Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀

Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀

Báwo lo ṣe lè mọ ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé ohun tọ́kàn wọn bá ṣáà ti ní kí wọ́n ṣe ni wọ́n máa ń ṣe, àwọn kan sì wà tó jẹ́ pé ohun tójú wọn ti rí ló máa ń mú kí wọ́n mọ ohun tí wọ́n máa ṣe. Ní ti àwọn kan, ohun táwọn èèyàn bá sọ ni wọ́n máa ń tẹ̀ lé. Ìwọ ńkọ́? Kí ló máa ń jẹ́ kó o mọ̀ bóyá ohun tó o fẹ́ ṣe dáa àbí kò dáa? Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe àwọn ìpinnu táá ṣe ìwọ àti ìdílé ẹ láǹfààní lọ́jọ́ iwájú?