ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ October 2019

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti December 2-29, 2019 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

1919​—Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn

Ọdún 1919 ni Jèhófà fún àwọn èèyàn rẹ̀ lókun láti máa wàásù ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Àmọ́ kíyẹn tó lè ṣeé ṣe, àwọn ìyípadà kan gbọ́dọ̀ wáyé fún Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Ìdájọ́ Ọlọ́run—Ṣé Ọlọ́run Máa Ń Kìlọ̀ Fáwọn Èèyàn Kó Tó Ṣèdájọ́?

Jèhófà ń kìlọ̀ fún gbogbo aráyé lónìí pé “ìjì” kan ń bọ̀, tó le ju èyíkéyìí tí ẹ̀dá èèyàn tí ì gbọ́ rí lẹ́nu àwọn tó ń sọ bí ojú ọjọ́ ṣe máa rí. Báwo ló ṣe ń kìlọ̀ fún wọn?

Jẹ́ Kí Ọwọ́ Rẹ Dí Ní “Apá Ìgbẹ̀yìn Àwọn Ọjọ́” Yìí

Àwọn nǹkan wo ló máa ṣẹlẹ̀ tí “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí bá dópin? Kí ni Jèhófà sì fẹ́ ká máa ṣe bá a ṣe ń retí àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀?

Jẹ́ Olóòótọ́ Lákòókò “Ìpọ́njú Ńlá”

Kí ni Jèhófà máa fẹ́ ká ṣe nígbà “ìpọ́njú ńlá”? Báwo la ṣe lè múra sílẹ̀ nísinsìnyí ká lè jẹ́ olóòótọ́ lásìkò yẹn?

Kí Ni Jèhófà Máa Mú Kó O Dì?

Láyé àtijọ́, Jèhófà mú kó máa wu àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ó sì fún wọn lágbára láti ṣe é. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ran àwa náà lọ́wọ́ ká lè máa jọ́sìn rẹ̀?

Jèhófà Nìkan Ṣoṣo Ni Kó O Máa Jọ́sìn

A máa ṣàyẹ̀wò nǹkan méjì táá jẹ́ ká mọ̀ bóyá Jèhófà nìkan là ń jọ́sìn.