Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN | RÈBÉKÀ

“Mo Múra Tán Láti Lọ”

“Mo Múra Tán Láti Lọ”

RÈBÉKÀ ń wo ilẹ̀ tó tẹ́jú lọ salalu lọ́ọ̀ọ́kán lórí ràkúnmí tó jókòó sí. Bí ràkúnmí náà ṣe ń rìn gbà-gó-gbà-gó ti bẹ̀rẹ̀ sí í mọ́ ọn lára báyìí, torí pé ó ti tó ọ̀sẹ̀ mélòó kan tí wọ́n ti wà lẹ́nu ìrìn àjò náà. Wọ́n ti jìnnà gan-an sí ìlú Háránì, níbi tó dàgbà sí. Ó sì ṣeé ṣe kó máà tún fojú kan àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ mọ́. Ó dájú pé ọ̀pọ̀ nǹkan láá máa jà gùdù lọ́kàn rẹ̀, àgàgà ní báyìí tí wọ́n ti sún mọ́ ibi tí wọ́n ń lọ.

Wọ́n ti rìnrìn àjò gba ilẹ̀ Kénáánì kọjá, ní báyìí wọ́n ti dé àgbègbè Négébù tó jẹ́ aṣálẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 24:62) Ó ṣeé ṣe kí Rèbékà rí àwọn àgùntàn. Ilẹ̀ yìí kò jọ èyí tí wọ́n lè fi dáko, torí pé aṣálẹ̀ ni, àmọ́ koríko wà dáadáa táwọn ẹran ọ̀sìn lè jẹ. Bàbá àgbàlagbà tó ń tẹ̀ lé lọ mọ àgbègbè yìí dáadáa. Ara rẹ̀ sì ti wà lọ́nà láti ròyìn fún ọ̀gá rẹ̀ pé Rèbékà ti gbà láti di ìyàwó Ísákì. Rèbékà lè máa rò ó lọ́kàn pé, báwo ni nǹkan ṣe máa rí fún òun níbí yìí. Irú èèyàn wo ni Ísákì ẹni tóun máa fẹ́? Wọn ò kúkú fojú kanra rí! Ṣé Ísákì máa nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ tó bá rí i, ṣé òun náà sì máa nífẹ̀ẹ́ Ísákì?

Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa ń fúnra rẹ̀ yan ẹni tó máa fẹ́. Àwọn ibòmíì sì wà tó jẹ́ pé àwọn òbí ló máa ń yan ẹni tí ọmọ wọn máa fẹ́. Ọ̀nà yòówù kí wọ́n máa gbà ṣe é ládùúgbò rẹ, wàá gbà pé Rèbékà kò mọ ohun tó lè gbẹ̀yìn ìpinnu rẹ̀. Èyí fi hàn pé obìnrin tó ní ìgboyà àti ìgbàgbọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni. Àwa náà nílò ìgboyà àti ìgbàgbọ́ ká lè kojú àwọn àyípadà tó lè dé bá wa nígbèésí ayé. Rèbékà tún ní àwọn ìwà rere míì tó ṣọ̀wọ́n tó túbọ̀ mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára.

“ÀWỌN RÀKÚNMÍ RẸ NI ÈMI YÓÒ TÚN FA OMI FÚN”

Wẹ́rẹ́ báyìí ni àyípadà ńlá tó ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé Rèbékà bẹ̀rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú ìlú Háránì tàbí agbègbè rẹ̀ ló dàgbà sí, ìlú yìí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí ilẹ̀ Mesopotámíà. Àwọn òbí rẹ̀ yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń gbé nílùú Háránì torí pé òrìṣà Sínì làwọn èèyàn náà ń jọ́sìn. Àmọ́, Jèhófà Ọlọ́run làwọn òbí Rèbékà ń jọ́sìn.—Jẹ́nẹ́sísì 24:50.

Rèbékà rẹwà lọ́mọbìnrin, àmọ́ kì í ṣe ẹwà ojú lásán ló ní. Ó nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, kì í sì í ṣe oníṣekúṣe. Inú ìdílé tó rí jájẹ ni wọ́n bí i sí torí pé wọ́n láwọn ìránṣẹ́. Àmọ́, wọn ò kẹ́ Rèbékà bà jẹ́, wọ́n tọ́ ọ láti jẹ́ òṣìṣẹ́ kára. Bíi ti ọ̀pọ̀ obìnrin láyé ìgbà yẹn, Rèbékà ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ilé tó máa ń ṣe, lára ẹ̀ ni pípọn omi tí gbogbo ilé máa lò. Lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́, á gbé korobá omi sí èjìká, á sì kọrí sọ́nà odò.—Jẹ́nẹ́sísì 24:11, 15, 16.

Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan lẹ́yìn tó ti pọn omi kún korobá rẹ̀ tán, bàbá àgbàlagbà kan wá bá a. Bàbá náà sọ pé: “Jọ̀wọ́ fún mi ní òfèrè omi díẹ̀ láti inú ìṣà omi rẹ.” Ohun tí bàbá náà béèrè kò pọ̀ jù, ó sì béèrè tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Rèbékà rí i pé bàbá náà ti rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn. Kíá ló gbé korobá omi náà sọ̀ kalẹ̀ léjìká, ó sì fún bàbá náà ní omi tútù débi tí bàbá náà fi mu ún tẹ́rùn. Rèbékà kíyè sí i pé, kò sí omi nínú ọpọ́n ìmumi tí àwọn ràkúnmí mẹ́wàá tí bàbá náà kó wá lè mu. Àánú ṣe é bó ṣe rí i tí bàbá náà ń wo òun, ó sì wù ú láti ṣoore fún bàbá náà. Torí náà, ó sọ pé: “Àwọn ràkúnmí rẹ ni èmi yóò tún fa omi fún títí tí wọn yóò fi mu tẹ́rùn.”—Jẹ́nẹ́sísì 24:17-19.

Wàá rí i pé kì í ṣe pé Rèbékà kàn fẹ́ fún àwọn ràkúnmí náà lómi mu nìkan, àmọ́ ó máa fún wọn títí wọn yóò fi mu ún tẹ́rùn. Tí òùngbẹ bá gbẹ ràkúnmí dáadáa, ẹyọ kan lè mú tó gálọ̀nù omi mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25]. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ ṣe gbẹ àwọn ràkúnmí mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà, á jẹ́ pé iṣẹ́ ńlá ni Rèbékà fẹ́ ṣe. Àmọ́, ó jọ pé òùngbẹ kò fi bẹ́ẹ̀ gbẹ àwọn ràkúnmí náà lọ́jọ́ yẹn. * Àmọ́ ṣé Rèbékà mọ̀ bẹ́ẹ̀ kó tó sọ pé òun máa fún wọn lómi? Rárá o. Ńṣe ló wù ú látọkànwá pé kó ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti ṣaájò bàbá àgbàlagbà náà. Bàbá náà gbà pé kó fún wọn lómi. Ó sì ń wo Rèbékà bó ṣe ń lọ tó ń bọ̀, tó ń pọn omi, tó sì ń dà á sínú ọpọ́n ìmumi náà.—Jẹ́nẹ́sísì 24:20, 21.

Òṣìṣẹ́ kára ni Rèbékà, ó sì lẹ́mìí àlejò ṣíṣe

Àpẹẹrẹ Rèbékà kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan lónìí. Àkókò tí ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan gbòde kan là ń gbé. Bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn èèyàn ti di “olùfẹ́ ara wọn,” wọn ò lè yááfì nǹkan nítorí àǹfààní àwọn ẹlòmíì. (2 Tímótì 3:1-5) Àwọn Kristẹni tí kò bá fẹ́ jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Rèbékà, bí wọ́n ṣe ń ronú nípa bó ṣe ń lọ tó ń bọ̀ nídìí kànga náà.

Ó dájú pé Rèbékà máa kíyè sí i pé bàbá àgbàlagbà yẹn ń wo òun. Kì í ṣe pé bàbá náà ní èròkérò lọ́kàn ló ṣe ń wò ó, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń wò ó tìyanu-tìyanu, inú rẹ̀ sì ń dùn. Nígbà tí Rèbékà ṣe tán, bàbá náà fún un lẹ́bùn ohun ọ̀ṣọ́ iyebíye. Lẹ́yìn náà, ó wá béèrè pé: “Ọmọbìnrin ta ni ìwọ? Jọ̀wọ́, sọ fún mi. Yàrá ha wà ní ilé baba rẹ fún wa láti sùn mọ́jú bí?” Nígbà tí Rèbékà sọ ọmọ ẹni tó jẹ́ fún un, ayọ̀ bàbá náà túbọ̀ kún. Pẹ̀lú ara yíyá gágá ni ọmọbìnrin náà tún fi sọ pé: “Èérún pòròpórò àti oúnjẹ ẹran púpọ̀ wà lọ́dọ̀ wa, àyè tún wà láti sùn mọ́jú.” Oore ńlá lèyí jẹ́, torí pé àwọn míì wà pẹ̀lú bàbá àgbàlagbà náà. Rèbékà sí ṣíwájú wọn lọ sílé kó lè lọ sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ìyá rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 24:22-28, 32.

Ó ṣe kedere pé, ọmọ tó mọ aájò èèyàn ṣe ni Rèbékà. Èyí sì jẹ́ ìwà rere míì tí kò wọ́pọ̀ nínú ayé lónìí. Ó sì tún jẹ́ ìdí míì fún wa láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ọmọbìnrin olójú àánú yìí. Ó yẹ kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Ọlọ́run sún wa láti máa ṣaájò àwọn èèyàn. Jèhófà máa ń ṣoore fún wa torí pé ó lawọ́ sí gbogbo èèyàn, ó sì fẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ òun. Tá a bá ń ṣe aájò àwọn èèyàn tí kò lè san oore náà pa dà fún wa, inú Baba wa ọ̀run á dùn sí wa.—Mátíù 5:44-46; 1 Pétérù 4:9.

“ÌWỌ YÓÒ SÌ MÚ AYA FÚN ỌMỌKÙNRIN MI”

Ta ni bàbá àgbàlagbà tó wá síbi kànga náà? Ìránṣẹ́ Ábúráhámù ni. Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò sì ni Ábúráhámù àti bàbá-bàbá Rèbékà. Torí náà, tọwọ́tẹsẹ̀ ni Bẹ́túélì bàbá Rèbékà fi gba bàbá náà sílé. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Élíésérì ni orúkọ bàbá náà. * Àwọn tó gbà á lálejò fi oúnjẹ lọ̀ ọ́, àmọ́ ó kọ̀ láti jẹun. Ó sọ pé ó dìgbà tí òun bá sọ ohun tó gbé òun wá kí òun tó lè jẹun. (Jẹ́nẹ́sísì 24:31-33) A lè fojú inú yàwòrán bó ṣe ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ara yíyá gágá, torí ó ti rí i pé Jèhófà Ọlọ́run wà lẹ́yìn òun gbágbáágbá. Lọ́nà wo?

O lè fọkàn yàwòrán bí Élíésérì ṣe ń sọ ohun tó ṣẹlẹ̀, tí Bẹ́túélì tó jẹ́ bàbá Rèbékà àti Lábánì ẹ̀gbọ́n Rèbékà sì tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́. Ó sọ fún wọn pé Jèhófà ti bù kún Ábúráhámù gan-an nílẹ̀ Kénáánì àti pé Ábúráhámù àti Sárà ní ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ísákì, òun ló sì máa jogún gbogbo ohun tí wọ́n ní. Ábúráhámù sì ti fún ìránṣẹ́ rẹ̀ yìí ni iṣẹ́ pàtàkì kan, pé kó wá ìyàwó fún Ísákì láàárín àwọn ẹbí òun tó ń gbé ní Háránì.—Jẹ́nẹ́sísì 24:34-38.

Ábúráhámù mú kí Élíésérì búra fún òun pé kò ní fẹ́yàwó fún Ísákì láàárín àwọn ọmọbìnrin Kénáánì. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn ọmọ Kénáánì kò jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run, wọn ò sì ka Jèhófà sí. Ábúráhámù mọ̀ pé Jèhófà máa tó fìyà jẹ àwọn èèyàn yẹn torí ìwà ibi tó kún ọwọ́ wọn. Torí náà, Ábúráhámù kò fẹ́ kí Ísákì ọmọ rẹ̀ ní àjọṣe kankan pẹ̀lú wọn. Ó tún mọ̀ pé ọmọ òun máa kópa pàtàkì láti mú kí ohun tí Ọlọ́run ti pinnu ní ìmúṣẹ.—Jẹ́nẹ́sísì 15:16; 17:19; 24:2-4.

Élíésérì wá sọ fún àwọn tó gbà á lálejò pé òun gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run nígbà tí òun dé ibi kànga tó wà létí ìlú Háránì. Ó bẹ Jèhófà pé kó bá òun yan ọmọbìnrin fún Ísákì láti fi ṣaya. Lọ́nà wo? Élíésérì bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí ọmọbìnrin tó fẹ́ kí Ísákì fẹ́ wá síbi kànga náà. Tí òun bá sì ní kó fún òun lómi, kí ọmọbìnrin náà gbà láti fún òun, kó sì tún fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda láti fún àwọn ràkúnmí òun lómi pẹ̀lú. (Jẹ́nẹ́sísì 24:12-14) Ta sì lẹ́ni tó wá tó sì ṣe àwọn nǹkan yìí? Rèbékà ni! O lè fojú inú wo bó ṣe máa rí lára Rèbékà tó bá fetí kọ́ ohun tí Élíésérì ń sọ fún àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀!

Ohun tí Élíésérì sọ yìí wọ Bẹ́túélì àti Lábánì lọ́kàn gan-an. Ni wọ́n bá sọ pé: “Láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ni nǹkan yìí ti wá.” Gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn, wọ́n ṣàdéhùn lórí ọ̀ràn ìgbéyàwó náà, wọ́n sì gbà kí Rèbékà fẹ́ Ísákì. (Jẹ́nẹ́sísì 24:50-54) Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé wọn ò jẹ́ kí Rèbékà sọ tẹnu ẹ̀ ni?

Ní ọ̀sẹ̀ mélòó kan ṣáájú àkókò yìí, Élíésérì ti béèrè lọ́wọ́ Ábúráhámù pé: “Bí obìnrin náà kò bá ní bá mi wá ńkọ́?” Ábúráhámù dáhùn pé: ‘Ìwọ yóò bọ́ lọ́wọ́ ìbúra tó o ṣe fún mi.’ (Jẹ́nẹ́sísì 24:39, 41) Nílé Bẹ́túélì pàápàá, wọ́n ka èrò ọmọbìnrin náà sí pàtàkì. Inú Élíésérì dùn gan-an pé ohun tí òun bá wá yọrí sí rere, torí náà ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, ó béèrè bóyá òun lè máa mú Rèbékà lọ sí ìlú Kénáánì lọ́jọ́ yẹn. Àmọ́, àwọn mọ̀lẹ́bí ṣì fẹ́ kí Rèbékà dúró fún ọjọ́ mẹ́wàá sí i. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n pinnu láti pe ọ̀dọ́bìnrin náà, kí wọ́n sì wádìí lẹ́nu rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 24:57.

Ọ̀rọ̀ náà wá dà bíi ti àlejò tó dé oríta mẹ́ta tí kò mọ ibi tó máa yà sí fún Rèbékà. Kí ló máa sọ? Ṣé ó máa dọ́gbọ́n yẹ ìrìn àjò náà sílẹ̀ torí ó kíyè sí i pé bàbá òun àti ẹ̀gbọ́n òun kò tíì fẹ́ kí òun lọ? Àbí ó wò ó bí àǹfààní láti kópa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí Jèhófà lọ́wọ́ sí? Èsì tó fún wọn jẹ́ ká mọ bí àyípadà òjijì yìí ṣe rí lára rẹ̀. Ohun tó sọ ni pé: “Mo múra tán láti lọ.”—Jẹ́nẹ́sísì 24:58.

Ẹ ò rí i pé Rèbékà lẹ́mìí tó dáa! Lóde òní, ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣègbéyàwó lágbègbè rẹ lè yàtọ̀ sí èyí, àmọ́ a ṣì lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára Rèbékà. Kì í ṣe ohun tó nífẹ̀ẹ́ sí ló jẹ́ ẹ lọ́kàn jù lọ, bí kò ṣe ohun tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ fẹ́. Tó bá kan ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó lóde òní, ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló ṣì gbéṣẹ́ jù lọ. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wa ní ìmọ̀ràn lórí yíyan ẹni tá a máa fẹ́ àti bí àwa fúnra wa ṣe lè jẹ́ ọkọ tàbí aya rere. (2 Kọ́ríńtì 6:14, 15; Éfésù 5:28-33) Ó máa dáa tá a bá lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Rèbékà, ká sì ṣe nǹkan lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́.

“TA NI ỌKÙNRIN YẸN TÍ Ó WÀ LỌ́HÙN-ÚN?”

Àwọn ẹbí ṣàdúrà fún Rèbékà ọmọ wọn. Lẹ́yìn náà, òun àti Dèbórà tó ń tọ́jú rẹ̀ láti kékeré àtàwọn ìránṣẹ́bìnrin mélòó kan gbéra ìrìn àjò pẹ̀lú Élíésérì àtàwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ wá. (Jẹ́nẹ́sísì 24:59-61; 35:8) Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, wọ́n ti jìnnà sí ìlú Háránì. Ìrìn àjò náà kì í ṣe kékeré, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rin [800] kìlómítà, ó sì ṣeé ṣe kó gbà wọ́n tó ìrìn ọ̀sẹ̀ mẹ́ta gbáko. Kò jọ pé ìrìn àjò náà rọrùn. Lóòótọ́, ọjọ́ pẹ́ tí Rèbékà ti ń rí àwọn ràkúnmí, àmọ́ a ó lè fi gbogbo ẹnu sọ pé Rèbékà mọ ràkúnmí gùn dáadáa. Ìdí ni pé Bíbélì sọ pé iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn ni ìdílé wọn ń ṣe, wọn kì í ṣe oníṣòwò tó máa ń gún ràkúnmí lọ sí ìrìn àjò. (Jẹ́nẹ́sísì 29:10) Àwọn tí kò bá mọ ràkúnmí gùn dáadáa máa ń ṣàròyé pé kò rọrùn, kí wọ́n tiẹ̀ tó rìn jìnnà rárá.

Láìka gbogbo ìṣòro yìí sí, ibi tí Rèbékà ń lọ ló wà lọkàn rẹ̀, ó sì lè máa béèrè ọ̀pọ̀ nǹkan lọ́wọ́ Élíésérì nípa Ísákì àti ìdílé rẹ̀. Fojú inú wo bí bàbá àgbàlagbà yẹn ṣe ń bá a sọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe ń yáná lọ́wọ́ alẹ́, tó ń sọ ìlérí tí Jèhófà ṣe fún Ábúráhámù fún un. Ọlọ́run ṣèlérí pé látinú ìlà ìdílé Ábúráhámù ni ẹni tó máa bù kún ìran èèyàn yóò ti wá. Wo bí inú Rèbékà ṣe máa dùn tó nígbà tó gbọ́ pé ipasẹ̀ Ísákì tó máa tó di ọkọ òun ni Ọlọ́run máa gbà mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ àti pé òun náà máa kópa nínú rẹ̀!—Jẹ́nẹ́sísì 22:15-18.

Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tí Rèbékà fi hàn kò wọ́pọ̀

Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ọjọ́ tá a ṣàpèjúwe rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí wọlé dé wẹ́rẹ́. Ilẹ̀ sì ti ń ṣú nígbà tí wọ́n fi máa dé ilẹ̀ Négébù, Rèbékà sì tajú kán rí ọkùnrin kan tó ń rìn lórí pápá. Ó jọ pé ńṣe ni ọkùnrin náà ń ronú. Bíbélì sọ nípa Rèbékà pé: “Ó sì tọ sílẹ̀ láti orí ràkúnmí.” Kò tiẹ̀ dúró kí ràkúnmí náà bẹ̀rẹ̀ tó fi bọ́ sílẹ̀, ó sì béèrè lọ́wọ́ bàbá náà pé: “Ta ni ọkùnrin yẹn tí ó wà lọ́hùn-ún, tí ń rìn nínú pápá láti pàdé wa?” Nígbà tó gbọ́ pé Ísákì ni, ńṣe ló daṣọ borí rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 24:62-65) Kí nìdí? Kò sí àní-àní pé ohun tó ṣe yìí fi hàn pé ó bọ̀wọ̀ fún ẹni tó máa di ọkọ rẹ̀. Àwọn kan lè gbà pé irú ọ̀wọ̀ bẹ́ẹ̀ kò bóde mu mọ́. Àmọ́, tọkùnrin tobìnrin wa ló yẹ kó kẹ́kọ̀ọ́ nínú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ Rèbékà yìí, àbí èwo nínú wa ni kò nílò irú ìwà àtàtà yìí?

Ísákì tó jẹ́ ẹni ogójì [40] ọdún ṣì ń ṣọ̀fọ̀ Sárà ìyá rẹ̀, tó kú ní nǹkan bí ọdún mẹ́ta sẹ́yìn. Èyí jẹ́ ká rí i pé ọkùnrin náà jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́. Ẹ ò rí i pé ìbùkún ni obìnrin bíi Rèbékà máa jẹ́ fún irú ọkùnrin yìí, torí pé òṣìṣẹ́ kára ni, ó lẹ́mìí àlejò ṣíṣe, ó sì níwà ìrẹ̀lẹ̀! Ǹjẹ́ àwọn méjèèjì mọwọ́ ara wọn? Ohun tí Bíbélì sọ ni pé: “Ó sì kó sínú ìfẹ́ fún obìnrin náà.”—Jẹ́nẹ́sísì 24:67; 26:8.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti pẹ́ gan-an, síbẹ̀ ó rọrùn fún wa láti nífẹ̀ẹ́ Rèbékà. Ohun tó sì mú ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni pé ó ní ìgboyà, òṣìṣẹ́ kára àti ẹni tó lẹ́mìí ṣiṣẹ́ àlejò ni, ó sì tún níwà ìrẹ̀lẹ̀. Gbogbo wa pátá yálà a jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, ọmọdé tàbí àgbà, bóyá a ti ṣe ìgbéyàwó tàbí a kò tíì ṣe, ó máa dáa ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Rèbékà!

^ ìpínrọ̀ 10 Ó ti di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́. Ìtàn náà kò sì sọ pé Rèbékà wà níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀ wákàtí. Kò sì jọ pé àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ti sùn kó tó délé tàbí pé ẹnì kan wá wò ó kó lè mọ ohun tó fà á tó fi pẹ́.

^ ìpínrọ̀ 15 Ìtàn yìí kò dárúkọ Élíésérì, àmọ́ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ni Ábúráhámù rán ní iṣẹ́ yìí. Ṣáájú kí Ábúráhámù tó bímọ tó máa jogún rẹ̀, ìgbà kan wà tó gbèrò láti kó gbogbo ogún rẹ̀ fún Élíésérì. Èyí fi hàn pé òun ló dàgbà jù tó sì ṣe é fọkàn tán jù lọ lára àwọn ìránṣẹ́ Ábúráhámù. Bí Bíbélì sì ṣe ṣàpèjúwe ẹni tí Ábúráhámù rán níṣẹ́ yìí nìyẹn.—Jẹ́nẹ́sísì 15:2; 24:2-4.