4 | Ìmọ̀ràn Tó Wúlò Wà Nínú Bíbélì
BÍBÉLÌ SỌ PÉ: ‘Gbogbo Ìwé Mímọ́ ló wúlò.’—2 TÍMÓTÌ 3:16.
Ohun Tó Túmọ̀ Sí
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kì í ṣe ìwé ìṣègùn, ìmọ̀ràn inú ẹ̀ wúlò gan-an. Àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì lè ran ẹni tó ní àárẹ̀ ọpọlọ lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ mélòó kan.
Àǹfààní Tó Máa Ṣe Ẹ́
“Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn, àmọ́ àwọn tó ń ṣàìsàn nílò rẹ.”—MÁTÍÙ 9:12.
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá ní àìlera, ó lè gba pé ká lọ gba ìtọ́jú. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ní àárẹ̀ ọpọlọ ló sọ pé ara tu àwọn nígbà táwọn ṣe ìwádìí nípa ohun tó ń ṣe àwọn lọ́dọ̀ àwọn tó mọ̀ nípa ẹ̀ dáadáa, táwọn sì lọ gba ìtọ́jú tó yẹ lọ́dọ̀ àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́.
“Àǹfààní . . . wà nínú eré ìmárale.”—1 TÍMÓTÌ 4:8.
Àwọn nǹkan pàtàkì kan wà tó yẹ ká máa ṣe tá a bá fẹ́ kí ọpọlọ wa túbọ̀ jí pépé. Lára àwọn nǹkan náà ni pé ká máa ṣe eré ìmárale déédéé, ká máa jẹ àwọn oúnjẹ aṣaralóore, ká sì máa sùn dáadáa.
“Ọkàn tó ń yọ̀ jẹ́ oògùn tó dára fún ara, àmọ́ ẹ̀mí tí ìdààmú bá máa ń tánni lókun.”—ÒWE 17:22.
Tó o bá ń ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ń fini lọ́kàn balẹ̀, tó o sì láwọn àfojúsùn tí ò kọjá agbára ẹ, ìyẹn á jẹ́ kó o máa láyọ̀. Tínú ẹ bá ń dùn, tó o sì gbà pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, ọkàn ẹ á balẹ̀, wàá sì lè fara da àìlera ọpọlọ ẹ.
“Ọgbọ́n wà lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n mọ̀wọ̀n ara wọn.”—Nígbà míì agbára ẹ lè má gbé gbogbo nǹkan tó o fẹ́ ṣe, torí náà jẹ́ káwọn ẹlòmíì ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ó ṣeé ṣe káwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ẹbí ẹ fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́, àmọ́ wọ́n lè má mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Torí náà, á dáa kó o jẹ́ kí wọ́n mọ ọ̀nà tí wọ́n lè gbà ràn ẹ́ lọ́wọ́. Má retí pé kí wọ́n ṣe ohun tó ju agbára wọn lọ, kó o sì máa dúpẹ́ gbogbo oore tí wọ́n bá ṣe fún ẹ.
Bíbélì Máa Ń Ran Àwọn Tó Ní Àárẹ̀ Ọpọlọ Lọ́wọ́
“Nígbà tí mo kíyè sí i pé nǹkan ń ṣe mí, mo lọ rí dókítà. Wọ́n yẹ̀ mí wò, wọ́n sì sọ ohun tó ń ṣe mí. Ní báyìí tí mo ti mọ ohun tó ń ṣe mí, ìyẹn jẹ́ kí n lè ṣèwádìí kí n lè mọ irú ìtọ́jú tó yẹ kí n gbà kí ara mi lè balẹ̀.”—Nicole, a tó ní àìlera ọpọlọ tí wọ́n ń pè ní bipolar disorder.
“Bí èmi àti ìyàwó mi ṣe máa ń ka Bíbélì láràárọ̀ ti jẹ́ kí n lè máa ronú nípa àwọn ohun tó dáa tó sì ń gbéni ró. Láwọn ìgbà tí mo bá sì ní ìdààmú ọkàn, mo sábà máa ń rántí ẹsẹ Bíbélì kan tí mo kà, ìyẹn sì máa ń tù mí nínú.”—Peter, tó máa ń ní ìdààmú ọkàn tó lágbára.
“Kò rọrùn fún mi láti sọ ìṣòro mi fún àwọn míì torí mo gbà pé ohun ìtìjú ni. Àmọ́ mo ní ọ̀rẹ́ tọ́rọ̀ mí yé tó sì lójú àánú. Ó máa ń dúró tì mí, ó sì máa ń jẹ́ kára tù mí.”—Ji-yoo, tí àárẹ̀ ọpọlọ máa ń mú kó jẹun lájẹjù.
“Bíbélì ti jẹ́ kí n rí i pé tí mo bá ń ṣiṣẹ́, ó yẹ kí n máa wáyè láti sinmi. Àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú ẹ̀ ti jẹ́ kí n lè fara da àárẹ̀ ọpọlọ tí mo ní.”—Timothy, tó ní àárẹ̀ ọpọlọ tí kì í jẹ́ kí ara èèyàn balẹ̀, ìyẹn obsessive-compulsive disorder.
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.