Ohun Tó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Ọjọ́ Iwájú
Ṣé o máa ń ronú nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan máa wáyé lọ́jọ́ iwájú, tó sì máa kan gbogbo èèyàn.
Jésù sọ àwọn nǹkan tó máa jẹ́ ká “mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́lé.” (Lúùkù 21:31) Lára àwọn nǹkan tó sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀ ni, àwọn ogun ńlá, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára, àìtó oúnjẹ àti àjàkálẹ̀ àrùn. Àwọn nǹkan yìí sì ń ṣẹlẹ̀ lónìí lóòótọ́.—Lúùkù 21:10-17.
Bíbélì tún sọ ìwà táwọn èèyàn á máa hù nígbà tí ìṣàkóso èèyàn bá ti wà ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ó ní àwọn èèyàn á máa hùwàkíwà. O lè ka àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní 2 Tímótì 3:1-5. Tó o bá kíyè sí ìwà àti ìṣe àwọn èèyàn lónìí, ó dájú pé wàá gbà pé àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò yìí bá àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yẹn mu.
Kí ni èyí túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé kò ní pẹ́ mọ́ tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe àwọn àyípadà ńlá tó máa tún ayé yìí ṣe lọ́nà tó dára gan-an. (Lúùkù 21:36) Ọlọ́run ṣèlérí àwọn ohun rere fún aráyé nínú Bíbélì. Àpẹẹrẹ díẹ̀ lára wọn nìyí.
ÌJỌBA RERE
“A sì fún [Jésù] ní àkóso, ọlá àti ìjọba, pé kí gbogbo àwọn èèyàn, orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà máa sìn ín. Àkóso rẹ̀ jẹ́ àkóso tó máa wà títí láé, tí kò ní kọjá lọ, ìjọba rẹ̀ ò sì ní pa run.”—DÁNÍẸ́LÌ 7:14.
Ohun tó túmọ̀ sí: O lè gbádun ayé rẹ lábẹ́ ìjọba gidi tó máa kárí ayé, èyí tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ tó sì fi Ọmọ rẹ̀ ṣe Ọba.
ÌLERA TÓ DÁA
“Kò sí ẹnì kankan tó ń gbé ibẹ̀ tó máa sọ pé: ‘Ara mi ò yá.’”—ÀÌSÁYÀ 33:24.
Ohun tó túmọ̀ sí: Àìsàn ò ní ṣe ẹ́ mọ́ láé, o ò sì ní di aláàbọ̀ ara; wàá tún ní àǹfààní láti wà láàyè láìní kú.
ÀLÀÁFÍÀ KÁRÍ AYÉ
Ọlọ́run máa “fòpin sí ogun kárí ayé.”—SÁÀMÙ 46:9.
Ohun tó túmọ̀ sí: A ò ní gbúròó ogun mọ́ àtàwọn nǹkan burúkú tó máa ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ogun.
ÈÈYÀN RERE NÌKAN LÓ MÁA WÀ LÁYÉ
“Àwọn ẹni burúkú ò ní sí mọ́ . . . Àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóò jogún ayé.”—SÁÀMÙ 37:10, 11.
Ohun tó túmọ̀ sí: Kò ní sí àwọn ẹni burúkú mọ́, àwọn tó ń gbọ́ràn sí Ọlọ́run lẹ́nu nìkan ló máa ṣẹ́ kù.
GBOGBO AYÉ MÁA DI PÁRÁDÍSÈ
“Wọ́n á kọ́ ilé, wọ́n sì máa gbé inú wọn, wọ́n á gbin ọgbà àjàrà, wọ́n sì máa jẹ èso wọn.”—ÀÌSÁYÀ 65:21, 22.
Ohun tó túmọ̀ sí: Gbogbo ayé máa lẹ́wà gan-an. Ọlọ́run máa dáhùn àdúrà tá a máa ń gbà pé kí ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ “ní ayé.”—Mátíù 6:10.