Ìjà Dáfídì Àti Gòláyátì—Ṣé Ó Ṣẹlẹ̀ Lóòótọ́?
Àwọn kan ń ṣiyèméjì pé ṣé òótọ́ ni ìtàn Dáfídì àti Gòláyátì àbí àròsọ lásán ni. Ṣé irú èrò bẹ́ẹ̀ wá sí ìwọ náà lọ́kàn bó o ṣe ń ka àpilẹ̀kọ tó ṣáájú? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, jọ̀wọ́ gbé ìbéèrè mẹ́ta yìí yẹ̀ wò.
1 | Ṣé èèyàn lè ga tó ẹsẹ̀ bàtà mẹ́sàn-án àtààbọ̀ (9 ft 6 in)?
Bíbélì sọ pé Gòláyátì ga tó “ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà àti ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan.” (1 Sámúẹ́lì 17:4) Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ íǹṣì mẹ́tàdínlógún àti ẹ̀sún márùn-ún (17.5 in), ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan sì fi díẹ̀ dín ní íǹṣì mẹ́sàn-án (8.75 in). Tá a bá rò ó pọ̀, ó jẹ́ nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́sàn àtààbọ̀ (9 ft 6 in). Àmọ́, àwọn kan sọ pé Gòláyátì ò lè ga tó bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n ronú lórí èyí: Ẹni tó ga jù láyé báyìí jẹ́ ẹsẹ̀ bàtà mẹ́jọ àti íǹṣì mọ́kànlá (8 ft 11 in). Ṣé a wá lè sọ pé Gòláyátì ò lè fi íǹṣì mẹ́fà (6 in) péré ga ju ẹni yìí lọ? Inú ẹ̀yà Réfáímù ni Gòláyátì ti wá, wọ́n sì máa ń ṣe fìrìgbọ̀n ju àwọn ẹ̀yà tó kù lọ. Ìwé kan táwọn ará Íjíbítì ṣe ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún kẹtàlá Ṣáájú Sànmánì Kristẹni sọ pé àwọn àkòtagìrì jagunjagun láti àgbègbè Kénáánì máa ń ga tó ẹsẹ̀ bàtà mẹ́jọ (8 ft). Torí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Gòláyátì ga lọ́nà àrà ọ̀tọ̀, ẹ̀rí wà pé kì í ṣe tiẹ̀ làkọ́kọ́.
2 | Ṣé òótọ́ lẹnì kan wà tó ń jẹ́ Dáfídì?
Ìgbà kan wà táwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan gbìyànjú láti sọ pé ìtàn àròsọ ni ìtàn Dáfídì Ọba, àmọ́ kò sẹ́ni tó lè sọ bẹ́ẹ̀ mọ́ báyìí. Ìdí ni pé àwọn awalẹ̀pìtàn ti rí àfọ́kù òkúta tó ti wà látayé ìgbàanì tí wọ́n kọ “ilé Dáfídì” sí lára. Láfikún sí i, Jésù Kristi sọ̀rọ̀ nípa Dáfídì pé ó gbé ayé lóòótọ́. (Mátíù 12:3; 22:43-45) Bákan náà, ìlà ìdílé Dáfídì Ọba ni Jésù ti wá, èyí sì jẹ́ ẹ̀rí pé Jésù ni Mèsáyà. (Mátíù 1:6-16; Lúùkù 3:23-31) Gbogbo èyí mú kó ṣe kedere pé òótọ́ lẹnì kan wà tó ń jẹ́ Dáfídì.
3 | Ṣé ibi tí ìtàn náà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ wà lóòótọ́?
Bíbélì sọ pé Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Éláhì ni Dáfídì àti Gòláyátì ti bára wọn jà. Bíbélì tún fi hàn pé àwọn ọmọ ogun Filísínì tẹ̀dó sí orí òkè kan tó wà láàárín ìlú Sókóhì àti Ásékà. Àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì sì tẹ̀dó sí orí òkè tó wà ní òdì kejì òkè náà. Ṣé àwọn ìlú yìí wà lóòótọ́?
Gbọ́ ohun tí àwọn tó rìnrìn àjò lọ sí àgbègbè yẹn lẹ́nu àìpẹ́ yìí sọ, wọ́n ní: “Ẹni tó mú wà rìn yíká, tí kì í ṣe ẹlẹ́sìn, mú wa dé Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Éláhì. A wá gba ọ̀nà kan dé orí òkè ńlá kan tó wà níbẹ̀. Bá a ṣe ń wo pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà, ó ní ká ka 1 Sámúẹ́lì 17:1-3. Lẹ́yìn náà, ó wá nawọ́ sí òdì kejì pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà, ó sì sọ pé: ‘Àwókù ìlú Sókóhì lẹ̀ ń wò lọ́wọ́ òsì yín yẹn.’ Ó tún yí pa dà, ó sì sọ pé, ‘Àwókù ìlú Ásékà ló wà lọ́wọ́ ọ̀tún yín yẹn. Àárín méjì àwọn ìlú yẹn làwọn ọmọ ogun Filísínì tẹ̀dó sí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ apá ibì kan lórí òkè tẹ́ ẹ̀ ń wò lọ́ọ̀ọ́kán yẹn. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ibi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀dó sí la wà yìí.’ Mo ronú pé ibi tí mo dúró sí yìí ni Sọ́ọ̀lù àti Dáfídì náà dúró sí. A wá sọ̀ kalẹ̀ lórí òkè náà, nígbà tá a dé ìsàlẹ̀, a fo odò kan tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ tán, òkúta sì pọ̀ nínú rẹ̀. Mo wá fọkàn yàwòrán pé Dáfídì dúró níbi odò yìí, ó sì ṣa òkúta márùn-ún, tó fi ọ̀kan lára rẹ̀ pa Gòláyátì.” Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé tí kò lábùlà tí Bíbélì ṣe wú arìnrìn àjò yìí lórí gan-an, bẹ́ẹ̀ náà ló sì máa ń rí lára ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lọ sí àgbègbè yìí.
Kò sí ìdí kankan tó fi yẹ kéèyàn máa ṣiyè méjì nípa ìtàn yìí. Àwọn èèyàn tó gbé ayé ló ṣẹlẹ̀ sí, ibi tó sì ti ṣẹlẹ̀ ṣì wà títí dòní. Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé, ó wà lára Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí. Torí náà, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run òtítọ́, Ẹni “tí kò lè purọ́” ló ti wá.—Títù 1:2; 2 Tímótì 3:16.