Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ibo Lo Ti Lè Rí Ìmọ̀ràn Tó Ṣeé Gbára Lé Lónìí?

Ibo Lo Ti Lè Rí Ìmọ̀ràn Tó Ṣeé Gbára Lé Lónìí?

Láyé tá a wà yìí, àwọn èèyàn lè gbà pé ohun kan dáa lónìí, àmọ́ kí wọ́n tún sọ pé kò dáa mọ́ lọ́la. Torí náà, o lè máa bi ara ẹ pé: Kí ló máa ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe àwọn nǹkan tó dáa, tó sì máa múnú mi dùn? Kí ló máa jẹ́ kó dá mi lójú pé ohun tí mo gbà pé ó dáa báyìí ò ní pa dà di ohun tí kò dáa tó bá yá?

Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe àwọn nǹkan tó dáa, tó ò sì ní kábàámọ̀ tó bá yá. Kí nìdí tó o fi lè gbára lé Bíbélì? Ìdí ni pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa ni Bíbélì ti wá. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, Ọlọ́run mọ ohun tó lè jẹ́ ká láyọ̀ àtohun táá fi wá lọ́kàn balẹ̀.

“Ó ti sọ ohun tó dára fún ọ.”—Míkà 6:8.

Tá a bá ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì, a ò ní kábàámọ̀ láé. Ó “ṣeé gbára lé ní gbogbo ìgbà, ní báyìí àti títí láé.”—Sáàmù 111:8.

A rọ̀ ẹ́ pé kó o fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó o lè mọ bí Bíbélì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ nínú ayé tó jẹ́ pé ojoojúmọ́ ni nǹkan ń yí pa dà yìí.