Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọlọ́run Ò Dá Wa Pé Ká Máa Kú

Ọlọ́run Ò Dá Wa Pé Ká Máa Kú

KÒ SÍ ẹni tí kò wù láti máa gbádùn ayé ẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀ àti àlàáfíà. Tiẹ̀ wo bó ṣe máa rí ná ká ní a lè máa wà láàyè títí láé nínú ìdẹ̀ra! Àá lè lo àkókò tó pọ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn wa, àá lè rìnrìn àjò kárí ayé, àá lè kọ́ àwọn iṣẹ́ tuntun, ọgbọ́n wa á pọ̀ sí i, àá sì túbọ̀ ní ìmọ̀ tó jinlẹ̀ nípa àwọn nǹkan tó wù wá.

Ṣé ó burú kó máa wu èèyàn láti wà láàyè títí láé? Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé Ọlọ́run ti fi sí wa lọ́kàn láti máa wà láàyè nìṣó. (Oníwàásù 3:11) Àti pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Àmọ́, tí Ọlọ́run ò bá fẹ́ ká wà láàyè títí láé, ṣé ó bọ́gbọ́n mu pé kó dá wa lọ́nà táá fi máa wù wá láti wà láàyè títí láé?

Ó ṣe kedere pé ikú kì í ṣe ọ̀rẹ́ wa. Kódà, Bíbélì pe ikú ní “ọ̀tá.” (1 Kọ́ríńtì 15:26) Ikú máa ń pa àwọn kan ní kékeré, ó sì máa ń pa àwọn kan tí wọ́n bá ti pẹ́ láyé dáadáa. Àmọ́ bópẹ́ bóyá kò sẹ́ni tí kò ní kú. Kì í bára dé fún ọ̀pọ̀ tí wọ́n bá ronú kan ikú, ó tiẹ̀ máa ń bà wọ́n lẹ́rù pàápàá. Ṣé ìgbà kan ń bọ̀ tá a máa ṣẹ́gun ọ̀tá yìí? Ṣé a lè ṣàṣeyọrí?

Ẹ̀RÍ TÓ FI HÀN PÉ ÌRÈTÍ WÀ

Ǹjẹ́ kò yani lẹ́nu pé Ọlọ́run ò ní in lọ́kàn pé káwa èèyàn máa kú? Ìwé Jẹ́nẹ́sísì nínú Bíbélì fi ẹ̀rí hàn pé Ọlọ́run fẹ́ kí ẹ̀dá èèyàn máa gbé inú ayé títí láé. Jèhófà fara balẹ̀ ṣètò ayé yìí lọ́nà tó máa ṣeé gbé fún àwa èèyàn. Lẹ́yìn ìyẹn, ó dá Ádámù, ó sì fi sínú ọgbà Édẹ́nì. Lẹ́yìn náà, “Ọlọ́run rí gbogbo ohun tó ti ṣe, sì wò ó! ó dára gan-an.”​—Jẹ́nẹ́sísì 1:​26, 31.

A dá Ádámù ní pípé ní àwòrán Ọlọ́run. (Diutarónómì 32:4) Éfà ìyàwó rẹ̀ náà kò ní àbùkù kankan, ara àti èrò rẹ̀ pé. Jèhófà sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bímọ, kí ẹ sì pọ̀, kí ẹ kún ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí ẹ máa jọba lórí àwọn ẹja inú òkun, àwọn ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run àti lórí gbogbo ohun alààyè tó ń rìn lórí ilẹ̀.”​—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.

Kí ọmọ wọn tó lè kún ayé, ó máa gba àkókò. Éfà máa bímọ, àwọn ọmọ náà máa bí ọmọ tiwọn títí àwọn èèyàn á fi kún ayé bí Ọlọ́run ṣe ní in lọ́kàn. (Àìsáyà 45:18) Ṣé ó bọ́gbọ́n mu pé kí Ọlọ́run ṣèlérí yẹn fún Ádámù àti Éfà tó bá jẹ́ pé wọn kò ní lè rí ju àwọn ọmọ wọn tàbí àwọn ọmọ-ọmọ wọn lọ?

Tún ronú nípa àṣẹ tó pa fún wọn pé kí wọ́n máa jọba lórí àwọn ẹranko. Ó ní kí Ádámù sọ àwọn ẹranko lórúkọ, ìyẹn á sì gba àkókò. (Jẹ́nẹ́sísì 2:19) Àmọ́ láti máa jọba lórí wọn lè túmọ̀ sí pé ó ní láti kọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe, kó sì mọ bó ṣe máa tọ́jú wọn. Ó dájú pé ìyẹn á gba àkókò tó pọ̀ gan-an.

Nítorí náà, àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún wọn pé kí wọ́n kún ayé kí wọ́n sì máa jọba lórí àwọn ẹranko fi hàn pé Ọlọ́run dá tọkọtaya àkọ́kọ́ náà láti máa gbé ayé títí láé. Ká sòótọ́, Ádámù pẹ́ láyé gan-an.

ỌLỌ́RUN FẸ́ KÍ ARÁYÉ MÁA GBÉ TÍTÍ LÁÉ NÍNÚ PÁRÁDÍSÈ

WỌ́N PẸ́ LÁYÉ GAN-AN

Ádámù, 930 ọdún

Mètúsélà, 969 ọdún

Nóà 950, ọdún

Lónìí, 70 sí 80 ọdún

Bíbélì fi hàn pé láyé ìgbà kan, ẹ̀mí àwọn èèyàn máa ń gùn ju tiwa lọ lóde òní. Ó sọ pé: “Gbogbo ọjọ́ ayé Ádámù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé ọgbọ̀n (930) ọdún.” Lẹ́yìn náà, ó tún mẹ́nu kan àwọn ọkùnrin mẹ́fà míì tí wọ́n gbé ayé ju ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900) ọdún lọ! Àwọn ni Sẹ́ẹ̀tì, Énọ́ṣì, Kénánù, Járédì, Mètúsélà àti Nóà. Gbogbo wọn gbé ayé ṣáájú Ìkún Omi ọjọ́ Nóà, Nóà sì ti lo ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọdún láyé kí Ìkún Omi tó dé. (Jẹ́nẹ́sísì 5:​5-27; 7:6; 9:29) Kí ló fà á tí àwọn èèyàn fi pẹ́ láyé gan-an nígbà yẹn?

Gbogbo àwọn èèyàn yẹn gbé lákòókò tó sún mọ́ ìgbà tí èèyàn ṣì jẹ́ pípé. Ó jọ pé ìyẹn ni ìdí pàtàkì tí wọ́n fi pẹ́ láyé gan-an. Ṣé lóòótọ́ ni pé táwa èèyàn bá di pípé a ò ní kú mọ́? Báwo la sì ṣe máa ṣẹ́gun ikú? Láti rí àwọn ìdáhùn yìí, a ní láti kọ́kọ́ lóye ìdí tí a fi ń darúgbó tí a sì ń kú.