Àǹfààní Tí Wàá Rí Tó O Bá Mọ Òtítọ́
Ọlọ́run kì í parọ́, ó máa fún ẹ ní ìrètí “ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16.
KÍ LÓ YẸ KÓ O ṢE?
Máa kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Jòhánù 17:3, 17.
Máa gbọ́ràn sí Ọlọ́run lẹ́nu.—Diutarónómì 30:19, 20.
Máa fi ìmọ̀ràn Ọlọ́run sílò láyé rẹ̀.—Jémíìsì 1:25.
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ń jàǹfààní bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ látinú Bíbélì. Inú wa máa dùn láti fi àwọn ohun tá à ń kọ́ nínú Bíbélì hàn ẹ́.
Kó o lè túbọ̀ mọ àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, wo ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é, ó sì wà lórí ìkànnì www.pr418.com/yo.