OHUN TÓ LÈ FÒPIN SÍ ÌKÓRÌÍRA
1 | Yẹra fún Ojúsàájú
Ohun Tí Bíbélì Sọ:
“Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, àmọ́ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tó bá bẹ̀rù rẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ ni ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.”—ÌṢE 10:34, 35.
Ohun Tó Túmọ̀ Sí:
Kì í ṣe orílẹ̀-èdè wa, ẹ̀yà wa, àwọ̀ wa tàbí àṣà ìbílẹ̀ wa ni Jèhófà * fi ń dá wa lẹ́jọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ló máa ń wò, ìyẹn ohun tó wà lọ́kàn wa. Bíbélì sọ pé: “Ohun tí ó bá hàn síta ni èèyàn ń rí, ṣùgbọ́n Jèhófà ń rí ohun tó wà nínú ọkàn.”—1 Sámúẹ́lì 16:7.
Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe:
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lè mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn, ó yẹ ká rí i pé a kì í ṣe ojúsàájú bíi ti Ọlọ́run. Kò yẹ kó o kórìíra ẹnì kan torí ohun táwọn èèyàn gbà gbọ́ nípa ẹni náà, torí ibi tó ti wá, èdè tó ń sọ tàbí àwọn nǹkan míì. Tó o bá rí i pé o ti ń ní èrò tí ò dáa nípa àwọn èèyàn, gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè borí irú èrò bẹ́ẹ̀. (Sáàmù 139:23, 24) Tó o bá fi tọkàntọkàn bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lókun kó o má bàa máa ṣe ojúsàájú, jẹ́ kó dá ẹ lọ́jú pé ó máa gbọ́ àdúrà rẹ, á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́.—1 Pétérù 3:12.
^ Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.
“Èmi àti aláwọ̀ funfun kankan ò jọ jókòó pa pọ̀ lálàáfíà rí . . . Ní báyìí, mo ti wà lára ojúlówó ẹgbẹ́ ará kárí ayé.”—TITUS