KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | IBO LO TI LÈ RÍ ÌTÙNÚ?
Bá A Ṣe Lè Rí Ìtùnú Lásìkò Wàhálà
Onírúurú ìṣòro làwa èèyàn máa ń dojú kọ. A ò lè sọ̀rọ̀ nípa gbogbo ìṣòro náà báyìí, àmọ́ a máa sọ̀rọ̀ nípa mẹ́rin lára àwọn àpẹẹrẹ tá a mẹ́nu bà. Kó o sì kíyè sí bí àwọn tó ń dojú kọ onírúurú ìṣòro ṣe rí ìtùnú gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
TÍ IṢẸ́ BÁ BỌ́ LỌ́WỌ́ RẸ
Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Seth * sọ pé: “Ìgbà kan náà ni iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ èmi àti ìyàwó mi. Owó táwọn mọ̀lẹ́bí ń fún wa àti iṣẹ́ lébìrà la fi gbọ́ bùkátà ara wa fún ọdún méjì gbáko. Èyí kó ẹ̀dùn ọkàn bá Priscilla, ìyàwó mi, èmi náà ò sì já mọ́ nǹkan kan lójú ara mi.
“Ọgbọ́n wo la wá dá sí i? Gbogbo ìgbà ni Priscilla máa ń ronú lórí ọ̀rọ̀ Jésù tó wà ní Mátíù 6:34. Jésù sọ pé ká má ṣe ṣàníyàn nípa ọ̀la, torí pé ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ló ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Àdúrà tí ìyàwó mi máa ń gbà látọkànwá sì máa ń fún un lókun láti máa fara dà á. Sáàmù 55:22 ló ran èmi lọ́wọ́. Bíi ti ẹni tó kọ Sáàmù yẹn, ńṣe ni mo ju gbogbo ẹrù ìnira mi sọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì ràn mí lọ́wọ́. Ní báyìí mo ti ríṣẹ́, síbẹ̀ à ṣì ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù tó wà ní Mátíù 6:20-22, a ò sì ṣe kọjá agbára wa. Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé, a ti sún mọ́ Ọlọ́run gan-an, èmi àtìyàwó mi sì tún ti mọ́wọ́ ara wa dáadáa.”
Jonathan sọ pé: “Ẹ̀rù bà mí gan-an nígbà tí okòwò tí ìdílé wa ń ṣe dẹnu kọlẹ̀. Torí ìṣòro ọrọ̀ ajé tí kò lọ dáadáa, gbogbo ohun tá a ti fi ogún [20] ọdún kó jọ ló lọ láú. Ó wá di pé kémi àti ìyàwó mi máa bára wa jiyàn lórí ọ̀rọ̀ owó. Ó le débi pé a ò lè lo káàdì tá a fi ń rajà láwìn torí pé ẹ̀rù ń bà wá pé wọ́n lè má tajà fún wa.
“Àmọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́. Mo gbà láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá yọjú, a sì dín ìnáwó wa kù. Torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, àwọn ará wa tún ràn wá lọ́wọ́. Wọn ò jẹ́ kójú tì wá, wọ́n sì máa ń tì wá lẹ́yìn nígbà tí nǹkan bá le koko.”
BÍ ÌGBÉYÀWÓ BÁ TÚ KÁ
Raquel sọ pé: “Nígbà tí ọkọ mi já mi jù sílẹ̀ ní ọ̀sán kan òru kan, ó dùn mí wọra, inú sì bí mi gan-an. Ìbànújẹ́ tó kọjá àfẹnusọ dorí mi kodò. Àmọ́ mo sún mọ́ Ọlọ́run. Ọkàn mi sì máa ń balẹ̀ tí mo bá gbàdúrà sí Ọlọ́run. Ńṣe ló dà bíi pé Ọlọ́run wo ọgbẹ́ ọkàn mi sàn.
“Ọpẹ́lọpẹ́ Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lára mi, òun ló jẹ́ kí n lè gbé ìbínú àti ìkórìíra kúrò lọ́kàn. Mo tún máa ń fi ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ́kàn, èyí tó wà nínú Róòmù 12:21, tó sọ pé: ‘Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n máa fi ire ṣẹ́gun ibi.’
“Ọ̀rẹ́ mi kan tún jẹ́ kí n rí ìdí tó fi yẹ kí n máa bá ìgbésí ayé mi lọ. Ó fi ohun tó wà nínú Oníwàásù 3:6 hàn mí, ó sì sọ fún mi pé ìgbà míì wà tó máa gba pé ká gbọ́kàn kúrò lára nǹkan wa tó ‘ti sọnù.’ Ìmọ̀ràn yẹn le lójú mi, àmọ́ ohun tí mo nílò gan-an nìyẹn. Mo ti wá ní àwọn nǹkan tuntun tí mò ń lépa báyìí.”
Elizabeth sọ pé: “Èèyàn máa ń nílò ìtìlẹ́yìn lásìkò tí ìgbéyàwó rẹ̀ bá tú ká. Mo ní ọ̀rẹ́ kan tó máa ń fún mi ní irú ìtìlẹ́yìn bẹ́ẹ̀ lójoojúmọ́. Ó máa ń bá mi sunkún, ó máa ń tù mí nínú, ó sì máa ń jẹ́ kí n mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ mi. Ó dá mi lójú pé ńṣe ni Jèhófà lò ó láti wo ọgbẹ́ ọkàn mi sàn.”
TÍ ÀÌSÀN TÀBÍ ỌJỌ́ OGBÓ BÁ DÉ
Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Luis, tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ ní àrùn ọkàn tó lágbára gan-an, ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú. Ní báyìí, ó ní láti lo ẹ̀rọ téèyàn fi ń mí fún wákàtí mẹ́rìndínlógún [16] lójoojúmọ́. Ó sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà. Tí mo bá ti gbàdúrà, mo máa ń mọ̀ ọ́n lára pé ẹ̀mí Ọlọ́run ti fún mi lókun. Àdúrà máa ń jẹ́ kí n nígboyà láti má ṣe sọ̀rètí nù, torí mò nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, mo sì mọ̀ pé ó bìkítà fún mi.”
Obìnrin kan tó ń jẹ́ Petra tó ti lé lẹ́ni ọgọ́rin [80] ọdún sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń wù mí láti ṣe, àmọ́ agbára mi ò gbé e. Kò rọrùn rárá bí mi ò ṣe lókun mọ́. Mi ò lè dá nǹkan kan ṣe, oògùn ni mo sì fi ń gbéra. Mo sábà máa ń ronú nípa bí Jésù ṣe bẹ Bàbá rẹ̀ pé kó jẹ́ kí àwọn ìṣòro kan ré òun kọjá, tó bá ṣeé ṣe. Àmọ́, Jèhófà fún Jésù lókun, ó sì ń fún Mátíù 26:39.
èmi náà lókun. Ojoojúmọ́ ni mò ń gbàdúrà, ara sì máa ń tù mí lẹ́yìn tí mo bá ti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀.”—Bọ́rọ̀ ṣe rí lára Julian náà nìyẹn. Ó ti tó ọgbọ̀n [30] ọdún báyìí tí àìsàn sclerosis tó máa ń mú kí iṣan ara le gbagidi, ti ń yọ ọ́ lẹ́nu. Ó sọ pé: “Èmi tí mo máa ń jókòó sórí àga ọlọ́lá tẹ́lẹ̀ wá dẹni tó ń jókòó sórí àga arọ. Àmọ́ ayé yẹ mí torí pé mò ń ṣe ohun tó ń ṣe àwọn míì láǹfààní. Fífún àwọn èèyàn ní nǹkan lè dín ìyà tó ń jẹ wọ́n kù. Jèhófà sì máa ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun á fún wa lókun nígbà ìṣòro. Èmi náà lè sọ ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: ‘Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.’”—Fílípì 4:13.
TÍ ÈÈYÀN RẸ BÁ KÚ
Antonio sọ pé: “Ńṣe ló dà bí àlá lójú mi nígbà tí bàbá mi kú nínú ìjàǹbá tó ṣẹlẹ̀ sí wọn. Kó dáa rárá, torí pé jẹ́jẹ́ ni wọ́n ń fẹsẹ̀ rìn lọ, tí mọ́tò fi yà lọ gbá wọn. Àmọ́ kò sí ohun tí mo lè ṣe sí i. Ọjọ́ márùn-ún ni wọn ò fi mọ nǹkan kan, kí wọ́n tó kú. Mi ò kì í sunkún tí mo bá wà lọ́dọ̀ màmá mi, àmọ́ tí mo bá dá wà, ńṣe ni mo máa ń wa ẹkún mu. Ohun tí mo ṣáà ń bi ara mi ni pé, ‘Kí ló dé tírú èyí fi ṣẹlẹ̀.’
“Ní gbogbo àkókò yẹn, mi ò yéé gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́ láti borí ẹ̀dùn ọkàn mi, kó sì fi mí lọ́kàn balẹ̀. Nígbà tó yá, ara bẹ̀rẹ̀ sí í tù mí. Mo rántí ọ̀rọ̀ Bíbélì tó sọ pé ‘ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀’ lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni lára wa. Ó dá mi lójú pé màá rí bàbá mi pa dà nígbà àjíǹde, torí pé Ọlọ́run kò lè parọ́.”—Oníwàásù 9:11; Jòhánù 11:25; Títù 1:2.
Èrò yẹn náà ni Robert tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú ní. Ó sọ pé: “Èmi àtìyàwó mi ti wá mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ní àlàáfíà Ọlọ́run tí Fílípì 4:6, 7 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Bá a ṣe ń gbàdúrà sí Jèhófà ló jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe. Àlàáfíà tó wá látinú ọkàn yìí ló jẹ́ ká lè bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ nípa ìrètí àjíǹde. Òótọ́ ni pé ìjàǹbá ọkọ̀ òfúrufú náà gba ẹ̀mí ọmọ wa, síbẹ̀ a ṣì ń rántí àwọn àkókò alárinrin tá a ti jọ lò pa pọ̀. Ìyẹn la fi ń tu ara wa nínú.
“Nígbà tí àwọn tá a jọ jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ fún wa pé àwọn rí wa tí à ń fara balẹ̀ ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́ lórí tẹlifíṣọ̀n, ohun tá a sọ fún wọn ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà tí wọ́n gbà fún wa ló jẹ́ kó ṣeé ṣe. Ó dá mi lójú pé Jèhófà tì wá lẹ́yìn nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tí wọ́n sọ fún wa.”
Bí àwọn ohun tá a gbé yẹ̀wò yìí ṣe fi hàn, Ọlọ́run lè pèsè ìtùnú fún àwọn èèyàn tó ń dojú kọ onírúurú ìṣòro àti ìpèníjà. Ìwọ ńkọ́? Ìṣòro yòówù kó o dojú kọ nígbèésí ayé, ohun tó lè tù ẹ́ nínú nírú àkókò tó nira bẹ́ẹ̀ wà. * O ò ṣe kúkú yíjú sí Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́? Òun ni “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.”—2 Kọ́ríńtì 1:3.
^ ìpínrọ̀ 5 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.
^ ìpínrọ̀ 23 Tó o bá nílò ìrànlọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run, kó o sì rí ìtùnú, jọ̀wọ́ kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kó o kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó bá sún mọ́ ẹ jù lọ.