Kí Lèrò Rẹ?
Ṣé Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?
ÀWỌN KAN GBÀ PÉ . . .
àwọn ò lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run torí wọ́n rò pé aláìmọ́ àti ẹlẹ́ṣẹ̀ ni àwọn. Àwọn míì sọ pé Ọlọ́run ò rí ti àwa èèyàn rò. Kí lèrò rẹ?
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
“Ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ [Ọlọ́run] wà pẹ̀lú àwọn adúróṣánṣán.” (Òwe 3:32) A máa di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tí a bá ń ṣègbọràn sí i.
KÍ LÀWỌN NǸKAN MÍÌ TÍ BÍBÉLÌ SỌ?
Ọlọ́run fẹ́ di Ọ̀rẹ́ wa.—Jákọ́bù 4:8.
Torí pé Ọlọ́run jẹ́ Ọ̀rẹ́ wa, ó múra tán láti ràn wá lọ́wọ́ kó sì dárí jì wá.—Sáàmù 86:5.
Àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run máa ń nífẹ̀ẹ́ ohun tí Ọlọ́run fẹ́, wọ́n sì máa ń kórìíra ohun tí Ọlọ́run kò fẹ́.—Róòmù 12:9.