Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÍ ỌLỌ́RUN ṢE PA​—BÍBÉLÌ MỌ́

Bíbélì Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Alátakò

Bíbélì Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Alátakò

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO: Ọ̀pọ̀ àwọn olóṣèlú àtàwọn aṣáájú ẹ̀sìn ti ṣe ohun tó lòdì sí ẹ̀kọ́ Bíbélì. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ti lo agbára wọn láti má ṣe jẹ́ kí àwọn èèyàn ní Bíbélì tiwọn, kí wọ́n tẹ̀ é jáde, tàbí kí wọ́n sì tú u sí èdè míì. Wo àpẹẹrẹ méjì yìí:

  • Nǹkan Bí Ọdún 167 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni: Ọba Seleucid Antiochus Epiphanes, gbìyànjú láti mú kí àwọn Júù máa ṣe ẹ̀sìn àwọn Gíríìkì, torí náà ó pàṣẹ pé kí wọ́n ba gbogbo Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù jẹ́. Òpìtàn kan tó ń jẹ́ Heinrich Graetz kọ̀wé pé, àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ máa ń “fa gbogbo ìwé Òfin tí wọ́n bá ti rí ya, wọ́n á sì dáná sun ún. Wọ́n sì tún máa ń pa ẹni tí wọ́n bá rí i pé ó gbádùn láti máa ka Bíbélì láti fún ara rẹ̀ lókun àti ìtùnú.”

  • Àkókò Ọ̀làjú: Àwọn kan lára àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Kátólíìkì máa ń bínú pé àwọn ọmọ ìjọ ń kọ́ni ní ohun tí Bíbélì sọ dípò ẹ̀kọ́ ìsìn Kátólíìkì. Ojú burúkú ni wọ́n fi ń wo ọmọ ìjọ tó bá ní àwọn ìwé Bíbélì míì yàtọ̀ sí Sáàmù ní èdè Látìn. Ìgbìmọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì kan tiẹ̀ pàṣẹ pé kí àwọn ọkùnrin kan lọ máa tú ilé àwọn èèyàn tí wọ́n fura sí pé ó ní Bíbélì. Ńṣe ni wọ́n máa ń ba ilé tí wọ́n bá ti rí Bíbélì jẹ́.

Ká sọ pé àwọn tó ń tako Bíbélì ti ṣàṣeyọrí láti pa á run, àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ náà ì bá ti pa run.

Wọ́n fòfin de Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì tí William Tyndale túmọ̀, wọ́n dáná sun ún, wọ́n sì pa Tyndale fúnra rẹ̀ lọ́dún 1536, síbẹ̀ Bíbélì náà kò pa run

OHUN TÓ JẸ́ KÍ BÍBÉLÌ WÀ DÒNÍ: Ilẹ̀ Ísírẹ́lì ni Ọba Antiochus dojú ìjà kọ, àmọ́ àwọn Júù ti fọ́n ká sí àwọn ilẹ̀ míì káàkiri. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan tiẹ̀ sọ pé nígbà tó fi máa di ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, àwọn Júù tó ń gbé nílẹ̀ òkèèrè ti pọ̀ gan-an ju àwọn tó ń gbé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lọ. Àwọn Júù wọ̀nyẹn máa ń tọ́jú Ìwé Mímọ́ sínú àwọn sínágọ́gù wọn. Àwọn Ìwé Mímọ́ tí wọ́n tọ́jú yìí ni àwọn ìran tó tẹ̀ lẹ́ wọn lò, tó fi mọ́ àwọn Kristẹni.—Ìṣe 15:21.

Láàárín Àkókò Ọ̀làjú, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Bíbélì fara da ìyà tí wọ́n fi jẹ wọ́n, kí wọ́n lè túmọ̀ Bíbélì kí wọ́n sì tẹ̀ ẹ́ jáde. Ní àárín ọdún 1500, àwọn apá kan lára Bíbélì wà ní èdè mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [33], bẹ́ẹ̀ wọn ò tíì ṣe ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ayára-bí-àṣá nígbà yẹn! Àmọ́ lẹ́yìn àkókò náà, iṣẹ́ títúmọ̀ Bíbélì àti títẹ̀ ẹ́ jáde wá túbọ̀ yára kánkán.

ÀBÁJÁDE RẸ̀: Àwọn ọba aláṣẹ àtàwọn aṣáájú ìsìn ti gbéjà ko Bíbélì, síbẹ̀ nínú gbogbo ìwé tó wà láyé, Bíbélì nìkan làwọn èèyàn ní nílé-lóko, tó sì tún wà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè. Ó ti ran àwọn orílẹ̀-èdè kan lọ́wọ́ nínú òfin àti èdè wọn, ó sì ti mú kí ìgbésí ayé ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn dára sí i.