Àwọn Awòràwọ̀ Àtàwọn Woṣẹ́woṣẹ́—Ṣé Wọ́n Lè Mọ Ọjọ́ Ọ̀la?
WÍWO ÌRÀWỌ̀
Woṣẹ́woṣẹ́ làwọn tó ń wo ìràwọ̀, ìgbàgbọ́ wọn sì ni pé òṣùpá, àwọn ìràwọ̀, àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì máa ń nípa lórí ìgbésí ayé ẹnì kọ̀ọ̀kan. Wọ́n gbà pé ipò tí òṣùpá, ìràwọ̀ tàbí àwọn pílánẹ́ẹ̀tì bá wà ní ọjọ́ tí wọ́n bí ẹnì kan máa nípa lórí ìgbésí ayé rẹ̀ àti bí ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ ṣe máa rí.
Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti máa ń wo ìràwọ̀, kódà ìwádìí jẹ́ ká mọ̀ pé orílẹ̀-èdè Bábílónì àtijọ́ ni ìràwọ̀ wíwò ti bẹ̀rẹ̀. Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 2012, wọ́n bi àwọn èèyàn pé kí lèrò wọn nípa wíwo ìràwọ̀, púpọ̀ nínú àwọn tí wọ́n bi léèrè gbà pé “ara ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì” ni wíwo ìràwọ́. Àmọ́ èrò wọn ò tọ̀nà. Ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀ rèé.
-
Kò sí agbára kankan tó ń jáde lára àwọn pílánẹ́ẹ̀tì tàbí ìràwọ̀ tó lè nípa lórí ìgbé ayé èèyàn, àwọn awòràwọ̀ kàn ń sọ tiwọn ni.
-
Kò sóhun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú ohun tí wọ́n máa ń sọ, àwọn nǹkan tó máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn níbi gbogbo náà ni.
-
Àwọn awòràwọ̀ gbà pé àwọn pílánẹ́ẹ̀tì ń yí ayé po, ìlànà yẹn ni wọ́n sì ń lò láti fi bá àwọn èèyàn woṣẹ́. Àmọ́ ìwádìí òde òní ti jẹ́ ká mọ̀ pé, oòrùn ni àwọn pílánẹ́ẹ̀tì ń yí po, kì í ṣe ayé.
-
Tí awòràwọ̀ kan bá woṣẹ́ fún ẹnì kan, tẹ́ni náà bá tún lọ bá awòràwọ̀ míì, ọ̀tọ̀ lohun tó máa gbọ́.
-
Ọ̀nà méjìlá tí wọ́n pè ní àmì zodiac làwọn awòràwọ̀ pín gbogbo èèyàn sí, ibi tí ìràwọ̀ bá wà lójú sánmà lọ́jọ́ tí wọ́n bá bí ẹnì kan ni wọ́n á fi mọ àmì tó jẹ́ tiẹ̀. Àmọ́ torí ayé ò dúró sójú kan, déètì àti gbogbo àwọn àmì yẹn ò bára mu mọ́.
Wọ́n gbà pé àwọn àmì zodiac máa jẹ́ káwọn mọ ìwà tẹ́nì kan á máa hù. Ká má tan ara wa jẹ, àwọn tí wọ́n bí lọ́jọ́ kan náà kì í hùwà bákan náà, kò sẹ́ni tó lè fi ọjọ́ ìbí ẹnì kan pinnu irú ìwà tẹ́ni náà á máa hù. Táwọn awòràwọ̀ bá gbọ́ ọjọ́ tí wọ́n bí ẹnì kan, láì tiẹ̀ rí ẹni náà, wọ́n máa sọ pé irú ìwà báyìí lẹni náà á máa hù, wọ́n gbàgbé pé ìwà èèyàn kì í dọ́gba. Ṣe lọ̀rọ̀ wọn dà bí ẹni tó ń dájọ́ láìgbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ẹnì kan.
WÍWOṢẸ́
Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn woṣẹ́woṣẹ́. Àwọn woṣẹ́woṣẹ́ máa ń wá àmì nínú ìfun ẹranko àti tèèyàn, àwọn kan máa ń lo oríṣiríṣi ewé, àwọn míì máa ń lo adìyẹ, wọ́n á máa wo bó ṣe ń jẹun. Lóde òní, wọ́n máa ń lo káàdì, awẹ́ obì, owó ẹyọ, omi, iyanrìn, èkùrọ́, àwo ribiti, àtẹ́lẹwọ́ àtàwọn nǹkan míì láti fi wo bí ọjọ́ ọ̀la ẹnì kan ṣe máa rí. Àmọ́ ṣé lóòótọ́ làwọn woṣẹ́wosẹ́ lè sọ bí ọjọ́ ọ̀la ṣe máa rí? Rárá, èèyàn ò lè gbẹ́kẹ̀ lé ohun tí wọ́n bá sọ. Ẹ jẹ́ ká wo ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀.
Ọ̀rọ̀ wọn kì í dọ́gba. Oríṣiríṣi ọ̀nà làwọn woṣẹ́woṣẹ́ máa ń gbà woṣẹ́, ohun tí wọ́n máa ń sọ sì máa ń yàtọ̀ síra, kódà tí wọ́n bá lo ọ̀nà kan náà. Ohun tá à ń sọ ni pé tí ẹnì kan bá sọ fún woṣẹ́woṣẹ́ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ pé kí wọ́n bá òun fi káàdì ìwoṣẹ́ wo bí ọjọ́ ọ̀la òun ṣe máa rí, torí pé káàdì ìwoṣẹ́ làwọn méjèèjì fẹ́ lò, ó yẹ kí ohun tí wọ́n máa sọ bára mu, àmọ́ kì í rí bẹ́ẹ̀.
Àwọn èèyàn ti ń ṣiyèméjì nípa àwọn woṣẹ́woṣẹ́. Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé, ńṣe ni wọ́n kàn ń fi káàdì àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n ń lò tan àwọn èèyàn jẹ. Ohun tí wọ́n máa ń ṣe ni pé, wọ́n máa fara balẹ̀ wo bí ẹnì kan ń ṣe ń ṣe, ìyẹn ní wọ́n fi máa mọ ohun tí wọ́n máa sọ fún un. Ohun táwọn woṣẹ́woṣẹ́ tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ máa ń ṣe ni pé, wọ́n máa ń kíyè sí ẹni tí wọ́n fẹ́ woṣẹ́ fún, wọ́n á bi í láwọn ìbéèrè, wọ́n á sì fara balẹ̀ tẹ́tí sí i. Ìyẹn á mú kí wọ́n mọ àwọn nǹkan kan nípa ẹni náà. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n á sọ nǹkan kan fún ẹni tí wọ́n ń woṣẹ́ fún, ẹni náà á sì rò pé agbára abàmì ló jẹ́ kó mọ àwọn nǹkan yẹn. Owó ńlá làwọn woṣẹ́woṣẹ́ sì máa ń gbà lọ́wọ́ àwọn tó bá wá sọ́dọ̀ wọn.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Ohun táwọn awòràwọ̀ àtàwọn woṣẹ́woṣẹ́ ń dọ́gbọ́n sọ ni pé, gbogbo èèyàn ló ti ní kádàrá tiẹ̀. Àmọ́ ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwa fúnra wa la máa yan ohun tó wù wá láti fi ayé wa ṣe. Ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé ohun tá a bá yàn ló máa pinnu bí ọjọ́ ọ̀la wa ṣe má rí.—Jóṣúà 24:15.
Àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run tiẹ̀ tún ní ìdí pàtàkì tí wọn ò fi gbọ́dọ̀ máa lọ sọ́dọ̀ àwọn awòràwọ̀ àtàwọn woṣẹ́woṣẹ́. Ìdí náà ni pé Ọlọ́run kórìíra nǹkan bẹ́ẹ̀. Ó sọ nínú Bíbélì pé: “Kí a má ṣe rí láàárín rẹ ẹnikẹ́ni . . . tí ń woṣẹ́, pidánpidán kan tàbí ẹnikẹ́ni tí ń wá àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí oníṣẹ́ oṣó, tàbí ẹni tí ń fi èèdì di àwọn ẹlòmíràn tàbí ẹnikẹ́ni tí ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò tàbí olùsàsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí ẹnikẹ́ni tí ń ṣèwádìí lọ́dọ̀ òkú. Nítorí gbogbo àwọn tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.” a—Diutarónómì 18:10-12.
a Orúkọ “Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 83:18.