̀sìn kankan tàbí àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́ pàdé ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ ọ̀nà tá a lè gbà wàásù fún wọn kí wọ́n sì dẹni tó nígbàgbọ́ nínú Bíbélì àti Jèhófà Ọlọ́run.

^ ìpínrọ̀ 1 Nínú ìwádìí táwọn kan ṣe, díẹ̀ rèé lára àwọn ilẹ̀ náà: Alibéníà, Ọsirélíà, Austria, Azerbaijan, Kánádà, Ṣáínà, Czech Republic, Denmark, Faransé, Jámánì, Hong Kong, Ireland, Ísírẹ́lì, Japan, Netherlands, Nọ́wè, South Korea, Sípéènì, Sweden, Switzerland, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Vietnam.

^ ìpínrọ̀ 2 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Nínú àpilẹ̀kọ yìí, àwọn tí kò ṣe ẹ̀sìn kankan làwọn tí kì í lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì tàbí ṣe ẹ̀sìn èyíkéyìí. Ó sì tún tọ́ka sí àwọn tó gbà pé kò sí Ọlọ́run.

^ ìpínrọ̀ 54 ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan ń wàásù fún ẹnì kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ nílé ìwòsàn, ẹ̀yìn náà ni ọkùnrin yẹn wá lọ sí apá Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì lórí Ìkànnì wa.