Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tá A Fi Ń Darúgbó Tá A Sì Ń Kú?

Kí Nìdí Tá A Fi Ń Darúgbó Tá A Sì Ń Kú?

ỌLỌ́RUN ò ní in lọ́kàn pé kí àwa èèyàn máa kú. Nígbà tó dá àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, ó fún wọn ní ọpọlọ pípé àti ara pípé. Ká ní kì í ṣe ohun tó ṣẹlẹ̀ ni, wọn ì bá wà títí dòní. Èyí sì ṣe kedere nínú ohun tí Jèhófà sọ fún Ádámù nípa igi kan tó hù nínú ọgbà Édẹ́nì.

Ọlọ́run sọ fún Ádámù nípa igi náà pé: “Ọjọ́ tí o bá jẹ ẹ́ lo máa kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Àṣẹ yẹn ì bá má wúlò ká sọ pé Ọlọ́run dá Ádámù láti darúgbó, kó sì kú. Ádámù mọ̀ pé tí òun ò bá jẹ nínú igi náà, òun ò ní kú.

ỌLỌ́RUN KÒ NÍ IN LỌ́KÀN PÉ KÍ ÀWA ÈÈYÀN MÁA KÚ

Kò pọn dandan kí Ádámù àti Éfà jẹ nínú igi náà kí wọ́n tó lè gbé ẹ̀mí wọn ró, torí pé oríṣirísi igi eléso ló wà nínú ọgbà yẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 2:9) Ká sọ pé wọn ò jẹ nínú igi yẹn, ńṣe nìyẹn máa fi hàn pé wọ́n ṣègbọràn sí ẹni tó fún wọn ní ẹ̀mí. Ó tún máa fi hàn pé wọ́n gbà pé Ọlọ́run ló lẹ́tọ̀ọ́ láti máa darí àwọn.

ÌDÍ TÍ ÁDÁMÙ ÀTI ÉFÀ FI KÚ

Ká lè lóye ìdí tí Ádámù àti Éfà fi kú, ó yẹ ká mọ̀ nípa ìjíròrò kan tó kan gbogbo àwa èèyàn. Sátánì Èṣù lo ejò láti parọ́ burúkú kan. Bíbélì sọ pé: “Nínú gbogbo ẹranko tí Jèhófà Ọlọ́run dá, ejò ló máa ń ṣọ́ra jù. Ó sọ fún obìnrin náà pé: ‘Ṣé òótọ́ ni Ọlọ́run sọ pé ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú èso gbogbo igi inú ọgbà?’ ”​—Jẹ́nẹ́sísì 3:1.

Éfà dá a lóhùn pé: “A lè jẹ lára àwọn èso igi inú ọgbà. Àmọ́ Ọlọ́run sọ fún wa nípa èso igi tó wà láàárín ọgbà pé: ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́, kódà, ẹ ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn án; kí ẹ má bàa kú.’ ” Ejò yẹn wá sọ fún obìnrin náà pé: “Ó dájú pé ẹ ò ní kú. Torí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ tí ẹ bá jẹ ẹ́ ni ojú yín máa là, ẹ máa dà bí Ọlọ́run, ẹ sì máa mọ rere àti búburú.” Ohun tí Sátánì ń sọ ni pé irọ́ ni Jèhófà ń pa, ńṣe ló sì ń fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ wọn.​—Jẹ́nẹ́sísì 3:​2-5.

Éfà gba ọ̀rọ̀ yẹn gbọ́. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í wo igi yẹn, o sì dára lójú rẹ̀, èso igi náà sì wù ú! Ló bá já lára èso rẹ̀, ó sì jẹ̀ ẹ́. Bíbélì fi kún un pé: “Lẹ́yìn náà, ó fún ọkọ rẹ̀ lára èso náà nígbà tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́.”​—Jẹ́nẹ́sísì 3:6.

Ọlọ́run sọ fún Ádámù pé: “Ọjọ́ tí o bá jẹ ẹ́ lo máa kú.”​—JẸ́NẸ́SÍSÌ 2:17

Ẹ wo bó ṣe máa dun Ọlọ́run tó pé àwọn ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí òun! Kí ló wá ṣe? Jèhófà sọ fún Ádámù pé: “Wàá . . . pa dà sí ilẹ̀, torí inú rẹ̀ lo ti wá. Erùpẹ̀ ni ọ́, ìwọ yóò sì pa dà sí erùpẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:​17-19) Torí èyí, “gbogbo ọjọ́ ayé Ádámù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé ọgbọ̀n (930) ọdún, ó sì kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 5:5) Ádámù ò lọ sí ọ̀run tàbí kó máa lọ gbé ibi tí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí wà. Kò sí níbì kankan kí Jèhófà tó dá a látinú erùpẹ̀. Torí náà, nígbà tó kú, ó di erùpẹ̀, kò sì sí mọ́. Ó mà ṣe o, ẹ ò ríbi tó parí ayé ẹ̀ sí!

A KÌ Í ṢE ẸNI PÍPÉ

Torí pé Ádámù àti Éfà mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn, wọn kì í ṣe ẹni pípé mọ́. Ara wọn bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà, wọn di aláìpé àti ẹlẹ́ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn nìkan kọ́ ni àìgbọràn wọn ṣàkóbá fún, àwọn ọmọ tí wọ́n bí náà jogún àìpé àti ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ wọn. Róòmù 5:12 sọ pé: “Bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe tipasẹ̀ ẹnì kan wọ ayé, tí ikú sì wá nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ikú ṣe tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn torí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.”

Bíbélì sọ pé ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú jẹ́ ‘ohun tó ń bo gbogbo èèyàn àti aṣọ tí wọ́n hun bo gbogbo orílẹ̀-èdè.’ (Àìsáyà 25:7) Ohun tó ń bo gbogbo aráyé yẹn dà bíi kùrukùru onímájèlé téèyàn ò lè sá kúrò nínú rẹ̀. Ìyẹn sì bá ohun tí Bíbélì sọ mu pé: “Gbogbo èèyàn ń kú nínú Ádámù.” (1 Kọ́ríńtì 15:22) Ìbéèrè tó wá yẹ ká dáhùn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù béèrè ni pé: “Ta ló máa gbà mí lọ́wọ́ ara tó ń kú lọ yìí?” Ṣé ẹnì kan lè gbà wá?​—Róòmù 7:24.