Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe?

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe?

Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé. Ó mọ̀ pé Ọlọ́run ò fẹ́ káwọn nǹkan burúkú máa ṣẹlẹ̀ láyé àti pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè tún gbogbo ohun tó ti bà jẹ́ ṣe. Kí ni Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe?

OHUN TÍ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN TI ṢE

Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, a sọ̀rọ̀ nípa àmì tí Jésù fún wa. Àmì yẹn ló máa jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ti gbé Ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ lọ́run, ó sì ti fi Jésù Kristi jẹ Ọba.

Bíbélì sọ pé nígbà tí Jésù bá gba agbára Ìjọba, ó máa lé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù kúrò lọ́run. Látìgbà yẹn, ayé nìkan ni Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù ti lè máa ṣọṣẹ́, ìyẹn sì jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó fà á tí nǹkan fi burú gan-an láyé látọdún 1914.​—Ìfihàn 12:​7, 9.

Láìka bí ayé ṣe ń bà jẹ́ sí, Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run ṣì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kárí ayé. Iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń lọ kárí ayé tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ ló ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ ìlànà Bíbélì, kí wọ́n sì máa fi sílò nígbèésí ayé wọn. (Àìsáyà 2:​2-4) Àìmọye èèyàn ló ti kọ́ bí wọn ò ṣe ní máa ṣe iṣẹ́ àṣejù nítorí àtidi olówó, wọ́n ti kọ́ bí wọ́n ṣe lè mú kí ìdílé wọn tòrò, wọ́n sì ti kọ́ bí wọ́n ṣe lè gbádùn ohun ìní tara láì sọ ọ́ di ohun tó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé wọn. Ohun táwọn èèyàn ń kọ́ yìí ń ṣe wọ́n láǹfààní báyìí, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n ní ìwà tí Ọlọ́run fẹ́ káwọn tó máa wà lábẹ́ Ìjọba òun ní.

KÍ LÓ KÀN TÍ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN MÁA ṢE?

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù ti ń ṣàkóso lọ́run, ìjọba èèyàn ló ṣì ń ṣàkóso ayé. Àmọ́, Ọlọ́run ti sọ fún Jésù pé: “Máa ṣẹ́gun lọ láàárín àwọn ọ̀tá rẹ.” (Sáàmù 110:2) Láìpẹ́, Jésù máa pa gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ run pátápátá, á sì mú ìtura bá gbogbo àwọn tó ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run tọkàntọkàn.

Ní àkókò yẹn, ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe rèé:

  • Ó máa pa ẹ̀sìn èké run. Gbogbo ẹ̀sìn tó ti ń fi ọ̀pọ̀ ọdún kọ́ àwọn èèyàn ní irọ́ nípa Ọlọ́run, tó sì ń mú ayé nira fún wọn, máa pa run. Bíbélì fi ẹ̀sìn èké wé aṣẹ́wó. Ó máa ya ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́nu gan-an tí ẹ̀sìn èké bá pa run.​—Ìfihàn 17:​15, 16.

  • Ó máa fòpin sí ìjọba èèyàn. Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo ìjọba èèyàn.​—Ìfihàn 19:​15, 17, 18.

  • Ó máa pa àwọn èèyàn burúkú run. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tí wọn ò jáwọ́ nínú ìwà burúkú, tí wọ́n sì kọ̀ láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run? “Ní ti àwọn ẹni burúkú, a ó pa wọ́n run kúrò ní ayé.”​—Òwe 2:22.

  • Ó máa pa Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù run. Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ò ní lè “ṣi àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà mọ́.”​—Ìfihàn 20:​3, 10.

Àǹfààní wo ni èyí máa ṣe àwọn tó fi ara wọn sábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run?

OHUN TÍ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN MÁA ṢE FÚN ARÁYÉ

Nígbà tí Jésù Ọba bá ń ṣàkóso láti ọ̀run, ó máa ṣe ohun ńlá táwọn èèyàn tó jẹ́ alákòóso ò tíì ṣe rí. Àwọn tó máa bá a ṣàkóso jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tó wá láti ara aráyé. (Ìfihàn 5:​9, 10; 14:​1, 3) Ó máa rí i dájú pé ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ láyé. Kí ni Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fáwọn tó máa wà láyé?

  • Ó máa mú àìsàn àti ikú kúrò. “Kò sí ẹnì kankan tó ń gbé ibẹ̀ tó máa sọ pé: ‘Ara mi ò yá.’ ” Bákan náà, “ikú ò ní sí mọ́.”​—Àìsáyà 33:24; Ìfihàn 21:4.

  • Ó máa mú kí àlàáfíà àti ààbò tòótọ́ wà. ‘Àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ máa pọ̀ gan-an,’ àti pé “kálukú wọn máa jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.”​—Àìsáyà 54:13; Míkà 4:4.

  • Àwọn èèyàn á gbádùn iṣẹ́ wọn. “Àwọn àyànfẹ́ mi sì máa gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ wọn dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Wọn ò ní ṣiṣẹ́ kára lásán.”​—Àìsáyà 65:​22, 23.

  • Kò ní sí ohun tó ń ba àyíká jẹ́ mọ́. “Aginjù àti ilẹ̀ tí kò lómi máa yọ̀, aṣálẹ̀ tó tẹ́jú máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ó sì máa yọ ìtànná bíi sáfúrónì.”​—Àìsáyà 35:1.

  • Ó máa kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n wà láàyè títí láé. “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, pé kí wọ́n wá mọ ìwọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo àti Jésù Kristi, ẹni tí o rán.”​—Jòhánù 17:3.

Ọlọ́run fẹ́ kó o gbádùn àwọn ìbùkún yẹn. (Àìsáyà 48:18) Àpilẹ̀kọ tó kàn máa ṣàlàyé ohun tó yẹ kó o ṣe báyìí kó o lè gbádùn ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀.