Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ikú Ò Ṣeé Yẹ̀ Sílẹ̀

Ikú Ò Ṣeé Yẹ̀ Sílẹ̀

KÁ SỌ pé ò ń wo fídíò kan tó sọ nípa olókìkí kan, bóyá gbajúgbajà olórin kan tó o fẹ́ràn gan-an. Fídíò náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìgbà tó wà lọ́mọdé, ìgbà tó ń kẹ́kọ̀ọ́ orin àti ìgbà tó ń fi orin dánra wò léraléra. Lẹ́yìn ìyẹn, o rí i nígbà tó ń lọ kọrin lágbo eré, tó ń rìnrìn àjò lọ sí oríṣiríṣi ìlú, tó wá di olókìkí kári ayé. Àmọ́ kó o tó ṣẹ́jú pẹ́, fídíò náà ti débi ìgbà tó darúgbó, nígbà tó yá, ó kú, fídíò náà sì parí.

Fídíò yìí kì í ṣe ìtàn àròsọ, àmọ́ ó jẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ sí ẹnì kan tó ti kú. Bóyá fídíò náà ń sọ̀rọ̀ nípa olórin kan ni o, àbí onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, eléré ìdárayá tàbí olókìkí èèyàn kan, ohun kan náà ló ń ṣẹ́lẹ̀ sí gbogbo wọn. Ẹni náà ti lè gbé ohun púpọ̀ ṣe láyé, àmọ́ ṣé o kì í rò pé ì bá ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ ká ní ọjọ́ ogbó àti ikú kò gbẹ̀mí rẹ̀?

Ó bani nínú jẹ́ gan-an, àmọ́ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wa náà nìyẹn. (Oníwàásù 9:5) Kò sí bá a ṣe lè gbìyànjú tó, a ò lè gba ara wa lọ́wọ́ ọjọ́ ogbó àti ikú. Yàtọ̀ síyẹn, jàǹbá òjijì àti àìsàn burúkú lè gbẹ̀mí wa. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, a dà bí kùrukùru òwúrọ̀ tó máa “ń wà fúngbà díẹ̀, lẹ́yìn náà tí á pòórá.”​—Jémíìsì 4:14.

Lójú àwọn èèyàn kan, ayé yìí ò já mọ́ nǹkan kan, ìyẹn ló mú kí ọ̀pọ̀ wọn máa gbé ìgbé ayé “ẹ jẹ́ ká máa jẹ, ká sì máa mu, torí ọ̀la la máa kú.” (1 Kọ́ríńtì 15:32) Ìdí tí wọ́n sì fi ń gbé irú ìgbé ayé bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n ti gba kámú pé ọjọ́ kan ń bọ̀ táwọn máa kú. Bópẹ́ bóyá, tírú ẹni bẹ́ẹ̀ bá tiẹ̀ dojú kọ ìṣòro tó le, á máa bi ara rẹ̀ pé, ‘Ṣé ìgbésí ayé ẹ̀dá kò jù báyìí náà lọ?’ Ibo lo ti lè rí ìdáhùn?

Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì lè yanjú ìṣòro wa. Lóòótọ́, ìtẹ̀síwájú nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ ìṣègùn ti mú kí ẹ̀mí èèyàn gùn sí i. Ní báyìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń ṣiṣẹ́ kárakára láti mú kí ẹ̀mí èèyàn túbọ̀ gùn sí i. Ibi yòówù kí ìsapá wọn já sí, ìbéèrè kan tó ṣì yẹ ká dáhùn ni pé: Kí nìdí tá a fi ń darúgbó tá a sì ń kú? Ṣé ìrètí wà pé a máa ṣẹ́gun ikú tó jẹ́ ọ̀tá wa? Àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn kókó yìí, wọ́n sì máa dáhùn ìbéèrè náà: Ṣé ìgbésí ayé ẹ̀dá kò jù báyìí náà lọ?