Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀
TÍ ÀJÁLÙ bá ti bá ẹ rí, wàá mọ̀ pé ohun tí ojú àwọn tó ṣẹlẹ̀ sí máa ń rí kì í ṣe kékeré. Ìdààmú ńlá máa ń bá wọn, á máa ṣe wọ́n bíi pé wọ́n ń lálàá, àníyàn máa ń gbà wọ́n lọ́kàn, wọn kì í mọ ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe, kódà àwọn míì máa ń ṣe ìrànrán lójú oorun. Nǹkan máa ń sú ọ̀pọ̀ wọn, ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn sì lè mú wọn débi pé wọ́n á gbà pé kò sí ìrètí kankan fún àwọn mọ́.
Tí àjálù bá ti bá ẹ rí tó sì mú kó o pàdánù gbogbo ohun tó o ní, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ó ti tán fún ẹ. O tiẹ̀ lè máa rò pé ìgbésí ayé rẹ ò já mọ́ nǹkan kan. Àmọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ayé rẹ ṣì máa dùn àti pé ọ̀la ń bọ̀ wá dára.
Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ FINI LỌ́KÀN BALẸ̀ PÉ Ọ̀LA Ń BỌ̀ WÁ DÁRA
Oníwàásù 7:8 sọ pé: “Òpin nǹkan sàn ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ.” Lẹ́yìn tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ó lè dà bíi pé kò sí ìrètí kankan mọ́. Àmọ́ bó o ṣe ń sapá láti mú ìgbésí ayé rẹ pa dà bọ̀ sípò, nǹkan á bẹ̀rẹ̀ sí í sunwọ̀n sí i.
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àkókò kan ń bọ̀ tí ‘a ò ní gbọ́ igbe ẹkún tàbí igbe ìdààmú mọ́.’ (Àìsáyà 65:19) Èyí máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí ayé yìí bá pa dà di Párádísè lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Sáàmù 37:11, 29) Àjálù á di ohun ìgbàgbé. Kódà, gbogbo ọgbẹ́ ọkàn àti wàhálà tí ìṣẹ̀lẹ̀ èyíkéyìí bá ti fà máa di ohun ìgbàgbé pátápátá, torí pé Ọlọ́run Olódùmarè ti ṣèlérí pé: “Àwọn ohun àtijọ́ ò ní wá sí ìrántí, wọn ò sì ní wá sí ọkàn.”—Àìsáyà 65:17.
Rò ó wò ná: Ẹlẹ́dàá wa ti ṣètò láti ‘fún ẹ ní ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan,’ ìyẹn ìgbé ayé ìfọ̀kànbalẹ̀ lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Jeremáyà 29:11) Ṣé òtítọ́ inú Bíbélì lè fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀ pé ayé rẹ ṣì máa dùn àti pé ọ̀la ń bọ̀ wá dára? Sally tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí sọ pé: “Tó o bá ń rán ara rẹ létí àwọn ohun àgbàyanu tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú, ó máa jẹ́ kó o lè gbọ́kàn kúrò nínú àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, wàá sì lè fara da ohun tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí.”
Jọ̀wọ́, gbìyànjú kó o kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa tó ṣe fún aráyé. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, láìka àwọn àjálù tó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ, wàá rí i pé ayé rẹ ṣì máa dùn, bó o ṣe ń retí àkókò tí kò ní sí àjálù mọ́. Ní báyìí, wàá rí àwọn ìlànà Bíbélì táá jẹ́ kó o lè fara da àwọn ìṣòro to máa ń wáyé lẹ́yìn tí àjálù bá ṣẹlẹ̀. Jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.