Ohun Tí Bíbélì Sọ
Ṣé Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè borí àníyàn rẹ?
Kí ni ìdáhùn rẹ?
Bẹ́ẹ̀ ni
Bẹ́ẹ̀ kọ́
Kò dá mi lójú
Ohun tí Bíbélì sọ
“Kó gbogbo àníyàn yín lé [Ọlọ́run], nítorí ó bìkítà fún yín.” (1 Pétérù 5:7) Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè bọ́ lọ́wọ́ àníyàn.
Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?
Tá a bá ń gbàdúrà, a lè ní “àlàáfíà Ọlọ́run” tó máa mú kí àníyàn wa fúyẹ́.—Fílípì 4:6, 7.
Láfikún sí i, kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè mú ká fara da ìdààmú ọkàn.—Mátíù 11:28-30.
Ṣé àníyàn máa dópin?
Èrò àwọn kan ni pé. . . kò sí báwa èèyàn kò ṣe ní ṣàníyàn tàbí dààmú, àwọn míì sì gbà pé ó di ayé àtúnwá ká tó lè bọ́ lọ́wọ́ ṣíṣe àníyàn. Kí lèrò rẹ?
Ohun tí Bíbélì sọ
Ọlọ́run máa mú ohun tó ń fa àníyàn kúrò. “Ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”—Ìṣípayá 21:4.
Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?
Tí Ìjọba Ọlọ́run bá dé, àwọn èèyàn á máa gbé ayé ní àlàáfíà, láìsí ìyọlẹ́nu kankan.—Aísáyà 32:18.
Kò ní sídìí fún wọn láti máa ṣàníyàn tàbí dààmú.—Aísáyà 65:17.