Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OHUN TÓ LÈ FÒPIN SÍ ÌKÓRÌÍRA

3 | Mú Ìkórìíra Kúrò Lọ́kàn Rẹ

3 | Mú Ìkórìíra Kúrò Lọ́kàn Rẹ

Ohun Tí Bíbélì Sọ:

“Ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín pa dà, kí ẹ lè fúnra yín ṣàwárí ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.”​RÓÒMÙ 12:2.

Ohun Tó Túmọ̀ Sí:

Èrò wa ṣe pàtàkì sí Ọlọ́run. (Jeremáyà 17:10) Torí náà, yàtọ̀ sí pé ká yẹra fáwọn ọ̀rọ̀ tàbí ìwà tó máa fi hàn pé a kórìíra àwọn èèyàn, a tún gbọ́dọ̀ mú gbogbo ohun tó lè mú ká kórìíra àwọn èèyàn kúrò lọ́kàn wa, torí pé inú ọkàn ni ìkórìíra ti ń bẹ̀rẹ̀. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá fi hàn pé à ń “para dà,” ìyẹn á sì mú ká borí ìkórìíra.

Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe:

Fara balẹ̀ ronú nípa èrò tó o ní nípa àwọn èèyàn, ní pàtàkì àwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè míì tàbí àwọn tí ẹ̀yà wọn yàtọ̀ sí tìẹ. Bi ara ẹ pé: ‘Èrò wo ni mo ní nípa wọn? Ṣé ohun tí mo mọ̀ nípa wọn ló jẹ́ kí n nírú èrò yẹn? Àbí torí ibi tí wọ́n ti wá tàbí ẹ̀yà wọn ló jẹ́ kí n nírú èrò náà?’ Á dáa kó o yẹra fáwọn fíìmù àtàwọn eré ìnàjú tí wọ́n ti ń hùwà ipá, kó o sì yẹra fàwọn ìkànnì tó ń kọ́ni nípa ìkórìíra àti ìwà ipá.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìkórìíra tó wà lọ́kàn wa

Kì í sábà rọrùn láti ṣàyẹ̀wò èrò wa láìtan ara wa jẹ. Àmọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti ‘mọ ìrònú wa àti ohun tí ọkàn wa ń gbèrò.’ (Hébérù 4:12) Torí náà, máa ka Bíbélì déédéé, máa fi èrò rẹ wéra pẹ̀lú ohun tí Bíbélì sọ, kó o sì máa gbìyànjú láti mú kí èrò rẹ bá ohun tí Bíbélì sọ mu. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìkórìíra tó ti “fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in” nínú ọkàn wa.​—2 Kọ́ríńtì 10:​4, 5.