OHUN TÓ LÈ FÒPIN SÍ ÌKÓRÌÍRA
4 | Ọlọ́run Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Láti Borí Ìkórìíra
Ohun Tí Bíbélì Sọ:
“Èso ti ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, sùúrù, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.”—GÁLÁTÍÀ 5:22, 23.
Ohun Tó Túmọ̀ Sí:
Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìkórìíra. Òótọ́ ni pé àwọn ìwà rere kan wà tó lè má rọrùn fún wa láti ní, àmọ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní wọn. Torí náà, dípò ká máa gbìyànjú láti borí ìkórìíra fúnra wa, ṣe ló yẹ ká jẹ́ kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́. Tá a bá jẹ́ kó ràn wá lọ́wọ́, ọ̀rọ̀ tiwa náà máa dà bíi ti Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.” (Fílípì 4:13) Àwa náà á lè sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ mi ti ń wá.”—Sáàmù 121:2.
Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe:
“Ní báyìí, mi ò hùwà ipá mọ́ torí Jèhófà ti sọ mí di èèyàn àlááfíà.”—WALDO
Fi tọkàntọkàn gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Lúùkù 11:13) Bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa hùwà tó dáa. Kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìwà tó jẹ́ òdìkejì ìkórìíra, irú bí ìfẹ́, àlàáfíà, sùúrù àti ìkóra-ẹni-níjàánu. Jẹ́ káwọn ìwà yìí máa hàn nínú gbogbo ohun tó ò ń ṣe lójoojúmọ́. Kó o sì máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn tó ń gbìyànjú láti máa hu irú ìwà bẹ́ẹ̀, torí wọ́n “máa mú kó wù [ẹ́] láti ní ìfẹ́ àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ rere.”—Hébérù 10:24; àlàyé ìsàlẹ̀.