Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Lọ Jọ́sìn ní Ojúbọ?

Ṣé Ó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Lọ Jọ́sìn ní Ojúbọ?

LỌ́DỌỌDÚN, àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà máa ń rìnrìn àjò lọ síbi igbó kédárì kan ní àgbègbè Shima lórílẹ̀-èdè Japan. Ojúbọ ńlá kan tó wà ní ìlú Ise ni wọ́n máa ń lọ. Ó sì ti tó ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ọdún táwọn ẹlẹ́sìn Shinto ti ń jọ́sìn abo òrìṣà oòrùn tí wọ́n ń pè ní Amaterasu Omikami ní ojúbọ yìí. Tí wọ́n bá ti débẹ̀, wọ́n á kọ́kọ́ wẹ ara wọn mọ́ nípa fífọ ọwọ́ àti ẹnu wọn. Lẹ́yìn náà, wọ́n á dúró síwájú ilé òrìṣà náà, wọ́n á forí balẹ̀, wọ́n á máa pàtẹ́wọ́, wọ́n á sì máa gbàdúrà sí òrìṣà náà. * Àwọn ẹlẹ́sìn Shinto fàyè gba àwọn ọmọlẹ́yìn wọn láti máa ṣe ẹ̀sìn míì. Torí náà, àwọn ẹlẹ́sìn Búdà, àwọn Kristẹni kan àtàwọn ẹlẹ́sìn míì kò rí ohun tó burú nínú ṣíṣe àwọn ààtò ẹ̀sìn Shinto ní ojúbọ yìí.

Ọ̀pọ̀ àwọn ìsìn tó gbajúmọ̀ kárí ayé ló ní àwọn ojúbọ wọn, * ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló sì máa ń lọ síbẹ̀ lọ́dọọdún. Kódà, ní àwọn ìlú tí ẹ̀sìn Kristẹni ti gbilẹ̀, àìmọye ṣọ́ọ̀ṣì àti ojúbọ ni wọ́n kọ́ fún Jésù, Màríà àtàwọn ẹni mímọ́ míì. Wọ́n sì kọ́ àwọn ojúbọ míì sí àwọn ibi tí wọ́n gbà pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì inú Bíbélì ti wáyé tàbí ibi tí iṣẹ́ ìyanu kan ti ṣẹlẹ̀ tàbí ibi tí wọ́n kó àwọn nǹkan èlò ìsìn ayé àtijọ́ sí. Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń lọ gbàdúrà láwọn ojúbọ yìí torí wọ́n gbà gbọ́ pé Ọlọ́run máa gbọ́ àdúrà táwọn bá gbà níbẹ̀. Àwọn míì máa ń rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ mímọ́ tàbí ojúbọ láti fi hàn pé àwọn jẹ́ olùfọkànsìn Ọlọ́run.

Àwọn tó rìnrìn àjò lọ sí ojúbọ ńlá tó wà ní ìlú Ise lórílẹ̀-èdè Japan àti Grotto ti Massabielle tó wà ní ìlú Lourdes lórílẹ̀-èdè Faransé

Ṣé òótọ́ ni pé Ọlọ́run máa ń tètè gbọ́ àdúrà téèyàn bá gbà ní ojúbọ tàbí ilẹ̀ mímọ́? Ṣé torí pé ẹnì kan rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ mímọ́ ni Ọlọ́run fi máa kà á sí olùfọkànsìn? Àti pé, ṣé ó yẹ káwọn Kristẹni máa lọ jọ́sìn ní àwọn ilẹ̀ mímọ́ tàbí ojúbọ? Ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá ó tọ́ láti máa jọ́sìn láwọn ojúbọ. Bákan náà, ó máa jẹ́ ká mọ irú ìjọsìn tí inú Ọlọ́run dùn sí.

JỌ́SÌN NÍ “Ẹ̀MÍ ÀTI ÒTÍTỌ́”

Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé a gbọ́dọ̀ jọ́sìn ní “ẹ̀mí àti òtítọ́”?

Ọ̀rọ̀ tí Jésù bá obìnrin ará Samáríà kan sọ jẹ́ ká mọ irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìjọsìn ní àwọn ibi mímọ́ tàbí ojúbọ. Jésù ń rìnrìn àjò gba Samáríà kọjá, ó sì dúró láti sinmi níbi kànga kan nítòsí ìlú Síkárì. Ó wá bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú obìnrin kan tó wá fa omi nínú kànga náà. Bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ, obìnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn ìyàtọ̀ tó wà nínú bí àwọn Júù ṣe ń jọ́sìn àti bí àwọn ará Samáríà ṣe ń jọ́sìn. Obìnrin náà sọ pé: “Àwọn baba ńlá wa jọ́sìn ní òkè ńlá yìí; ṣùgbọ́n ẹ̀yin sọ pé Jerúsálẹ́mù ni ibi tí ó yẹ kí àwọn ènìyàn ti máa jọ́sìn.”—Jòhánù 4:5-9, 20.

Òkè Ńlá Gérísímù tó wà ní nǹkan bí àádọ́ta [50] kìlómítà sí àríwá Jerúsálẹ́mù ni obìnrin náà ń tọ́ka sí. Ìgbà kan wà táwọn ará Samáríà kọ́ tẹ́ńpìlì sí orí òkè yìí, níbẹ̀ ni wọ́n ti máa ń ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá. Àmọ́, kàkà kí Jésù tẹnu mọ́ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìjọsìn àwọn Júù àti tàwọn ará Samáríà, ńṣe ló sọ fún obìnrin náà pé: “Gbà mí gbọ́, obìnrin yìí, wákàtí náà ń bọ̀ nígbà tí kì í ṣe ní òkè ńlá yìí tàbí ní Jerúsálẹ́mù ni ẹ ó ti máa jọ́sìn Baba.” (Jòhánù 4:21) Ó yani lẹ́nu pé ẹni tó jẹ́ Júù lè sọ irú ọ̀rọ̀ yìí. Kí nìdí tí ìjọsìn ní tẹ́ńpìlì Ọlọ́run tó wà ní Jerúsálẹ́mù fi máa dópin?

Jésù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, ìsinsìnyí sì ni, nígbà tí àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́, nítorí pé, ní tòótọ́, irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá láti máa jọ́sìn òun.” (Jòhánù 4:23) Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún làwọn Júù fi gbà pé tẹ́ńpìlì rèǹtèrente tó wà ní Jerúsálẹ́mù ni ojúkò ìjọsìn wọn. Wọ́n sì máa ń rìnrìn àjò lọ síbẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹta lọ́dún láti rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run wọn. (Ẹ́kísódù 23:14-17) Àmọ́, Jésù sọ pé gbogbo èyí máa dópin àti pé “àwọn olùjọsìn tòótọ́” yóò máa jọ́sìn “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.”

Ilé tí wọ́n dìídì kọ́ síbi pàtó kan ni tẹ́ńpìlì àwọn Júù. Àmọ́, ẹ̀mí àti òtítọ́ kì í ṣe ohun tó ṣeé gbé kalẹ̀, kò sì sí ní ibi pàtó kan. Ohun tí Jésù ń sọ ni pé, kì í ṣe ibi pàtó kan ló máa jẹ́ ojúkò ìjọsìn àwọn Kristẹni tòótọ́, kò ní jẹ Òkè Ńlá Gérísímù tàbí tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù tàbí ibikíbi míì.

Nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù bá obìnrin ará Samáríà náà sọ, Jésù sọ pé “wákàtí” tí ìyípadà yìí máa ṣẹlẹ̀ “ń bọ̀.” Ìgbà wo ló máa jẹ́? Wákàtí náà dé nígbà tí Jésù tipasẹ̀ ikú rẹ̀ fòpin sí ìsìn àwọn Júù tí wọ́n gbé karí Òfin Mósè. (Róòmù 10:4) Jésù tún sọ pé: ‘Ìsinsìnyí ni wákàtí náà.’ Kí nìdí? Torí pé òun ni Mèsáyà, ó sì ti ń kó àwọn ọmọlẹ́yìn jọ. Àwọn wọ̀nyí máa ṣègbọràn sí àṣẹ tó pa lẹ́yìn náà pé: “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí, àwọn tí ń jọ́sìn rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:24) Kí wá ló túmọ̀ sí láti jọ́sìn Ọlọ́run ní ẹ̀mí àti òtítọ́?

Nígbà tí Jésù sọ pé ká máa jọ́sìn ní ẹ̀mí, ohun tó ní lọ́kàn ni pé kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wa. Lára ohun tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń ṣe fún wa ni pé, ó máa ń jẹ́ ká lóye Ìwé Mímọ́. (1 Kọ́ríńtì 2:9-12) Òtítọ́ tí Jésù sì ń sọ túmọ̀ sí níní ìmọ̀ tó péye tàbí òye tó tọ́ nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì. Torí náà, kì í ṣe ibi pàtó tá a ti jọ́sìn ló máa jẹ́ kí inú Ọlọ́run dùn sí ìjọsìn wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, inú Ọlọ́run máa dùn sí ìjọsìn wa tí ìjọsìn náà bá bá ohun tó wà nínú Bíbélì mu, tí ẹ̀mí Ọlọ́run sì ń darí wa.

OJÚ TÓ YẸ KÁWỌN KRISTẸNI FI WO JÍJỌ́SÌN NÍ OJÚBỌ

Ǹjẹ́ ó yẹ káwọn Kristẹni máa rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ mímọ́ tàbí kí wọ́n máa jọ́sìn ní ojúbọ? Tá a bá ronú jinlẹ̀ lórí ohun tí Jésù sọ nípa jíjọ́sìn Ọlọ́run ní ẹ̀mí àti òtítọ́, a máa rí i pé ìjọsìn tá a bá sẹ ní ilẹ̀ mímọ́ tàbí ojúbọ èyíkéyìí kò nítumọ̀ kankan sí Bàbá wa ọ̀run. Bákan náà, Bíbélì sọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo lílo ère nínú ìjọsìn. Ó sọ pé: “Ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà.” Ó sì tún sọ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn òrìṣà.” (1 Kọ́ríńtì 10:14; 1 Jòhánù 5:21) Fún ìdí yìí, àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í jọ́sìn ní ibikíbi táwọn èèyàn kà sí ibi mímọ́ tàbí ibi tó ń gbé ìbọ̀rìṣà lárugẹ.

Ṣùgbọ́n èyí kò túmọ̀ sí pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dẹ́bi fún gbígbàdúrà, kíkẹ́kọ̀ọ́ tàbí ṣíṣàṣàrò níbi kan tá a yàn láàyò. Ibi ìpàdé tó bojú mu máa tuni lára téèyàn bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. Kò sì sí ohun tó burú tá a bá kọ ọ̀rọ̀ sára sàréè ẹni tó kú. Èyí lè jẹ́ ohun tá a fi ń rántí èèyàn wa tó kú. Àmọ́, tá a bá sọ ibẹ̀ di ojúbọ tàbí tá a gbé ère tá à ń júbà fún síbẹ̀, èyí ta ko ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ.

Torí náà, kò dìgbà tó o bá lọ gbàdúrà ní ibi mímọ́ kí Ọlọ́run tó gbọ́ àdúrà rẹ. Bákan náà, ti pé o rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ mímọ́ kò ní kí inú Ọlọ́run dùn sí ìjọsìn rẹ tàbí kó tìtorí rẹ̀ bù kún ẹ. Bíbélì sọ fún wa pé Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ “Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, kì í gbé inú àwọn tẹ́ńpìlì àfọwọ́kọ́.” Àmọ́, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run jìnnà sí wa. Kò sí ibi tá a wà tí a kò lè gbàdúrà sí Ọlọ́run torí pé “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.”—Ìṣe 17:24-27.

^ ìpínrọ̀ 2 Bí wọ́n ṣe ń ṣe ààtò ẹ̀sìn yìí lè yàtọ̀ láwọn ojúbọ Shinto míì.

^ ìpínrọ̀ 3 Wo àpótí náà “ Kí ni Ojúbọ?