2 Ó Ń Jẹ́ Ká Borí Ìṣòro
Àwọn ìṣòro kan wà tí kì í lọ bọ̀rọ̀, wọ́n sì lè wà fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àwọn ìṣòro yìí lè ti wọ èèyàn lára gan-an kéèyàn tó mọ̀. Ṣé Bíbélì sọ ọgbọ́n téèyàn lè dá tó máa jẹ́ kó borí irú àwọn ìṣòro tí kò lọ bọ̀rọ̀ tó sì ń tán ni lókun bẹ́ẹ̀? Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀.
ÀNÍYÀN TÓ PỌ̀ LÁPỌ̀JÙ
Rosie sọ pé, “Àníyàn tí mò ń ṣe nípa àwọn ìṣòro mi máa ń pọ̀ débi pé mo máa ń ronú pé nǹkan burúkú kan máa ṣẹlẹ̀ sí mi.” Ẹsẹ Bíbélì wo ló ràn án lọ́wọ́? Ọ̀kan lára ẹ̀ ni Mátíù 6:34, ó ní: “Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, nítorí ọ̀la yóò ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Búburú ti ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tó fún un.” Rosie sọ pé ọ̀rọ̀ Jésù yìí ló ran òun lọ́wọ́ tí òun kò fi kó ọkàn sókè mọ́ nípa ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ lọ́la. Ó fi kún un pé, “Mo ti ní ìṣòro tó pọ̀ ti mò ń bá yí, mi ò tún fẹ́ fi àníyàn nípa ohun tí kò tíì ṣẹlẹ̀ kún un tàbí àwọn ohun tó ṣeé ṣe kò má ṣẹlẹ̀ rárá.”
Yasmine náà kíyè sí i pé àníyàn ti fẹ́ gba òun lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ. “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń sunkún láàárín ọ̀sẹ̀, tí mi ò sì ní rí oorun sùn lóru. Mo rí i pé èrò tí kò tọ́ ti sọ mí di ìdàkudà.” Ẹsẹ Bíbélì wo ló ràn án lọ́wọ́? Ó tọ́ka sí 1 Pétérù 5:7 tó ní: “Ẹ kó gbogbo àníyàn yín lé [Ọlọ́run], nítorí ó bìkítà fún yín.” Yasmine sọ pé: “Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì dáhùn àdúrà mi. Ṣe ló dà bíi pé wọ́n gbé ẹrù tó wúwo kúrò lórí mi. Àwọn èrò tí kò tọ́ yẹn ṣì máa ń wá sí mi lọ́kàn, àmọ́ ní báyìí mo ti mọ ohun tí mo lè ṣe sí i.”
FÍFI NǸKAN FALẸ̀
Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Isabella sọ pé: “Mo ronú pé àìsàn ìdílé ni fífi nǹkan falẹ̀ jẹ́ fún mi, torí pé ó ń ṣe dádì mi náà. Mo máa ń fi nǹkan gidi tó yẹ kí n ṣe sílẹ̀, mi ò sì ní ṣe nǹkan kan, ju pé kí n kàn jókòó lásán tàbí kí n máa wo tẹlifíṣọ̀n. Àṣà tó léwu ni torí pé ó máa ń jẹ́ kí wàhálà pọ̀ sí i tàbí kéèyàn máa ṣiṣẹ́ tí ò dáa tó.” Ìlànà kan tó ràn án lọ́wọ́ wà nínú 2 Tímótì 2:15, tó sọ pé: “Sa gbogbo ipá rẹ láti fi ara rẹ hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú.” Isabella sọ pé: “Mi ò fẹ́ kí Jèhófà fi ojú tí ò dáa wo iṣẹ́ mi torí pé mò ń fi nǹkan falẹ̀.” Isabella ti wá ń ṣe dáadáa gan-an báyìí.
Kelsey náà nírú ìṣòro yìí, ó sọ pé: “Mi ò kì í ṣe iṣẹ́ mi nígbà tó yẹ, àfìgbà tó bá ti bọ́ sórí tán. Màá wá máa sunkún, màá ṣe àìsùn, màá sì máa dààmú kiri. Ìyẹn ò dáa rárá.” Ọ̀rọ̀ tó wà ní Òwe 13:16 ran Kelsey lọ́wọ́, ẹsẹ náà sọ pé: “Ẹni tí ó jẹ́ afọgbọ́nhùwà yóò fi ìmọ̀ hùwà, ṣùgbọ́n ẹni tí ó jẹ́ arìndìn yóò tan ìwà òmùgọ̀ káàkiri.” Ó ṣàlàyé ẹ̀kọ́ tó kọ́ nígbà tó ronú lórí ẹsẹ Bíbélì yìí, ó ní: “Ó ṣe pàtàkì kéèyàn mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́, kó sì máa múra sílẹ̀. Ní báyìí, mo ní ìwé kékeré kan tó máa ń wà lórí tábìlì mi, inú ẹ̀ ni mo máa ń kọ àwọn ohun tí mo fẹ́ ṣe sí, èyí máa ń jẹ́ kí n lè ṣètò àwọn ohun tí mo fẹ́ ṣe kó tó bọ́ sórí.”
ÌDÁNÌKANWÀ
Kirsten sọ pé: “Ọkọ mi kọ̀ mí sílẹ̀, ó sì fàwọn ọmọ wa kékeré mẹ́rin sílẹ̀ fún èmi nìkan.” Ìlànà Bíbélì wo ló ràn án lọ́wọ́? Òwe 17:17 kà pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” Kirsten wá sún mọ́ àwọn tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà. Àǹfààní wo ló rí níbẹ̀? “Àwọn ọ̀rẹ́ mi ràn mí lọ́wọ́ ní onírúurú ọ̀nà! Àwọn kan máa ń gbé oúnjẹ àti òdòdó wá sílé mi. Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn èèyàn ran èmi àtàwọn ọmọ mi lọ́wọ́ nígbà tí a kó lọ sí ilé míì. Ẹnì kan bá mi wá iṣẹ́. Àwọn ọ̀rẹ́ mi ò sì fi mí sílẹ̀ nígbà kankan.”
Delphine, tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ tẹ́lẹ̀ náà ní ìṣòro ìdánìkanwà. Ó sọ ìṣòro tó ní lẹ́yìn tó pàdánù gbogbo nǹkan, ó ní: “Gbogbo èèyàn ló ń gbé níṣọ̀kan tí nǹkan sì ń lọ dáadáa fún wọn. Àmọ́ ńṣe ni ìbànújẹ́ dorí tèmi kodò tí mo sì dánìkan wà.” Ẹsẹ Bíbélì kan tó ràn án lọ́wọ́ ni Sáàmù 68:6 tó sọ pé: “Ọlọ́run ń mú kí àwọn adánìkanwà máa gbé inú ilé.” Ó ṣàlàyé pé: “Mo mọ̀ pé kì í ṣe ilé gbígbé ni ẹsẹ Bíbélì yẹn ń tọ́ka sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yé mi pé ibi ààbò nípa tẹ̀mí ni Ọlọ́run fẹ́ fún wa, ìyẹn ibi téèyàn ti máa ní ojúlówó ààbò, táá sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn míì tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Àmọ́ mo mọ̀ pé mi ò lè sún mọ́ àwọn èèyàn tí mi ò bá kọ́kọ́ sún mọ́ Jèhófà dáadáa. Torí náà Sáàmù 37:4 ràn mí lọ́wọ́ lórí èyí, ó ní: ‘Máa ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà, Òun yóò sì fún ọ ní àwọn ìbéèrè tí ó ti inú ọkàn-àyà rẹ wá.’ ”
Ó wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Mo gbà pé ó yẹ kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà dáadáa. Òun ló dáa jù láti sún mọ́. Lẹ́yìn náà, mo ṣe àkọsílẹ̀ àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run tí mo lè máa ṣe pẹ̀lú àwọn míì, kí n lè túbọ̀ sún mọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Mo kọ́ láti máa wo ibi táwọn èèyàn dáa sí, kí n sì máa gbọ́kàn kúrò lórí àwọn àṣìṣe wọn.”
Lóòótọ́, aláìpé náà ṣì làwọn èèyàn tó ń sin Ọlọrun. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ní àwọn ìṣòro tí à ń bá yí bíi tàwọn èèyàn tó kù láyé. Àmọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì ń jẹ́ ká lè máa ṣèrànwọ́ fáwọn míì nígbà tó bá ṣeé ṣe. Ó bọ́gbọ́n mu ká yan irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́rẹ̀ẹ́. Ṣùgbọ́n, ṣé àwọn ìlànà Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ lórí àwọn ìṣòro tí a ò lè mú kúrò lóde òní, irú bí àìsàn tó le koko àti ikú ẹni tá a nífẹ̀ẹ́?
Tó o bá fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, ó máa jẹ́ kó o láwọn ọ̀rẹ́ tó ń dúró tini nígbà ìṣòro