Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

Mo Ṣàṣìṣe Lọ́pọ̀ Ìgbà àmọ́ Mo Ṣàṣeyọrí

Mo Ṣàṣìṣe Lọ́pọ̀ Ìgbà àmọ́ Mo Ṣàṣeyọrí
  • ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1953

  • ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: ỌSIRÉLÍÀ

  • IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ÀWÒRÁN ÌṢEKÚṢE DI BÁRAKÚ FÚN MI

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:

Bàbá mi ṣí kúrò ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà lọ sí ìgbèríko Victoria lórílẹ̀-èdè Jámánì lọ́dún 1949, kó lè wá iṣẹ́ sí àwọn iléeṣẹ́ tí wọ́n ti ń wa góòlù tàbí iléeṣẹ́ mọ̀nàmọ́ná. Ìlú yẹn ló ti pàdé ìyá mi tí wọ́n sì fẹ́ra. Wọ́n bí mi lọ́dún 1953.

Ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà ni màmá mi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, torí náà àtikékeré lèmi náà ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́, bàbá mi kò nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀sìn kankan. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà ìkà sí màmá mi, débi pé màmá mi máa ń bẹ̀rù rẹ̀ gan-an. Síbẹ̀ màmá mi kò dáwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà dúró, wọ́n sì fẹ́ràn ẹ̀kọ́ náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n ń yọ́ ọ ṣe. Tí dádì mi bá ti jáde nílé, màmá mi máa ń kọ́ èmi àti àbúrò mi obìnrin lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó kọ́ wa pé tó bá yá gbogbo ayé máa di Párádísè àti pé a máa láyọ̀ tá a bá ń fi ohun tá a kọ́ nínú Bíbélì ṣèwà hù.—Sáàmù 37:10, 29; Aísáyà 48:17.

Bí dádì wa ṣe burú mọ́ wa mú kí n kó jáde nílé nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìdínlógún [18]. Mo gbà pé òótọ́ lohun tí màmá mi kọ́ wa látinú Bíbélì, àmọ́ mi ò kà á sí pàtàkì. Torí náà, mi ò tẹ̀ lé àwọn ẹ̀kọ́ náà. Mo ríṣẹ́ mọ̀nàmọ́ná síléeṣẹ́ tí wọ́n ti ń wa góòlù. Mo sì ṣègbéyàwó lọ́mọ ogún [20] ọdún. Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà la bí àkọ́bí wa tó jẹ́ obìnrin, mo sì ronú lórí ohun tó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé mi. Mo mọ̀ pé Bíbélì lè ran ìdílé wa lọ́wọ́, èyí ló mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, ìyàwó mi kò fara mọ́ ọn. Nígbà tí mo lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyàwó mi kìlọ̀ fún mi pé mo gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, òun á kó jáde ńlé fún mi. Mi ò mọ nǹkan tí mo lè ṣe, ni mo bá gbọ́ tìyàwó mi, mi ò sì kẹ́kọ̀ọ́ mọ́. Àmọ́, mo kábàámọ̀ pé mo kọ̀ láti ṣe ohun tí mo mọ̀ pé ó tọ́.

Lọ́jọ́ kan, ẹnì kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ fi àwòrán ìṣekúṣe hàn mí. Ó dùn mọ́ mi, àmọ́ ó tún kó ìdààmú bá mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í dá ara mi lẹ́bi. Mo rántí ohun tí mo ti kọ́ nínú Bíbélì, mo sì gbà lọ́kàn ara mi pé Ọlọ́run máa fìyà jẹ mí. Síbẹ̀ ńṣe ni ìwòkuwò náà túbọ̀ ń wọ̀ mí lára, mi ò sì rí ohun tó burú nínú rẹ̀ mọ́. Nígbà tó yá, mo kúkú wá jingíri sínú rẹ̀.

Ó lé lógún ọdún tí mo fi jìnnà réré sí àwọn ìlànà rere tí màmá mi ti fi kọ́ mi. Ìwàkíwà tí mò ń gbé sọ́kàn náà ni mò ń hù níwà. Ìsọkúsọ ló kún ẹnu mi, mo sì máa ń dápàárá rírùn. Mo sì ní èrò tí kò tọ́ nípa ìbálòpọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì ń gbé pẹ̀lú ìyàwó mi, síbẹ̀ mo láwọn obìnrin míì tí mò ń gbé níta. Lọ́jọ́ kan, mo wo ara mi nínú gíláàsì mo sì sọ pé, “Wo báyé ẹ ṣe dà.” Mi ò jámọ́ nǹkan kan lójú ara mi mọ́.

Ìdílé mi túká, ìgbésí ayé mi sì dìdàkudà. Mo wá fi gbogbo ọkàn mi gbàdúrà sí Jèhófà. Mo pa dà sídìí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi, bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo ti pa á tì fún ohun tó lé lógún ọdún. Nígbà yẹn, bàbá mi ti kú, màmá mi sì ti ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:

Ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ ló wà nínú bí mo ṣe ń gbé ìgbé ayé mi àti ìlànà gíga tó wà nínú Bíbélì. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, mo pinnu láti rí àlàáfíà ọkàn tí Bíbélì sọ. Mo sapá láti jáwọ́ nínú ìsọkúsọ àti ìbínú òdì. Mo tún pinnu láti jáwọ́ nínú ìṣekúṣe, tẹ́tẹ́ títa, ọtí àmujù àti bí mo ṣe ń ja àwọn tó gbà mí síṣẹ́ lólè.

Àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ kò mọ ìdí tí mo fi ń ṣe gbogbo àwọn ìyípadà ńlá yìí. Ọdún mẹ́ta gbáko ni wọ́n fi fìtínà mi kí n lè pa dà sí ìgbésí ayé mi àtẹ̀yìnwá. Tí mo bá ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó, irú bíi kí n sọ̀sọkúsọ tàbí kí n bínú, inú wọn á dùn, wọ́n á sọ pé: “À-á! Ohun tá a fẹ́ nìyẹn.” Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn máa ń bí mi nínú! Mo sì máa ń dà bí aláṣetì.

Àwòrán ìṣekúṣe ló kún ibiṣẹ́ wa, èyí tó wà lórí ẹ̀rọ àti tinú ìwé. Gbogbo ìgbà làwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ ń fi àwòrán ìṣekúṣe ránṣẹ́ sórí kọ̀ǹpútà mi, bá a ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Mò ń sápá láti jáwọ́ nínú àṣà tó ti wọ̀ mí lára yìí, àmọ́ ó jọ pé wọn ò fẹ́ kí n jáwọ́. Mo ṣàlàyé gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún ẹni tó ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó lè ràn mí lọ́wọ́, kó sì fún mi níṣìírí. Ó sì fara balẹ̀ gbọ́ gbogbo ẹ̀dùn ọkàn mi. Ó lo àwọn ẹsẹ Bíbélì kan láti fi bí mo ṣe lè borí ìṣòro náà hàn mí, ó sì rọ̀ mí láti máa gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn mí lọ́wọ́.—Sáàmù 119:37.

Lọ́jọ́ kan, mo pe gbogbo àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́. Nígbà tẹ́sẹ̀ gbogbo wọn pé, mo ní kí wọ́n fún àwọn méjì lára wọn ní ọtí. Ni gbogbo wọn bá bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo pé: “Báwo lo ṣe máa fún wọn lọ́tí! O ṣáà mọ̀ pé wọ́n fẹ́ jáwọ́ nínú ọtí àmujù!” Lèmi náà bá sọ fún wọn pé: “Ohun témi náà fẹ́ ṣe nìyẹn.” Àtọjọ́ yẹn ni wọn ò ti yọ mí lẹ́nu mọ́, wọ́n mọ̀ pé èmi náà fẹ́ jáwọ́ nínú ìwòkuwò.

Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú wíwo àwòrán ìṣekúṣe tó ti di bárakú fún mi. Lọ́dún 1999, mo ṣe ìrìbọmi láti di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo dúpẹ́ pé mo láǹfààní láti tún ìgbésí ayé mi ṣe, mo sì láyọ̀.

Mo ti wá mọ ìdí tí Jèhófà fi kórìíra ohun tí mo nífẹ̀ẹ́ sí látọjọ́ yìí. Torí pé Bàbá tó nífẹ̀ẹ́ mi ni, ó fẹ́ gbà mí lọ́wọ́ ìpalára tí àwòrán ìṣekúṣe máa ń fà. Òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ tó wà nínú Òwe 3:5, 6! Ó sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” Àwọn ìlànà Bíbélì máa ń dáàbò bò wá, ó sì máa ń jẹ́ ká ṣàṣeyọrí láyé wa.—Sáàmù 1:1-3.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:

Tẹ́lẹ̀, mi ò já mọ́ nǹkan kan lójú ara mi, àmọ́ ní báyìí mo ti wá níyì lójú ara mi, mo sì ní àlàáfíà tó tọkàn wá. Mo ti ń gbé ìgbésí ayé tó mọ́ báyìí, ó sì dá mí lójú pé Jèhófà ti dárí jì mí, ó sì ń tì mí lẹ́yìn. Lọ́dún 2000, mo fẹ́ Karolin, arẹwà obìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni tó sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà bíi tèmi. Ilé aláyọ̀ ni ilé wa báyìí. Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé a wà lára àwọn Kristẹni tó wà kárí ayé, tó ń fìfẹ́ bá ara wọn lò, tí wọ́n sì níwà mímọ́.