Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OHUN TÓ LÈ FÒPIN SÍ ÌKÓRÌÍRA

2 | Má Ṣe Gbẹ̀san

2 | Má Ṣe Gbẹ̀san

Ohun Tí Bíbélì Sọ:

“Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnikẹ́ni. . . . Tó bá ṣeé ṣe, nígbà tó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ló wà, ẹ wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo èèyàn. Ẹ má ṣe fúnra yín gbẹ̀san, . . . nítorí ó ti wà lákọsílẹ̀ pé: ‘“Tèmi ni ẹ̀san; màá gbẹ̀san,” ni Jèhófà wí.’”​RÓÒMÙ 12:​17-19.

Ohun Tó Túmọ̀ Sí:

Ká sòótọ́, inú lè bí wa tẹ́nì kan bá ṣe ohun tí ò dáa sí wa, àmọ́ Ọlọ́run ò fẹ́ ká máa gbẹ̀san. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run fẹ́ ká máa mú sùúrù, torí pé kò ní pẹ́ fòpin sí ìwà ibi àti ìrẹ́jẹ.​—Sáàmù 37:​7, 10.

Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe:

Táwa èèyàn aláìpé bá ń gbẹ̀san, ìyẹn ò ní paná ìkórìíra ṣe lá túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Torí náà, tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ ẹ́ tàbí tó ṣàìdáa sí ẹ, má ṣe gbẹ̀san, má sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà ká ẹ lára jù, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni kó o fi sùúrù bá ẹni náà sọ̀rọ̀. Nígbà míì, ohun tó máa dáa jù ni pé ká gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn. (Òwe 19:11) Àmọ́, tó o bá rí i pé o ò lè gbé e kúrò lọ́kàn, o lè wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ náà. Bí àpẹẹrẹ, táwọn ọ̀daràn bá gbéjà kò ẹ́, o lè fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn ọlọ́pàá tàbí àwọn aláṣẹ míì létí.

Àkóbá kékeré kọ́ lẹni tó bá ń gbẹ̀san máa ń ṣe fún ara ẹ̀

Ká sọ pé kò sí bẹ́ ẹ ṣe lè yanjú ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tí kò la ariwo lọ ńkọ́? Àbí o ti ṣe gbogbo nǹkan tó yẹ kó o ṣe láti fi sùúrù yanjú ọ̀rọ̀ náà? Má ṣe gbẹ̀san. Torí tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lọ̀rọ̀ náà á wá burú sí i. Dípò tí wàá fi gbẹ̀san, ńṣe ni kó o paná ìkórìíra. Ohun tó máa dáa ni pé kó o fi ọ̀rọ̀ náà lé Ọlọ́run lọ́wọ́ kó lè bá ẹ yanjú ẹ̀. “Gbẹ́kẹ̀ lé e, yóò sì gbé ìgbésẹ̀ nítorí rẹ.”​—Sáàmù 37:​3-5.