KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NI BÍBÉLÌ SỌ NÍPA ÀWỌN ÁŃGẸ́LÌ?
Bí Àwọn Áńgẹ́lì Ṣe Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́
Ọ̀rọ̀ àwa èèyàn máa ń jẹ àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ lọ́kàn gan-an, wọ́n sì ń fi taratara ṣe ohun tí Jèhófà ràn wọn. Nígbà tí Ọlọ́run dá ayé, àwọn áńgẹ́lì ‘fi ìdùnnú ké jáde, gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí hó yèè nínú ìyìn.’ (Jóòbù 38:4, 7) Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn áńgẹ́lì ti ń ‘fẹ́ láti wo’ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí ayé yìí.—1 Pétérù 1:11, 12.
Bíbélì fi hàn pé kí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn lè ṣẹ, àwọn ìgbà kan wà táwọn áńgẹ́lì ti dáàbò bo àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run tọkàntọkàn. (Sáàmù 34:7) Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀.
-
Nígbà tí Jèhófà fẹ́ pa ìlú Sódómù àti Gòmórà run, àwọn áńgẹ́lì ran Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè sá jáde.—Jẹ́nẹ́sísì 19:1, 15-26.
-
Ní ìlú Bábílónì ayé ìgbàanì, wọ́n dájọ́ ikú fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ Hébérù pé kí wọ́n sun wọ́n nínú iná ìléru, àmọ́ Ọlọ́run ‘rán áńgẹ́lì rẹ̀, ó sì gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀.’—Dáníẹ́lì 3:19-28.
-
Lẹ́yìn tí Dáníẹ́lì ọkùnrin olóòótọ́ ti wà nínú ihò kìnnìún láti òru mọ́jú, ó ṣàlàyé pé ohun tó jẹ́ kí òun bọ́ ni pé “Ọlọ́run mi rán áńgẹ́lì rẹ̀, ó sì dí ẹnu àwọn kìnnìún náà.”— Dáníẹ́lì 6:16, 22.
ÀWỌN ÁŃGẸ́LÌ TI ÀWỌN KRISTẸNI ÌGBÀANÌ LẸ́YÌN
Àwọn ìgbà kan wà tí àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run ran ìjọ Kristẹni ìgbàanì lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn nígbà tó pọn dandan bẹ́ẹ̀, kí ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn lè ṣẹ. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀.
-
Áńgẹ́lì kan ṣílẹ̀kùn ẹ̀wọ̀n, ó sì sọ fún àwọn àpọ́sítélì tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n pé kí wọ́n máa wàásù lọ nínú tẹ́ńpìlì.—Ìṣe 5:17-21.
-
Áńgẹ́lì kan sọ fún Fílípì ajíhìnrere pé kó lọ sí ọ̀nà aginjù, ìyẹn ọ̀nà tí wọ́n ń gbà lọ sí ìlú Gásà láti ìlú Jerúsálẹ́mù, kó lè wàásù fún ará Etiópíà kan tó lọ jọ́sìn ní Jerúsálẹ́mù.—Ìṣe 8:26-33.
-
Nígbà tó tásìkò lójú Ọlọ́run pé kí àwọn tí kì í ṣe Júù di Kristẹni, áńgẹ́lì kan fara han Kọ̀nílíù tó jẹ́ ọmọ ogun Róòmù nínú ìran, ó sì sọ fún un pé kó pe àpọ́sítélì Pétérù wá sí ilé rẹ̀.—Ìṣe 10:3-5.
-
Nígbà tí wọ́n fi àpọ́sítélì Pétérù sẹ́wọ̀n, áńgẹ́lì kan yọ sí i, ó sì mú un jáde kúrò lẹ́wọ̀n.—Ìṣe 12:1-11.
BÍ ÀWỌN ÁŃGẸ́LÌ ṢE LÈ RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́
Kò sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé Ọlọ́run ṣì ń lo àwọn áńgẹ́lì láti ran àwa èèyàn lọ́wọ́ lọ́nà ìyanu báyìí, bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú Bíbélì. Ṣùgbọ́n, Jésù sọ nípa àkókò wa yìí pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Ṣé o mọ̀ pé àwọn áńgẹ́lì ń darí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ ìwàásù yìí?
Ìwé Ìṣípayá fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì á máa fẹ̀sọ̀ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kárí ayé kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run àti ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe fún aráyé. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Mo sì rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run, ó sì ní ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti polongo gẹ́gẹ́ bí làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn, ó ń sọ ní ohùn rara pé: ‘Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ rẹ̀ ti dé, nítorí náà, ẹ jọ́sìn Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti àwọn ìsun omi.’” (Ìṣípayá 14:6, 7) Àwọn ìrírí tá à ń ní lásìkò yìí jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn áńgẹ́lì ń tì wá lẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tí à ń ṣe kárí ayé. Ká sòótọ́, tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá ronú pìwà dà tó sì wá sọ́dọ̀ Jèhófà, ńṣe ni ‘ìdùnnú máa ń sọ láàárín àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run.’—Lúùkù 15:10.
Kí ló máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí iṣẹ́ ìwàásù bá dópin? Nígbà yẹn, àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n jẹ́ “ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ń bẹ ní ọ̀run” máa jẹ́ alátìlẹyìn Jésù Kristi, tó jẹ́ Ọba àwọn ọba, láti ja “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè,” ìyẹn ogun Amágẹ́dọ́nì. (Ìṣípayá 16:14-16; 19:14-16) Àwọn áńgẹ́lì alágbára máa mú ìdájọ́ Ọlọ́run ṣẹ, bí Jésù Olúwa ṣe ń “mú ẹ̀san wá sórí àwọn . . . tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.”—2 Tẹsalóníkà 1:7, 8.
Torí náà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ọ̀rọ̀ rẹ jẹ àwọn áńgẹ́lì lọ́kàn gan-an. Wọ́n ń ronú nípa ohun tó máa ṣe àwọn tó ń fẹ́ sin Ọlọ́run láǹfààní. Jèhófà sì ti lò wọ́n lọ́pọ̀ ìgbà láti fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé lókun àti láti dáàbò bò wọ́n.—Hébérù 1:14.
Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa la ní ìpinnu pàtàkì kan láti ṣe. Ṣé a máa tẹ́tí sí ìhìn rere tá à ń polongo kárí ayé, ká sì ṣègbọràn sí i? Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè rẹ máa dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè jàǹfààní nínú ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́ tí àwọn áńgẹ́lì alágbára ń ṣe fáwọn èèyàn.