Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Tó Ti Kú?

Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Tó Ti Kú?

Ikú ti ṣàkóbá fún gbogbo èèyàn, àmọ́ ṣé ikú lòpin ìgbésí ayé ẹ̀dá? Téèyàn bá kú, ṣé ó ti di ẹni ìgbàgbé nìyẹn? Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó ti kú?

WO OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ:

ỌLỌ́RUN Ò GBÀGBÉ ÀWỌN TÓ TI KÚ

“Gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí máa . . . jáde wá.”​—Jòhánù 5:​28, 29.

Ọlọ́run ò gbàgbé àwọn tó ti kú; gbogbo àwọn tó wà nínú ìrántí rẹ̀ máa jíǹde.

ÀJÍǸDE MÁA WÀ NÍ AYÉ

“Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”​—Ìṣe 24:15.

Àìmọye èèyàn ló máa jíǹde, wọ́n á sì ní ìrètí láti gbé títí láé nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.

Ó DÁJÚ PÉ ÀWỌN ÒKÚ MÁA JÍǸDE

“[Ọlọ́run] ń ka iye àwọn ìràwọ̀; gbogbo wọn ni ó ń fi orúkọ pè.”​—Sáàmù 147:4.

Ọlọ́run lè fi orúkọ pe gbogbo àwọn ìràwọ̀, torí náà kò lè ṣòro fún un láti rántí gbogbo àwọn tó máa jí dìde.