A Lè Borí Ìkórìíra!
Ṣẹ́nì kan ti ṣohun tí ò dáa sí ẹ rí torí pé ó kórìíra ẹ?
Ká tiẹ̀ sọ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí, ó ṣeé ṣe kó o ti rí i táwọn kan hùwà ìkà sẹ́nì kan torí pé wọ́n kórìíra ẹ̀. A máa ń gbọ́ nípa báwọn kan ṣe ń fìyà jẹ àwọn míì torí pé wọn kì í ṣọmọ ìlú kan náà tàbí ẹ̀yà kan náà. Ó sì lè jẹ́ torí pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ́ ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin lò pọ̀ tàbí obìnrin tó ń bá obìnrin lò pọ̀. Èyí ló mú káwọn ìjọba ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ṣòfin pé tí wọ́n bá rí ẹnikẹ́ni tó ń fìyà jẹ ẹnì kan torí pé ó kórìíra ẹ̀, onítọ̀hún á jẹ palaba ìyà.
Àwọn kan máa ń kórìíra àwọn ẹlòmíì torí ohun tójú wọn ti rí báwọn èèyàn ṣe kórìíra wọn. Wọ́n tiẹ̀ lè bá a débi táwọn náà á fi máa hùwà ìkà sáwọn míì, tí nǹkan bá sì ń lọ bẹ́ẹ̀, ìkórìíra ò ní tán nílẹ̀.
Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti rí i táwọn kan ṣe ẹ̀tanú sáwọn míì, tí wọ́n ní èrò burúkú nípa wọn, tí wọ́n ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́, tí wọ́n ń kàn wọ́n lábùkù tàbí tí wọ́n ń halẹ̀ mọ́ wọn. Kódà, ó máa ń le débi pé àwọn kan máa ń lu àwọn míì nílùkulù, wọ́n máa ń ba nǹkan àwọn èèyàn jẹ́, wọ́n máa ń fipá báwọn kan lò pọ̀, àwọn míì tiẹ̀ lè pa àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà wọn.
Nínú ìwé yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè borí ìkórìíra, a sì máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí tí ìkórìíra fi pọ̀ láyé?
Báwo la ṣe lè borí ìkórìíra?
Ṣé ìgbà kan ń bọ̀ táwọn èèyàn ò ní máa kórìíra ara wọn mọ́?