Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bó O Ṣe Lè Gbádùn Ayé Rẹ Ní Báyìí

Bó O Ṣe Lè Gbádùn Ayé Rẹ Ní Báyìí

ÌGBÀ kan ń bọ̀ tí ayé máa dùn gan-an. Nígbà yẹn, kò ní sí àìsàn, ọjọ́ ogbó, àti ikú mọ́. Ìwọ náà sì lè wà lára àwọn táá máa gbé irú ìgbé ayé bẹ́ẹ̀! Àmọ́ ní báyìí, wàhálà àti ìdààmú pọ̀ nínú ayé yìí. Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí wàá fi lè máa gbádùn ayé rẹ ní báyìí? Bíbélì pèsè ìtọ́sọ́nà tó máa jẹ́ kó o láyọ̀ ní báyìí, tí ìgbésí ayé rẹ á sì dára. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro tá à ń dojú kọ àti bí Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́.

BÓ O ṢE LÈ NÍ ÌTẸ́LỌ́RÙN

Ìmọ̀ràn Bíbélì: “Ẹ yẹra fún ìfẹ́ owó nínú ìgbésí ayé yín, bí ẹ ṣe ń jẹ́ kí àwọn nǹkan tó wà báyìí tẹ́ yín lọ́rùn.”​Hébérù 13:5.

Lónìí, orísiríṣi ìpolówó ọjà ń jẹ́ káwọn èèyàn rò pé àwọn ohun kan jẹ́ kòṣeémáàní. Àmọ́, Bíbélì sọ pé a lè ‘jẹ́ kí àwọn nǹkan tó wà báyìí tẹ́ wa lọ́rùn.’ Báwo lá ṣe lè ṣe é?

Yẹra fún “ìfẹ́ owó.” Àwọn èèyàn ti ba ìlera wọn jẹ́, wọ́n ti pa ìdílé wọn tì, wọ́n ti pa ọ̀rẹ́ wọn tì, wọ́n sì ti sọ ìwa rere àti iyì ara wọn nù nítorí “ìfẹ́ owó.” (1 Tímótì 6:10) Àdánù ńlá gbáà nìyẹn! Àmọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn á wá ṣe kedere pé, owó “kì í tó ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀.”​—Oníwàásù 5:10.

Èèyàn ṣe pàtàkì ju àwọn nǹkan lọ. Lóòótọ́, àwọn nǹkan ìní wúlò. Àmọ́ àwọn nǹkan tówó lè rà kò lè nífẹ̀ẹ́ wa tàbí kí wọ́n mọyì wa, àwọn èèyàn nìkan ló lè ṣe bẹ́ẹ̀. Tá a bá ní “ọ̀rẹ́ tòótọ́,” ó máa jẹ́ kí ọkàn wa túbọ̀ balẹ̀.​—Òwe 17:17.

A MÁA GBÁDÙN AYÉ WA NÍ BÁYÌÍ TÁ A BÁ Ń TẸ̀ LÉ ÌTỌ́SỌ́NÀ BÍBÉLÌ

BÓ O ṢE LÈ FARA DA ÀÌLERA

Ìmọ̀ràn Bíbélì: “Ọkàn tó ń yọ̀ jẹ́ oògùn tó dára fún ara.”​Òwe 17:22.

Bí “oògùn tó dára” ṣe máa ń ṣe ara lóore, bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ ṣe máa ń jẹ́ kéèyàn fara da àìlera. Àmọ́, báwo la ṣe lè láyọ̀ tá a bá tiẹ̀ ní àìlera?

Máa dúpẹ́. Tó bá jẹ́ pé àwọn ìṣòro wa la máa ń rò ṣáá, ńṣe ló máa dà bíi pé a ò lè láyọ̀ mọ́ ní “gbogbo ọjọ́” ayé wa. (Òwe 15:15) Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì sọ pé ká “máa dúpẹ́.” (Kólósè 3:15) Jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa dúpẹ́ torí gbogbo ohun rere tó ò ń rí gbà, bó ti wù kó kéré tó. A máa ń gbádùn oòrùn tó ń wọ̀, afẹ́fẹ́ tó ń tuni lára, inú wa sì máa ń dùn tí ẹni tá a nífẹ̀ẹ́ bá rẹ́rìn-ín músẹ́ sí wa. Àwọn nǹkan yìí ń mú káyé ẹni dùn.

Máa ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Tí ara wa kò bá tiẹ̀ le dáadáa, a ṣì lè fi ohun tó wà ní Ìṣe 20:35 sílò tó sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.” Inú wa máa ń dùn táwọn èèyàn bá mọyì àwọn ohun tá a ṣe fún wọn, èyí sì máa ń jẹ́ ká gbọ́kàn kúrò lórí ìṣoro wa. A máa túbọ̀ gbádùn ìgbésí ayé wa, tá a bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè gbádùn ìgbésí ayé wọn.

BÍ TỌKỌTAYA ṢE LÈ TÚBỌ̀ MÁA ṢE ARA WỌN LỌ́KAN

Ìmọ̀ràn Bíbélì: “Wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.”​Fílípì 1:10.

Tí tọkọtaya kò bá ń lo àkókò pa pọ̀ dáadáa, àjọṣe wọn lè bà jẹ́. Torí náà, ó yẹ kí ọkọ àti ìyàwó máa fọwọ́ pàtàkì mú ìgbéyàwó wọn torí pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé.

Ẹ jọ máa ṣe nǹkan pa pọ̀. Ó yẹ kí ẹ jọ ṣètò láti máa ṣe nǹkan pa pọ̀ dípò tí kálukú á fi máa ṣe tiẹ̀. Bíbélì sọ pé “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan lọ.” (Oníwàásù 4:9) Ẹ lè jọ se oúnjẹ, ẹ lè jọ ṣe eré ìmárale, ẹ lè jọ gbádùn àwọn èso àti ohun mímu tàbí kẹ́ ẹ jọ tayò tàbí káàdì.

Jẹ́ kí ẹnì kejì rẹ mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ òun. Bíbélì sọ pé kí ọkọ àti ìyàwó nífẹ̀ẹ́ ara wọn kí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún ara wọn. (Éfésù 5:​28, 33) Tó o bá ń rẹ́rìn-ín músẹ́, tàbí tó o gbá ẹnì kejì rẹ mọ́ra, tàbí tó o fún ẹnì kejì rẹ ní ẹ̀bùn kékeré kan, ó máa túbọ̀ jẹ́ kí ìgbéyàwó rẹ lágbára sí i. Ohun pàtàkì tó tún yẹ ká fi sọ́kàn ni pé, ọkọ àti ìyàwó gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìbálòpọ̀ mọ sáàárín àwọn méjèèjì nìkan.​—Hébérù 13:4.