Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Rẹ
INÚ Bíbélì la ti lè rí ìtọ́sọ́nà tó dáa jù lọ torí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló ti wá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kì í ṣe ìwé ìṣègùn, ó lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá wà nínú ìṣòro tó lágbára, tí èròkerò bá ń wá sí wa lọ́kàn, tá a bá ní ẹ̀dùn ọkàn, àárẹ̀ ara tàbí ti ọpọlọ.
Ohun kan tó fini lọ́kàn balẹ̀ jù lọ ni pé, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀rọ̀ wa yé Jèhófà Ọlọ́run a Ẹlẹ́dàá wa, ó sì mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára wa ju ẹnikẹ́ni míì lọ. Ó máa ń wù ú gan-an láti ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro. Bí àpẹẹrẹ, wo àwọn ẹsẹ Bíbélì méjì tó ń tuni nínú yìí:
“Jèhófà wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn; ó ń gba àwọn tí àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn là.”—SÁÀMÙ 34:18.
“Èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tó ń sọ fún ọ pé, ‘Má bẹ̀rù. Màá ràn ọ́ lọ́wọ́.’” —ÀÌSÁYÀ 41:13.
Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ní àárẹ̀ ọpọlọ tó ń fa ìdààmú ọkàn tàbí ìsoríkọ́? Bá a ṣe máa rí i nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó wà níwájú, ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni Jèhófà ń gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa.
a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.