Ohun Tó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Ìjọba Ọlọ́run
Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di mímọ́. Kí Ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ ní ayé, bíi ti ọ̀run.” (Mátíù 6:9, 10) Kí ni Ìjọba Ọlọ́run? Kí ló máa ṣe? Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà pé kí Ìjọba náà dé?
Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run.
Lúùkù 1:31-33 sọ pé: “Kí o pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù. Ẹni yìí máa jẹ́ ẹni ńlá, wọ́n á máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ, Jèhófà Ọlọ́run sì máa fún un ní ìtẹ́ Dáfídì bàbá rẹ̀, ó máa jẹ Ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, Ìjọba rẹ̀ ò sì ní lópin.”
Ìjọba Ọlọ́run ni ìwàásù Jésù dá lé.
Mátíù 9:35 sọ pé: “Jésù wá bẹ̀rẹ̀ sí í lọ káàkiri gbogbo ìlú àti abúlé, ó ń kọ́ni nínú àwọn sínágọ́gù wọn, ó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà, ó sì ń wo onírúurú àìsàn àti onírúurú àìlera sàn.”
Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní àmì tó máa jẹ́ kí wọ́n mọ ìgbà tí Ìjọba náà máa dé.
Mátíù 24:7 sọ pé: “Torí orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba, àìtó oúnjẹ àti ìmìtìtì ilẹ̀ sì máa wà láti ibì kan dé ibòmíì.”
Lónìí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé.
Mátíù 24:14 sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.”