Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ayé Tuntun Là Ń Fẹ́!

Ayé Tuntun Là Ń Fẹ́!

Ọ̀gbẹ́ni António Guterres, tó jẹ́ akọ̀wé àgbà fún Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé sọ pé: “Ayé yìí ti dojú rú gan-an.” Ṣé o gbà pé òótọ́ lohun tí ọ̀gbẹ́ni yẹn sọ?

Àwọn nǹkan tó ń bani lọ́kàn jẹ́ là ń gbọ́ nínú ìròyìn

  • Àìsàn àti àjàkálẹ̀ àrùn

  • Ìmìtìtì ilẹ̀, omíyalé àtàwọn àjálù míì

  • Ipò òṣì àti ebi

  • Bíba àyíká jẹ́ àti kí ayé máa gbóná ju bó ṣe yẹ lọ

  • Ìwà ọ̀daràn àti ìwà ìbàjẹ́ àwọn aláṣẹ

  • Ogun

Ó ti wá hàn kedere báyìí pé, ayé tuntun là ń fẹ́. Àwọn nǹkan tí aráyé ń fẹ́ ni

  • Ara tó jí pépé

  • Ààbò àti ìfọ̀kànbalẹ̀ fún gbogbo èèyàn

  • Oúnjẹ tó pọ̀ rẹpẹtẹ

  • Àyíká tó tura

  • Ìdájọ́ òdodo fún gbogbo èèyàn

  • Àlàáfíà kárí ayé

Kí ni ayé tuntun?

Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ayé tá a wà yìí?

Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ máa gbénú ayé tuntun?

Nínú ìwé yìí, Bíbélì máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí àtàwọn ìbéèrè míì bí irú èyí lọ́nà tó ń fini lọ́kàn balẹ̀.