Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Arákùnrin Rutherford ń sọ àsọyé ní àpéjọ agbègbè Cedar Point, Ohio, lọ́dún 1919

1919​—Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn

1919​—Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn

NÍGBÀ tó fi máa di ọdún 1919, Ogun Àgbáyé Kìíní ti parí. Ìparí ọdún 1918 làwọn orílẹ̀-èdè tó ń jagun náà fòpin sí ìjà tí wọ́n ń bá ara wọn jà fún ohun tó lé lọ́dún mẹ́rin. Nígbà tó sì di January 18, 1919, wọ́n ṣe àpérò kan nílùú Paris láti mú kí àlàáfíà jọba. Àpérò yẹn ni wọ́n pè ní Paris Peace Conference. Ọ̀kan lára àwọn ohun tí wọ́n ṣe níbẹ̀ ni àdéhùn àlàáfíà, ìyẹn Treaty of Versailles, ìyẹn ló sì fòpin sí ogun táwọn orílẹ̀-èdè kan ń jà pẹ̀lú Jámánì. June 28, 1919 ni wọ́n sì buwọ́ lu ìwé àdéhùn náà.

Níbi àpérò tí wọ́n ṣe yẹn, wọ́n tún dá àjọ kan tó ń jẹ́ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀. Ìdí tí wọ́n sì fi dá a sílẹ̀ ni pé wọ́n fẹ́ kí “àjọṣe tó gún régé wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, kí àlàáfíà àti ààbò sì wà níbi gbogbo láyé.” Ọ̀pọ̀ lára àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ló sì ti àjọ náà lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, Ìgbìmọ̀ Àpapọ̀ Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Kristi ní Amẹ́ríkà gbà pé àjọ náà ń ‘ṣojú Ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé.’ Kódà, wọ́n fi àwọn aṣojú ránṣẹ́ sí àpérò Paris Peace Conference, ọ̀kan lára àwọn aṣojú náà sì sọ pé ìpàdé yẹn máa mú kí “ìgbà ọ̀tun dé bá aráyé.”

Òótọ́ ni pé ìgbà ọ̀tun bẹ̀rẹ̀, àmọ́ kì í ṣe látọwọ́ àwọn tó kóra jọ síbi àpérò yẹn. Ọdún 1919 ni Jèhófà fún àwọn èèyàn rẹ̀ lókun láti máa wàásù ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, ìgbà yẹn gan-an ni ìgbà ọ̀tun wọlé dé. Àmọ́ kíyẹn tó lè ṣeé ṣe, àwọn ìyípadà kan gbọ́dọ̀ wáyé fún Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

ÌPINNU KAN TÓ ṢÒRO

Joseph F. Rutherford

Ọjọ́ Saturday, January 4, 1919 ni wọ́n ṣètò pé wọ́n máa ṣe ìpàdé ọdọọdún àjọ Watch Tower Bible and Tract Society, tí wọ́n á sì dìbò yan àwọn tó máa jẹ́ olùdarí. Nígbà yẹn, wọ́n ju Arákùnrin Joseph F. Rutherford tó ń múpò iwájú láàárín àwa èèyàn Jèhófà sẹ́wọ̀n láìṣẹ̀ láìrò nílùú Atlanta, Georgia, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà pẹ̀lú àwọn méje míì. Ìbéèrè náà ni pé, Ṣé wọ́n ṣì máa dìbò yan àwọn arákùnrin tó wà lẹ́wọ̀n? Àbí wọ́n máa yan àwọn míì rọ́pò wọn?

Evander J. Coward

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ẹ̀wọ̀n ni Arákùnrin Rutherford wà, ó ṣì ń ronú nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ètò Ọlọ́run. Ó mọ̀ pé àwọn kan ti ń ronú àtifi ẹlòmíì jẹ ààrẹ Watch Tower. Torí náà, ó kọ̀wé sí àwọn tó péjọ sí ìpàdé náà, ó sì dámọ̀ràn pé kí wọ́n yan Arákùnrin Evander J. Coward sípò ààrẹ. Arákùnrin Rutherford sọ pé Arákùnrin Coward jẹ́ “ẹni jẹ́jẹ́, onílàákàyè, ó sì fi ara ẹ̀ jìn fún iṣẹ́ Olúwa.” Àmọ́, ọ̀pọ̀ lára àwọn ará ló ronú pé kí wọ́n sún ìpàdé náà síwájú, ìyẹn lẹ́yìn oṣù mẹ́fà. Àwọn agbẹjọ́rò fáwọn ará tó wà lẹ́wọ̀n náà sì fara mọ́ ìpinnu yẹn. Àmọ́, ṣe ni inú ń bí àwọn kan bí ìjíròrò náà ṣe ń lọ.

Richard H. Barber

Nígbà tó yá, ọ̀kan lára àwọn arákùnrin tó wà níbẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ kan tí Arákùnrin Richard H. Barber gbà pé ó pẹ̀tù sọ́rọ̀ náà. Ohun tí arákùnrin náà sọ ni pé: “Mi ò kì í ṣe amòfin, àmọ́ tó bá dọ̀rọ̀ ká ṣe ohun tó tọ́ àtèyí tó yẹ, mo mọ ohun tí adúróṣinṣin máa ṣe. Inú kan ni Ọlọ́run fẹ́ ká fi máa bára wa lò. Torí náà, mi ò rò pé nǹkan míì wà tó yẹ ká ṣe ju pé ká dìbò, ká sì tún Arákùnrin Rutherford yàn sípò ààrẹ.”​—Sm. 18:25.

Alexander H. Macmillan

Arákùnrin A. H. Macmillan tóun náà wà lẹ́wọ̀n rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kejì. Ó sọ pé Arákùnrin Rutherford kan ògiri ẹ̀wọ̀n tóun wà, ó sì sọ pé, “Nawọ́ ẹ síta.” Arákùnrin Rutherford wá fún un ní ìwé kékeré kan. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí Arákùnrin Macmillan ka ìwé náà ló ti mọ ohun tó túmọ̀ sí. Ohun tó wà nínú ìwé náà ni: “RUTHERFORD WISE VAN BARBER ANDERSON BULLY ÀTI SPILL OLUDARÍ MẸ́TA ÀKỌ́KỌ́ Ń KÍ YÍN.” Ìyẹn túmọ̀ sí pé wọ́n ti tún gbogbo àwọn olùdarí náà yàn sípò àti pé Arákùnrin Joseph Rutherford àti Arákùnrin William Van Amburgh ti pa dà sípò tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀. Torí náà, Arákùnrin Rutherford ló ṣì máa jẹ́ ààrẹ.

WỌ́N DÁ WỌN SÍLẸ̀!

Nígbà tí àwọn arákùnrin mẹ́jọ náà ṣì wà lẹ́wọ̀n, Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n buwọ́ lu ìwé kan kí ìjọba lè dá àwọn arákùnrin tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n sílẹ̀. Àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méje (700,000) ló buwọ́ lu ìwé náà. Lọ́jọ́ Wednesday, March 26, 1919, wọ́n dá Arákùnrin Rutherford àtàwọn yòókù sílẹ̀ kí àwọn ará yẹn tiẹ̀ tó mú ìwé náà dé ọ̀dọ̀ ìjọba.

Nígbà tí Arákùnrin Rutherford ń bá àwọn tó wá kí i káàbọ̀ sọ̀rọ̀, ó ní: ‘Ó dá mi lójú pé ṣe lohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ń múra gbogbo wa sílẹ̀ fún àwọn àdánwò míì tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. Kì í ṣe torí pé ẹ fẹ́ kí wọ́n dá wa sílẹ̀ lẹ́wọ̀n nìkan lẹ ṣe ń tiraka, kékeré nìyẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, torí kẹ́ ẹ lè gbèjà Òtítọ́, kẹ́ ẹ sì mú ìyìn bá Jèhófà lẹ ṣe ń tiraka, àwọn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ sì ń rí ìbùkún gbà.’

Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí fi hàn pé Jèhófà lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ náà, ó sì ń tọ́ àwọn ará wa sọ́nà. Ní May 14, 1919, ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn dájọ́ pé: ‘Àwọn tó gbẹ́jọ́ wọn tẹ́lẹ̀ ṣègbè, torí náà, a fagi lé ìdájọ́ tí wọ́n ṣe.’ Ìdájọ́ tí wọ́n tún ṣe yìí dáa gan-an. Kí nìdí? Ìdí ni pé ẹ̀sùn ńláńlá ni wọ́n fi kan àwọn ará yẹn. Ká sọ pé wọ́n kàn dárí jì wọ́n ni tàbí kí wọ́n dín ìyà tí wọ́n fẹ́ fi jẹ wọ́n kù, ó ṣì máa wà lákọọ́lẹ̀ pé wọ́n hùwà ọ̀daràn. Àmọ́ torí pé wọ́n ti yí ìdájọ́ yẹn pa dà, wọn ò fẹ̀sùn kankan kàn wọ́n mọ́, kódà wọ́n tún fagi lé àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n tẹ́lẹ̀. Torí náà, ó ṣeé ṣe fún Judge Rutherford láti máa bá iṣẹ́ amòfin rẹ̀ lọ, ìyẹn sì mú kó máa gbèjà àwọn èèyàn Jèhófà ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Amẹ́ríkà, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n dá a sílẹ̀ lẹ́wọ̀n.

WỌN Ò YÉ WÀÁSÙ

Arákùnrin Macmillan sọ pé: “A ò kàn ní jókòó gẹlẹtẹ ká wá káwọ́ gbera láì ṣe nǹkan kan, ká sì máa retí pé Olúwa máa mú wa lọ sọ́run. A rí i pé a gbọ́dọ̀ wádìí ohun tí Olúwa fẹ́ ká ṣe gan-an.”

Àmọ́ kò ṣeé ṣe fáwọn arákùnrin tó ń ṣiṣẹ́ ní oríléeṣẹ́ láti tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tí wọ́n ti fi ọ̀pọ̀ ọdún ṣe. Kí nìdí? Ìdí ni pé lásìkò táwọn arákùnrin yẹn wà lẹ́wọ̀n, wọ́n ti ba gbogbo nǹkan tí wọ́n fi ń tẹ̀wé jẹ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn bà wọ́n nínú jẹ́ gan-an, kódà àwọn kan tiẹ̀ ronú pé iṣẹ́ ìwàásù ti parí nìyẹn.

Ìbéèrè náà ni pé ṣé àwọn èèyàn ṣì nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń wàásù? Kí wọ́n lè mọ̀, Arákùnrin Rutherford pinnu pé òun máa sọ àsọyé kan, wọ́n á sì pe àwọn èèyàn láti wá gbọ́ ọ. Arákùnrin Macmillan sọ pé: “Tá ò bá rẹ́nì kankan, á jẹ́ pé iṣẹ́ ìwàásù ti parí nìyẹn.”

Ìwé ìròyìn tí wọ́n fi polongo àsọyé Arákùnrin Rutherford nílùú Los Angeles, California, lọ́dún 1919. Àkọlé àsọyé náà ni “Ìrètí Tó Wà fún Aráyé Tí À Ń Pọ́n Lójú”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara Arákùnrin Rutherford ò yá rárá, síbẹ̀ ní Sunday, May 4, 1919, ó sọ àsọyé tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní “Ìrètí Tó Wà fún Aráyé Tí À Ń Pọ́n Lójú” ní Los Angeles, California. Àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ (3,500) ló wá síbẹ̀, kódà ṣe ni wọ́n ní káwọn kan pa dà wá lọ́jọ́ kejì torí kò sáyè mọ́. Lọ́jọ́ kejì, ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ (1,500) ló tún wá. Ìdáhùn náà ti ṣe kedere sáwọn ará, àwọn èèyàn ṣì nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù wa!

Ohun táwọn ará ṣe lẹ́yìn ìyẹn ló di ìpìlẹ̀ báwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń wàásù títí dòní.

WỌ́N ṢE OHUN TÓ MÚ KÍ IṢẸ́ NÁÀ GBÒÒRÒ

Ilé Ìṣọ́ August 1, 1919, kéde pé a máa ṣe àpéjọ agbègbè kan níbẹ̀rẹ̀ oṣù September ní Cedar Point, Ohio. Arákùnrin Clarence B. Beaty nílùú Missouri sọ pé: “Gbogbo wa ló ń ṣe bíi pé ká ti wà ńbẹ̀.” Àwọn ará tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) lọ ló wá síbẹ̀, iye yẹn sì kọjá ohun tí wọ́n retí. Ohun míì tó tún múnú wọn dùn ni pé àwọn tó lé ní ọgọ́rùn-ún méjì (200) ló ṣèrìbọmi nínú odò kan tí wọ́n ń pè ní Lake Erie.

Èèpo ẹ̀yìn ìwé ìròyìn The Golden Age tá a kọ́kọ́ tẹ̀ jáde, ìyẹn ẹ̀dà October 1, 1919

Ní ọjọ́ karùn-ún ìpàdé agbègbè náà, ìyẹn ní September 5, 1919, Arákùnrin Rutherford sọ àsọyé kan tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Àsọyé fún Àwọn Alájọṣiṣẹ́ Wa.” Nínú àsọyé yẹn, ó kéde pé a ti mú ìwé tuntun kan jáde, orúkọ rẹ̀ ni The Golden Age. * Ó sọ pé ìwé ìròyìn yìí á máa “sọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ tó ṣe pàtàkì, á sì tún máa ṣàlàyé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti ìdí tí wọ́n fi ń ṣẹlẹ̀.”

Wọ́n gba gbogbo Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níyànjú pé kí wọ́n máa fìtara lo ìwé ìròyìn yẹn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Nínú lẹ́tà tí wọ́n fi ṣàlàyé bí wọ́n á ṣe fi ìwé ìròyìn náà wàásù, wọ́n sọ pé: “Kí gbogbo àwọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run máa rántí pé àǹfààní ńlá làwọn ní bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run, kí wọ́n sapá láti kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ńlá yìí, kí wọ́n má sì jáfara.” Ẹ wá wo bí ọ̀pọ̀ àwọn ará ṣe dáhùn sí ìkésíni náà! Nígbà tó máa fi di December, àwọn ará ti gba àsansílẹ̀ tó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta (50,000) lọ fún ìwé ìròyìn náà.

Àwọn arákùnrin kan ní Brooklyn, New York, dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkọ̀ kan tó kó ìwé ìròyìn The Golden Age

Nígbà tí ọdún 1919 fi máa parí, Jèhófà ti ṣètò àwọn èèyàn rẹ̀ lákọ̀tun, ó sì fún wọn lókun láti máa bá iṣẹ́ náà lọ. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ló ti ní ìmúṣẹ. Lára ẹ̀ lèyí tí Málákì 3:​1-4 sọ tẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run máa yẹ àwọn èèyàn rẹ̀ wò, á sì yọ́ wọn mọ́. Bákan náà, Jèhófà ti dá àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ ní ìgbèkùn “Bábílónì Ńlá,” Jésù sì ti yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà. * (Ìfi. 18:​2, 4; Mát. 24:45) Ó ṣe kedere pé Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn ti ṣe tán báyìí láti ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà fẹ́ kí wọ́n ṣe.

^ ìpínrọ̀ 22 Nígbà tó dọdún 1937, a yí orúkọ ìwé ìròyìn The Golden Age Consolation, nígbà tó sì dọdún 1946, a bẹ̀rẹ̀ sí í pè é ní Jí!