Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ó ṣe pàtàkì pé káwọn èèyàn gbọ́ ìkìlọ̀ bí “ìjì” ìdájọ́ Ọlọ́run ṣe ń sún mọ́lé!

Ìdájọ́ Ọlọ́run—Ṣé Ọlọ́run Máa Ń Kìlọ̀ Fáwọn Èèyàn Kó Tó Ṣèdájọ́?

Ìdájọ́ Ọlọ́run—Ṣé Ọlọ́run Máa Ń Kìlọ̀ Fáwọn Èèyàn Kó Tó Ṣèdájọ́?

ẸNÌ kan tó máa ń sọ bí ojú ọjọ́ ṣe máa rí kíyè sí i pé ìjì burúkú kan máa tó jà ní agbègbè kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń gbé. Torí pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ ẹni náà lógún, ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti kìlọ̀ fáwọn èèyàn náà kó tó pẹ́ jù.

Lọ́nà kan náà, Jèhófà ń kìlọ̀ fún gbogbo aráyé lónìí pé “ìjì” kan ń bọ̀, tó le ju èyíkéyìí tí ẹ̀dá èèyàn tíì gbọ́ rí lẹ́nu àwọn tó ń sọ bí ojú ọjọ́ ṣe máa rí. Báwo ló ṣe ń kìlọ̀ fún wọn? Kí ló mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa ń ṣe sùúrù fún àwọn èèyàn kó tó mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ? Ká lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ìkìlọ̀ kan tí Jèhófà ti fún àwọn èèyàn nígbà àtijọ́.

ỌLỌ́RUN KÌLỌ̀ ṢÁÁJÚ

Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé òun máa mú ìdájọ́ tó dà bí “ìjì” wá, táá pa gbogbo àwọn tí kò pa òfin òun mọ́. (Òwe 10:25; Jer. 30:23) Ọ̀pọ̀ ọdún kí ìdájọ́ náà tó wáyé ni Jèhófà ti máa ń sọ fáwọn èèyàn náà, ó tún sọ ohun tí wọ́n máa ṣe tí wọ́n bá fẹ́ yè bọ́. (2 Ọba 17:12-15; Neh. 9:29, 30) Kí àwọn èèyàn náà lè mọ ohun tí wọ́n á ṣe, Jèhófà sábà máa ń rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí wọn, kí wọ́n lè mọ bí ìkìlọ̀ náà ṣe jẹ́ kánjúkánjú tó.”​—Émọ́sì 3:7.

Ọ̀kan lára àwọn olóòótọ́ tí Ọlọ́run lò láti kìlọ̀ fáwọn èèyàn ni Nóà. Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi kìlọ̀ fáwọn èèyàn burúkú tí ìṣekúṣe àti ìwà ipá ti wọ̀ lẹ́wù pé Ìkún Omi kan ń bọ̀. (Jẹ́n. 6:9-13, 17) Ó tún jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí wọ́n máa ṣe tí wọ́n bá fẹ́ rí ìgbàlà, abájọ tí Bíbélì fi pè é ní “oníwàásù òdodo.””​—2 Pét. 2:5.

Nóà sapá gan-an láti kìlọ̀ fáwọn èèyàn ṣáájú Ìkún Omi, àmọ́ wọn ò kọbi ara sí ìkìlọ̀ náà. Wọn ò ní ìgbàgbọ́ rárá, ìdí nìyẹn tí Ìkún Omi yẹn “fi dé, tó sì gbá gbogbo wọn lọ.” (Mát. 24:39; Héb. 11:7) Bí Ìkún Omi yẹn ṣe ń gbá wọn lọ, wọn ò lè sọ pé Ọlọ́run ò kìlọ̀ fáwọn tó.

Àwọn ìgbà míì wà tí Ọlọ́run kìlọ̀ fáwọn èèyàn nígbà tó ku díẹ̀ kí “ìjì” ìdájọ́ rẹ̀ dé. Àmọ́ ó ṣì rí i dájú pé òun fún àwọn èèyàn náà ní àsìkò tó tó láti gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ti kìlọ̀ fáwọn ará Íjíbítì ṣáájú kí ọ̀kọ̀ọ̀kan Ìyọnu Mẹ́wàá náà tó wáyé. Àpẹẹrẹ kan ni bó ṣe rán Mósè àti Áárónì pé kí wọ́n lọ kìlọ̀ fún Fáráò àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nípa ìyọnu keje, ìyẹn òjò yìnyín. Torí pé ọjọ́ kan ṣáájú kí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn tó wáyé ló kìlọ̀ fún wọn, ṣé a wá lè sọ pé Ọlọ́run fún wọn ní àsìkò tó tó kí wọ́n lè gbé ìgbésẹ̀ láti rí ìgbàlà? Ohun tí Bíbélì sọ ni pé: “Àwọn tó bẹ̀rù ọ̀rọ̀ Jèhófà nínú àwọn ìránṣẹ́ Fáráò yára mú àwọn ìránṣẹ́ wọn àtàwọn ẹran ọ̀sìn wọn wọnú ilé, àmọ́ àwọn tí kò ka ọ̀rọ̀ Jèhófà sí fi àwọn ìránṣẹ́ wọn àtàwọn ẹran ọ̀sìn wọn sílẹ̀ nínú oko.” (Ẹ́kís. 9:18-21) Ó ṣe kedere pé Jèhófà kìlọ̀ dáadáa, ìyẹn sì mú kó ṣeé ṣe fáwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ láti gbé ìgbésẹ̀ kí ìyà má bàa jẹ wọ́n.

Bákan náà, kí ìyọnu kẹwàá tó wáyé ni Jèhófà ti kìlọ̀ fún Fáráò àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Àmọ́ wọn ò dáhùn, torí pé olóríkunkun ni wọ́n. (Ẹ́kís. 4:22, 23) Ìdí nìyẹn tí gbogbo àkọ́bí wọn tó jẹ́ ọkùnrin fi kú. Ó mà ṣe o! (Ẹ́kís. 11:4-10; 12:29) Ṣé wọ́n ní àsìkò tó tó láti gbé ìgbésẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni! Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Mósè sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ìyọnu kẹwàá yẹn, ó sì sọ ohun tí wọ́n máa ṣe kí wọ́n lè dáàbò bo ìdílé wọn. (Ẹ́kís. 12:21-28) Àwọn mélòó ló fetí sí ìkìlọ̀ tí wọ́n gbọ́ yìí? Àwọn kan fojú bù ú pé mílíọ̀nù mẹ́ta èèyàn ló la ìparun yẹn já tí wọ́n sì kúrò ní Íjíbítì. Lára wọn ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti “oríṣiríṣi èèyàn tó pọ̀ rẹpẹtẹ” tí wọn kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, títí kan àwọn ará Íjíbítì.—Ẹ́kís. 12:38; àlàyé ìsàlẹ̀.

Bá a ṣe rí i nínú àwọn àpẹẹrẹ yìí, gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń rí i dájú pé òun fún àwọn èèyàn ní àsìkò tó tó láti gbé ìgbésẹ̀ lórí ìkìlọ̀ tó fún wọn. (Diu. 32:4) Kí nìdí tó fi máa ń ṣe bẹ́ẹ̀? Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé Jèhófà “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà.” (2 Pét. 3:9) Ọ̀rọ̀ wọn jẹ Ọlọ́run lógún, torí náà ó wù ú pé kí wọ́n ronú pìwà dà, kí wọ́n sì ṣiṣẹ́ lórí ìkìlọ̀ tó fún wọn kí ìdájọ́ rẹ̀ tó dé.”​—Àìsá. 48:17, 18; Róòmù 2:4.

Ẹ TẸ́TÍ SÍ ÌKÌLỌ̀ ỌLỌ́RUN

Bákan náà lónìí, ó ṣe pàtàkì káwọn èèyàn ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ Ọlọ́run tá à ń wàásù kárí ayé. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa pa ayé búburú yìí run nígbà “ìpọ́njú ńlá.” (Mát. 24:21) Jésù jẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ tí ìparun yẹn bá ti ń sún mọ́lé, kí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn má bàa báwọn lójijì. Àwọn nǹkan tí Jésù sọ ló sì ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé lónìí.”​—Mát. 24:3-12; Lúùkù 21:10-13.

Torí náà, Jèhófà ń rọ gbogbo èèyàn pé kí wọ́n wá sin òun, kí wọ́n má bàa pa run. Ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn tó bá fetí sí òun gbádùn ayé wọn nísinsìnyí, kí wọ́n sì tún gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún nínú ayé tuntun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. (2 Pét. 3:13) Jèhófà fẹ́ kí àwọn èèyàn nígbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí òun, ìdí nìyẹn tó fi ṣètò pé ká máa wàásù “ìhìn rere Ìjọba” náà káwọn èèyàn lè rí ìgbàlà. Ìhìn rere yìí ni Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé a máa ‘wàásù ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè.’ (Mát. 24:14) Ọlọ́run ti ṣètò àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ láti máa ‘jẹ́rìí’ tàbí wàásù fáwọn èèyàn ní ọgọ́rùn-ún méjì ó lé ogójì (240) ilẹ̀. Ó wu Jèhófà pé tó bá ṣeé ṣe kí gbogbo èèyàn ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ òun, kí wọ́n lè yè bọ́ nínú ìdájọ́ rẹ̀ tó dà bí “ìjì” tó ń bọ̀ láìpẹ́.”​—Sef. 1:14, 15; 2:2, 3.

Níbi tá a bọ́rọ̀ dé yìí, kò yẹ ká tún máa béèrè bóyá Ọlọ́run ń fún àwọn èèyàn lásìkò tó tó láti ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ tó ń fún wọn. Ó ṣe kedere pé ó ń ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó yẹ ká máa béèrè ni pé: Ṣé àwọn èèyàn máa ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ Ọlọ́run ní báyìí tí wọ́n ṣì láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀? Torí náà, ǹjẹ́ kí àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa bá a lọ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè la ìparun tó ń bọ̀ sórí ayé búburú yìí já.