Ibi Gbogbo Ni Ìkórìíra Wà
Kò síbi kan láyé yìí táwọn èèyàn ò ti lẹ́mìí ìkórìíra.
Léraléra làwọn oníròyìn ń sọ̀rọ̀ nípa báwọn èèyàn ṣe kórìíra ara wọn. Oríṣiríṣi ọ̀nà làwọn èèyàn ń gbà fẹ̀mí ìkórìíra hàn, wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ lójúkojú, lórí ìkànnì àjọlò, lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí kí wọ́n kọ lẹ́tà. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ti halẹ̀ mọ́ àwọn kan, wọ́n kan àwọn míì lábùkù, wọ́n lé àwọn kan kúrò nílùú, wọ́n sì ba ohun ìní àwọn míì jẹ́. Kò síbi téèyàn yíjú sí tí ò ti ní ráwọn èèyàn tó ń jìyà nítorí ìkórìíra. Ó délé ó dóko!
Ìwé yìí á jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè borí ìkórìíra. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o lè borí, kì í ṣe ohun tí kò ṣeé ṣe, kódà ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti borí ìkórìíra kárí ayé.