Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 29

‘Ẹ Lọ, Ẹ Máa Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn’

‘Ẹ Lọ, Ẹ Máa Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn’

“Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.”​—MÁT. 28:19.

ORIN 60 Wọ́n Máa Rí Ìyè Tí Wọ́n Bá Gbọ́

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. (a) Bó ṣe wà nínú Mátíù 28:​18-20, iṣẹ́ pàtàkì wo ni Jésù gbé fún ìjọ Kristẹni? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?

LẸ́YÌN tí Jésù jíǹde, ó ṣètò ìpàdé kan pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lórí òkè kan ní Gálílì. Ó dájú pé ara wọn á ti wà lọ́nà láti rí Jésù, kí wọ́n sì gbọ́ ohun tó fẹ́ sọ. (Mát. 28:16) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ibẹ̀ ló ti “fara han èyí tó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) àwọn ará lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.” (1 Kọ́r. 15:6) Kí nìdí tí Jésù fi ṣètò ìpàdé yìí? Ìdí ni pé ó fẹ́ gbé iṣẹ́ pàtàkì kan lé wọn lọ́wọ́. Ó pàṣẹ fún wọn pé: “Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.”​—Ka Mátíù 28:​18-20.

2 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù lọ́jọ́ yẹn ló wá di ara ìjọ Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tí Jésù gbé fún wọn ni pé kí wọ́n sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn òun. * Lónìí, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìjọ Kristẹni tòótọ́ ló wà kárí ayé, iṣẹ́ yìí làwọn náà sì ń ṣe. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ìbéèrè mẹ́rin: Kí nìdí tí iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn fi ṣe pàtàkì gan-an? Àwọn nǹkan wo la gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè sọni di ọmọ ẹ̀yìn? Ṣé gbogbo Kristẹni ló yẹ kó máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà? Kí sì nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe sùúrù lẹ́nu iṣẹ́ náà?

KÍ NÌDÍ TÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN FI ṢE PÀTÀKÌ GAN-AN?

3. Bó ṣe wà nínú Jòhánù 14:6 àti 17:​3, kí nìdí tí iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn fi ṣe pàtàkì gan-an?

3 Kí nìdí tí iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn fi ṣe pàtàkì gan-an? Ìdí ni pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi nìkan ló lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, ìgbésí ayé àwọn tó bá ń tẹ̀ lé Kristi máa ń nítumọ̀, wọ́n sì nírètí àtigbé títí láé lọ́jọ́ iwájú. (Ka Jòhánù 14:6; 17:3.) Kò sí àní-àní pé iṣẹ́ ńlá ni Jésù gbé fún wa yìí, àmọ́ a ò lè dá iṣẹ́ náà ṣe. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ohun kan nípa ara rẹ̀ àtàwọn Kristẹni bíi tiẹ̀, ó ní: “Alábàáṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ni wá.” (1 Kọ́r. 3:9) Ẹ ò rí i pé àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ni Jèhófà àti Jésù fún wa, bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá!

4. Kí la rí kọ́ látinú ìrírí Arákùnrin Ivan àti ìyàwó rẹ̀ Matilde?

4 Iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn máa ń fún wa láyọ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Ivan àti ìyàwó rẹ̀ Matilde tí wọ́n ń gbé ní Kòlóńbíà. Wọ́n wàásù fún ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Davier. Ọkùnrin yẹn sọ fún wọn pé: “Ó wù mí kí n ṣàtúnṣe sí ìgbésí ayé mi, àmọ́ mi ò mọ bí màá ṣe ṣe é.” Davier máa ń kan ẹ̀ṣẹ́, ó ń lo oògùn olóró, ó ń mutí para, ó sì ní ọ̀rẹ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Erika tí wọ́n jọ ń gbé láì ṣègbéyàwó. Arákùnrin Ivan sọ pé: “A bẹ̀rẹ̀ sí í lọ kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ní abúlé tó ń gbé. Ìyẹn máa ń gba pé ká gun kẹ̀kẹ́ wa fún ọ̀pọ̀ wákàtí, ọ̀nà yẹn ò sì dáa rárá torí ẹrẹ̀ ló kún ibẹ̀. Lẹ́yìn tí Erika kíyè sí àwọn ìyípadà tí Davier ṣe, òun náà gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Nígbà tó yá, Davier ò lo oògùn olóró mọ́, kò mutí mọ́, kò sì kan ẹ̀ṣẹ́ mọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún fẹ́ Erika níṣu lọ́kà. Arábìnrin Matilde sọ pé: “Nígbà tí Davier àti Erika ṣèrìbọmi lọ́dún 2016, a rántí ohun tí Davier máa ń sọ pé, ‘Ó wù mí kí n ṣàtúnṣe sí ìgbésí ayé mi, àmọ́ mi ò mọ bí màá ṣe ṣe é.’ Nígbà tá a rántí, ṣe lomijé ayọ̀ ń dà lójú wa.” Ó ṣe kedere pé a máa ń láyọ̀ gan-an tá a bá ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ọmọlẹ́yìn Kristi.

ÀWỌN NǸKAN WO LA GBỌ́DỌ̀ ṢE KÁ TÓ LÈ SỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN?

5. Kí lohun àkọ́kọ́ tá a máa ṣe tá a bá fẹ́ sọni di ọmọ ẹ̀yìn?

5 Ohun àkọ́kọ́ tá a máa ṣe tá a bá fẹ́ sọni di ọmọ ẹ̀yìn ni pé ká “wá” àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ kàn. (Mát. 10:11) Ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá lóòótọ́ ni pé ká máa wàásù fún gbogbo àwọn tá a bá pàdé. Bẹ́ẹ̀ ni, tá a bá ń pa àṣẹ Kristi mọ́ pé ká wàásù, ṣe là ń fi hàn pé Kristẹni tòótọ́ ni wá.

6. Kí lá jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa wọ àwọn èèyàn lọ́kàn lóde ẹ̀rí?

6 Ó máa ń yá àwọn kan lára láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ ọ̀pọ̀ lára àwọn tá à ń bá pàdé lè kọ́kọ́ ṣe bíi pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù wa. Ó lè gba pé ká ṣe ohun táá mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Bíbélì. Torí náà, tá a bá fẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa wọ̀ wọ́n lọ́kàn, a gbọ́dọ̀ múra ohun tá a máa sọ àti ọ̀nà tá a máa gbà sọ ọ́. Yan àwọn àkòrí tó o mọ̀ pé àwọn tó ò ń wàásù fún máa nífẹ̀ẹ́ sí. Lẹ́yìn ìyẹn, múra bó o ṣe máa gbé e kalẹ̀.

7. Báwo lo ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú ẹnì kan, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o tẹ́tí sí ẹni náà kó o sì bọ̀wọ̀ fún un?

7 Bí àpẹẹrẹ, o lè bi onílé pé: “Ṣé mo lè mọ èrò yín lórí ọ̀rọ̀ yìí? Tó bá jẹ́ pé ìjọba kan ṣoṣo ló ń ṣàkóso ayé, ṣé ẹ rò pé á lè yanjú gbogbo ìṣòro táwa èèyàn ń kojú?” Lẹ́yìn ìyẹn, o lè ka Dáníẹ́lì 2:​44, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò ẹ̀. O sì lè bi òbí kan pé: “Kí lẹ rò pé èèyàn lè ṣe tó bá fẹ́ tọ́ àwọn ọmọ yanjú? Màá fẹ́ mọ èrò yín lórí ọ̀rọ̀ yìí.” Lẹ́yìn ìyẹn, o lè ka Diutarónómì 6:​6, 7, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò ẹ̀. Ohun yòówù kó o ní lọ́kàn láti bá wọn sọ, á dáa kó o ronú nípa àwọn tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀. Ronú nípa bí wọ́n ṣe máa jàǹfààní látinú ọ̀rọ̀ Bíbélì tó o fẹ́ bá wọn sọ. Tẹ́ ẹ bá ń sọ̀rọ̀, rí i dájú pé o tẹ́tí sí wọn dáadáa, kó o sì bọ̀wọ̀ fún wọn kódà tí èrò wọn bá yàtọ̀ sí tìẹ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lóye ohun tí wọ́n ń sọ, àwọn náà á sì fara balẹ̀ tẹ́tí sí ẹ.

8. Kí nìdí tó fi gba ọ̀pọ̀ ìsapá àti àkókò láti ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹnì kan?

8 Nígbà míì, ó máa ń gba ọ̀pọ̀ ìsapá àti àkókò láti ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹnì kan kó tó lè gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí nìdí? Ìdí ni pé a lè má bá àwọn míì nílé tàbí kí wọ́n má ráyè tá a bá pa dà sọ́dọ̀ wọn. Yàtọ̀ síyẹn, ó lè gba pé kó o lọ lọ́pọ̀ ìgbà kí ọkàn ẹni náà tó balẹ̀ pẹ̀lú rẹ, débi táá fi gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Máa rántí pé, kí irúgbìn tó hù dáadáa, a gbọ́dọ̀ máa bomi rin ín déédéé. Bákan náà, ìfẹ́ tí ẹnì kan ní sí Jèhófà àti Jésù máa pọ̀ sí i tá a bá ń bá a sọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé.

ṢÉ GBOGBO KRISTẸNI LÓ YẸ KÓ MÁA LỌ́WỌ́ NÍNÚ IṢẸ́ NÁÀ?

Kárí ayé làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń wá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ (Wo ìpínrọ̀ 9 àti 10) *

9-10. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé gbogbo Kristẹni ló ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn?

9 Gbogbo àwa Kristẹni pátá ló ń lọ́wọ́ nínú wíwá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. A lè fi iṣẹ́ ìwàásù wé àwọn tó ń wá ọmọ kan tó sọ nù. Lọ́nà wo? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n ń wá ọmọ ọdún mẹ́ta kan tó sọ nù. Àwọn èèyàn bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ló wá ọmọ náà kiri. Lẹ́yìn ogún (20) wákàtí tí ọmọ náà ti sọ nù, ọ̀kan lára àwọn tó ń wá a rí i nínú oko àgbàdo kan. Ọkùnrin yẹn ò jẹ́ kí wọ́n kan sárá sí òun pé òun lòhún wá ọmọ náà rí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ ni pé: “Ẹnì kan kì í jẹ́ àwa dé, gbogbo wa pátá la jẹ́ kó ṣeé ṣe.”

10 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló dà bí ọmọ yẹn torí pé wọn ò mọ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wọn ò nírètí, torí náà wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́. (Éfé. 2:12) Lónìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá à ń wá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ ju mílíọ̀nù mẹ́jọ lọ. Nínú ìjọ tó o wà, o lè má ní ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn kan nínú ìjọ rẹ lè ní àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí náà, tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan nínú ìjọ rẹ bá kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ tó sì ṣèrìbọmi, ó yẹ kí inú gbogbo wa dùn torí àjọṣe gbogbo wa ni.

11. Tó ò bá tiẹ̀ ní àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, báwo lo ṣe lè máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn?

11 Ká tiẹ̀ sọ pé o ò ní àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí, o ṣì lè lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn láwọn ọ̀nà míì. Bí àpẹẹrẹ, o lè fi tayọ̀tayọ̀ kí àwọn ẹni tuntun káàbọ̀ sí ìpàdé tàbí kó o bá wọn ṣọ̀rẹ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá jẹ́ kí wọ́n rí i pé Kristẹni tòótọ́ ni wá bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wa. (Jòh. 13:​34, 35) Tó o bá ń dáhùn nípàdé, bó tiẹ̀ jẹ́ ṣókí, ńṣe lò ń kọ́ àwọn ẹni tuntun bí wọ́n ṣe lè dáhùn lọ́rọ̀ ara wọn, kí wọ́n sì sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́. O tún lè ṣètò láti lọ sóde ẹ̀rí pẹ̀lú akéde tuntun kan, kó o sì jẹ́ kó rí bó ṣe lè máa fi Ìwé Mímọ́ fèrò wérò pẹ̀lú àwọn èèyàn. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àpẹẹrẹ Kristi lò ń tẹ̀ lé yẹn.​—Lúùkù 10:​25-28.

12. Ṣé ó dìgbà tá a bá ní àwọn ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ ká tó lè sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn? Ṣàlàyé.

12 Kò dìgbà tá a bá ní àwọn ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ ká tó lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arábìnrin Faustina tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Bòlífíà. Kò mọ ìwé kà nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó kọ́ bí wọ́n ṣe ń kàwé déwọ̀n àyè kan. Ní báyìí, ó ti ṣèrìbọmi, ó sì fẹ́ràn kó máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó kéré tán, ó máa ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ márùn-ún lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Arábìnrin Faustina kò mọ̀wé kà tó àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, síbẹ̀ èèyàn mẹ́fà ló ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n sì ti ṣèrìbọmi.​—Lúùkù 10:21.

13. Tá a bá tiẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ojúṣe tá à ń bójú tó, àwọn ìbùkún wo la máa rí lẹ́nu iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn?

13 Ọ̀pọ̀ Kristẹni lọwọ́ wọn máa ń dí torí àwọn ojúṣe tí wọ́n ń bójú tó. Síbẹ̀, wọ́n máa ń wáyè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn sì ń fún wọn láyọ̀. Ẹ jẹ́ ká wo ìrírí Arábìnrin Melanie tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Alaska. Òbí tó ń dá tọ́mọ ni, ó sì ní ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́jọ kan. Yàtọ̀ síyẹn, iṣẹ́ bó-o-jí-o-jí-mi ló ń ṣe, ó sì tún ń tọ́jú bàbá rẹ̀ tó ní àrùn jẹjẹrẹ. Arábìnrin Melanie nìkan ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú wọn. Tó bá ti fẹ́ lọ wàásù, ó máa ń bẹ Jèhófà pé kó fún òun ní okun kóun lè fara da òtútù torí pé ó wù ú kó ní ẹni táá máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tó yá, ó pàdé Sara. Inú Sara dùn gan-an nígbà tó mọ̀ pé Ọlọ́run ní orúkọ, ó sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Arábìnrin Melanie sọ pé: “Láwọn ìrọ̀lẹ́ Friday, ó ti máa ń rẹ̀ mí tẹnutẹnu, síbẹ̀ èmi àti ọmọ mi máa ń sapá láti lọ kọ́ obìnrin náà lẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn sì ń fún wa láyọ̀. A máa ń gbádùn ká máa ṣèwádìí àwọn ìbéèrè tí Sara bi wá, inú wa sì dùn gan-an nígbà tó di ọ̀rẹ́ Jèhófà.” Tẹbí-tọ̀rẹ́ ló ta ko Sara, síbẹ̀ ó fara dà á. Yàtọ̀ síyẹn, ó lo ìgboyà, ó fi ẹ̀sìn tó ń ṣe sílẹ̀, ó sì ṣèrìbọmi.

KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA ṢE SÙÚRÙ LẸ́NU IṢẸ́ NÁÀ?

14. (a) Báwo lọ̀rọ̀ àwọn tó ń sọni di ọmọ ẹ̀yìn ṣe jọ tàwọn apẹja? (b) Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú 2 Tímótì 4:​1, 2 ṣe rí lára rẹ?

14 Tó ò bá tiẹ̀ tíì rí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́, má jẹ́ kó sú ẹ. Máa rántí pé Jésù fi iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn wé iṣẹ́ ẹja pípa. Àwọn apẹja máa ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí kí wọ́n tó rí ẹja pa. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń wà lórí omi ní gbogbo òru mọ́jú, kódà nígbà míì wọ́n máa ń wakọ̀ lọ sọ́nà jíjìn kí wọ́n tó rí ẹja pa. (Lúùkù 5:5) Lọ́nà kan náà, àwọn kan tó ń sọni di ọmọ ẹ̀yìn máa ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí bíi tàwọn apẹja, wọ́n máa ń lọ síbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láwọn àsìkò tó yàtọ̀ síra. Kí nìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé wọ́n fẹ́ wá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ kàn. Àwọn tó ń sapá gan-an láti wá àwọn ẹni yíyẹ sábà máa ń rí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa. Ṣé ìwọ náà lè lọ wàásù lásìkò tó ṣeé ṣe kó o rí àwọn èèyàn tàbí níbi táá ti rọrùn láti bá wọn sọ̀rọ̀?​—Ka 2 Tímótì 4:​1, 2.

Máa mú sùúrù fún àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ bí wọ́n ṣe ń fi ẹ̀kọ́ òtítọ́ sílò (Wo ìpínrọ̀ 15 àti 16) *

15. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe sùúrù pẹ̀lú àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

15 Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe sùúrù pẹ̀lú àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ìdí kan ni pé kì í ṣe bí wọ́n ṣe máa lóye ẹ̀kọ́ Bíbélì kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ nìkan la ṣe ń kọ́ wọn. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n mọ Jèhófà tó jẹ́ Òǹṣèwé Bíbélì, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Yàtọ̀ sí pé ká jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ kan mọ àwọn ìlànà tí Jésù fi lélẹ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, a tún gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè máa fi àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ ṣèwà hù nígbèésí ayé wọn. Èyí máa gba pé ká ní sùúrù fún wọn bí wọ́n ṣe ń gbìyànjú láti fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Kì í pẹ́ táwọn kan fi máa ń yí ìgbésí ayé wọn pa dà, àmọ́ ó máa ń pẹ́ káwọn míì tó lè ṣe bẹ́ẹ̀.

16. Kí la rí kọ́ látinú ìrírí Raúl?

16 Míṣọ́nnárì kan lórílẹ̀-èdè Peru sọ ìrírí kan tó jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká máa ní sùúrù. Arákùnrin náà sọ pé: “A ti parí ìwé méjèèjì tá a fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú Raúl, àmọ́ ó ṣì ń nira fún un láti ṣe àwọn àtúnṣe kan. Bí àpẹẹrẹ, àárín òun àti ìyàwó rẹ̀ ò gún, ó máa ń bú èébú, àwọn ọmọ rẹ̀ sì máa ń gbó o lẹ́nu. Torí pé ó máa ń wá sípàdé déédéé, mi ò ṣíwọ́ lílọ sọ́dọ̀ rẹ̀ kí n lè ran òun àti ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́. Ẹ̀yìn ọdún mẹ́ta tá a ti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ló tó ṣèrìbọmi.”

17. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?

17 Jésù sọ fún wa pé “ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” Ká lè pa àṣẹ yẹn mọ́, a máa ń bá onírúurú èèyàn sọ̀rọ̀ títí kan àwọn tí èrò wọn yàtọ̀ sí tiwa, àwọn tí kò ní ẹ̀sìn kankan àtàwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa rí bá a ṣe lè wàásù lọ́nà tó gbéṣẹ́ fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀.

ORIN 68 Máa Fún Irúgbìn Ìjọba Náà

^ ìpínrọ̀ 5 Iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tí ìjọ Kristẹni ń ṣe ni láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí àwọn nǹkan tá a lè ṣe ká lè ṣe iṣẹ́ yìí láṣeyanjú.

^ ìpínrọ̀ 2 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ lóòótọ́, àmọ́ wọ́n ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n máa ń fi ohun tí wọ́n kọ́ sílò. Wọ́n máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù pẹ́kípẹ́kí.​—1 Pét. 2:21.

^ ìpínrọ̀ 52 ÀWÒRÁN: Ọkùnrin kan tó ń rìnrìn àjò gba ìwé kan lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tó pàtẹ ìwé ní ibùdókọ̀ òfúrufú. Nígbà tó dé ibi tó ń lọ, ó tún rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbi tí wọ́n pàtẹ ìwé sí. Nígbà tó délé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá wàásù fún un.

^ ìpínrọ̀ 54 ÀWÒRÁN: Ọkùnrin yẹn gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nígbà tó yá, ó ṣèrìbọmi.