Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 41

Jẹ́ Olóòótọ́ Lákòókò “Ìpọ́njú Ńlá”

Jẹ́ Olóòótọ́ Lákòókò “Ìpọ́njú Ńlá”

“Ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ adúróṣinṣin sí i! Jèhófà ń dáàbò bo àwọn olóòótọ́.”​—SM. 31:23.

ORIN 129 A Ó Máa Fara Dà Á Nìṣó

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. (a) Kí làwọn aṣáájú orílẹ̀-èdè máa kéde láìpẹ́? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká wá ìdáhùn sí?

LỌ́JỌ́ kan, àwọn aṣáájú orílẹ̀-èdè máa kéde pé “àlàáfíà àti ààbò” tí wọ́n ti ń fojú sọ́nà fún tipẹ́tipẹ́ ti dé báyìí. Wọ́n tiẹ̀ lè sọ pé ìsinsìnyí gan-an ni àlàáfíà ṣẹ̀ṣẹ̀ jọba láyé. Wọ́n máa fẹ́ ká gbà pé àwọn ti rí ojútùú sí gbogbo ìṣòro tó ń bá aráyé fínra. Ó mà ṣé o, wọn ò mọ̀ pé àwọn ò ní lè ṣe nǹkan kan sóhun tó máa ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e. Kí nìdí? Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn, . . . wọn ò sì ní yè bọ́ lọ́nàkọnà.”​—1 Tẹs. 5:3.

2 Àwọn ìbéèrè pàtàkì kan wà tó yẹ ká wá ìdáhùn sí. Àkọ́kọ́, kí ló máa ṣẹlẹ̀ lákòókò “ìpọ́njú ńlá”? Ìkejì, kí ni Jèhófà máa fẹ́ ká ṣe nígbà yẹn? Àti ìkẹta, báwo la ṣe lè múra sílẹ̀ nísinsìnyí ká lè jẹ́ olóòótọ́ lásìkò ìpọ́njú ńlá?​—Mát. 24:21.

KÍ LÓ MÁA ṢẸLẸ̀ LÁKÒÓKÒ “ÌPỌ́NJÚ ŃLÁ”?

3. Bó ṣe wà nínú Ìfihàn 17:5, 15-18, báwo ni Ọlọ́run ṣe máa pa “Bábílónì Ńlá” run?

3 Ka Ìfihàn 17:5, 15-18. Àbí ẹ ò rí nǹkan, “Bábílónì Ńlá” máa pa run! Bá a ṣe sọ ṣáájú, àwọn orílẹ̀-èdè ò ní lè ṣe nǹkan kan sí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn. Kí nìdí? Ìdí ni pé “Ọlọ́run [máa] fi sí ọkàn wọn láti ṣe ohun tí òun fẹ́.” Kí ni Ọlọ́run fẹ́? Ó fẹ́ pa àpapọ̀ àwọn ìsìn èké ayé yìí run títí kan Kristẹndọm. * Ọlọ́run máa fi ohun tó fẹ́ ṣe sínú ọkàn “ìwo mẹ́wàá” ti “ẹranko aláwọ̀ rírẹ̀dòdò” náà. Ìwo mẹ́wàá náà dúró fún gbogbo ìjọba ayé tó ń ti “ẹranko” yìí lẹ́yìn, ìyẹn Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. (Ìfi. 17:3, 11-13; 18:8) Nígbà táwọn ìjọba ayé bá gbéjà ko ẹ̀sìn èké, ìyẹn á fi hàn pé ìpọ́njú ńlá ti bẹ̀rẹ̀. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí máa wáyé lójijì, á sì lágbára gan-an débi pé kò sẹ́ni tí kò ní mọ̀ ọ́n lára.

4. (a) Kí ló ṣeé ṣe káwọn orílẹ̀-èdè sọ pé ó mú káwọn pa ẹ̀sìn èké run? (b) Kí làwọn tó ti ń ṣe ẹ̀sìn èké tẹ́lẹ̀ máa ṣe?

4 A ò mọ ohun táwọn orílẹ̀-èdè máa sọ pé àwọn fẹ́ tìtorí ẹ̀ pa Bábílónì Ńlá run. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n sọ pé àwọn ẹ̀sìn ni kò jẹ́ kí ìlú fara rọ àti pé ìgbà gbogbo ni wọ́n máa ń tojú bọ ọ̀rọ̀ òṣèlú. Wọ́n sì lè sọ pé ọrọ̀ àti dúkìá tí wọ́n kó jọ ti pọ̀ jù. (Ìfi. 18:3, 7) Àmọ́ ti pé wọ́n máa pa ẹ̀sìn èké run kò túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn èké ló máa pa run. Dípò bẹ́ẹ̀, ètò ẹ̀sìn lápapọ̀ ni wọ́n máa pa run. Tí gbogbo ẹ̀sìn èké bá ti pa run, àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn yẹn tẹ́lẹ̀ á wá rí i pé ńṣe làwọn olórí ẹ̀sìn kàn tan àwọn jẹ, wọ́n sì lè sọ pé àwọn ò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ẹ̀sìn.

5. Kí ni Jèhófà ṣèlérí nípa ìpọ́njú ńlá, kí sì nìdí?

5 Bíbélì ò sọ bí àkókò tí wọ́n máa fi pa Bábílónì Ńlá ṣe máa gùn tó, àmọ́ ó dá wa lójú pé kò ní pẹ́ rárá. (Ìfi. 18:10, 21) Jèhófà ti ṣèlérí pé òun máa “dín àwọn ọjọ́ náà kù,” ìyẹn àsìkò tí ìpọ́njú ńlá máa gbà kí ìsìn tòótọ́ àti “àwọn àyànfẹ́” lè là á já. (Máàkù 13:19, 20) Àmọ́, kí ni Jèhófà máa fẹ́ ká ṣe láàárín ìgbà tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀ sí ìgbà tí ogun Amágẹ́dọ́nì máa jà?

ÌSÌN TÒÓTỌ́ NI KÓ O MÁA ṢE

6. Yàtọ̀ sí pé ká má ṣe ẹ̀sìn èké mọ́, kí la tún gbọ́dọ̀ ṣe?

6 Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, Jèhófà fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ya ara wọn sọ́tọ̀ pátápátá kúrò nínú Bábílónì Ńlá. Àmọ́, èyí kọjá kéèyàn kàn sọ pé òun ò ṣe ẹ̀sìn èké mọ́. A gbọ́dọ̀ pinnu pé ìjọsìn Jèhófà làá máa ṣe kódà tí kò bá tiẹ̀ rọrùn. Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà méjì tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀.

Ẹ má ṣe jẹ́ ká máa pa ìpàdé jẹ kódà lásìkò tí nǹkan nira (Wo ìpínrọ̀ 7) *

7. (a) Kí la lè ṣe táá fi hàn pé à ń fọwọ́ gidi mú àwọn ìlànà òdodo Jèhófà? (b) Bó ṣe wà nínú Hébérù 10:24, 25, kí nìdí tó fi yẹ ká fọwọ́ gidi mú ìpàdé, ní pàtàkì lásìkò tá a wà yìí?

7 Àkọ́kọ́, ìlànà òdodo Jèhófà ni kó o máa tẹ̀ lé. A ò gbọ́dọ̀ fàyè gba ìwàkiwà tàbí àwọn àṣàkaṣà tó kúnnú ayé yìí. Bí àpẹẹrẹ, a kì í fàyè gba ìṣekúṣe èyíkéyìí títí kan kí ọkùnrin máa fẹ́ ọkùnrin tàbí kí obìnrin máa fẹ́ obìnrin. (Mát. 19:4, 5; Róòmù 1:26, 27) Ìkejì, a gbọ́dọ̀ máa pé jọ pẹ̀lú àwọn ará wa láti jọ́sìn Jèhófà. Ibi yòówù kó jẹ́, yálà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, láwọn ilé àdáni tàbí ní bòókẹ́lẹ́, ká ṣáà rí i pé à ń pésẹ̀ déédéé. Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, a ò ní jẹ́ kí ohunkóhun mú ká ṣíwọ́ àtimáa jọ́sìn Jèhófà pẹ̀lú àwọn ará wa. Kódà ní báyìí, ó yẹ ká fọwọ́ gidi mú ìpàdé lílọ “ní pàtàkì jù lọ bí [a] ṣe ń rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.”​—Ka Hébérù 10:24, 25.

8. Ìyípadà wo ló ṣeé ṣe kó bá iṣẹ́ ìwàásù wa?

8 Nígbà ìpọ́njú ńlá, ó ṣeé ṣe kí ohun tá à ń wàásù yí pa dà. Ní báyìí, ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run là ń kéde, a sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Àmọ́ tó bá dìgbà yẹn, ìkéde gbankọgbì tó dà bí òkúta yìnyín làá máa kéde. (Ìfi. 16:21) Àá máa kéde pé ayé Sátánì yìí máa tó pa run. Kí làá máa wàásù gan-an, ọ̀nà wo la sì máa gbà ṣe é? Àfi ká dúró dìgbà yẹn. A lè wá béèrè pé, ṣé ọ̀nà tá a gbà ń wàásù bọ̀ láti ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn náà làá máa lò? Àbí ọ̀nà míì la máa gbé e gbà? Ó dìgbà yẹn ká tó mọ̀. Ọ̀nà yòówù kó jẹ́, àǹfààní ńlá ló máa jẹ́ láti fìgboyà kéde ìdájọ́ Jèhófà!​—Ìsík. 2:3-5.

9. Kí làwọn orílẹ̀-èdè máa ṣe, àmọ́ kí ló dá wa lójú?

9 Ó ṣeé ṣe kí ìkéde wa bí àwọn orílẹ̀-èdè nínú, kí wọ́n sì gbìyànjú láti pa wá lẹ́nu mọ́ pátápátá. Ní báyìí, Jèhófà ló ń tì wá lẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa, òun náà ló sì máa ràn wá lọ́wọ́ tó bá dìgbà yẹn. Ó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa fún wa lágbára láti ṣe iṣẹ́ náà láṣeyanjú.—Míkà 3:8.

MÚRA SÍLẸ̀ DE ÌGBÀ TÍ WỌ́N MÁA GBÉJÀ KO ÀWA ÈÈYÀN ỌLỌ́RUN

10. Lúùkù 21:25-28 ṣe sọ tẹ́lẹ̀, kí ni ọ̀pọ̀ èèyàn máa ṣe nígbà ìpọ́njú ńlá?

10 Ka Lúùkù 21:25-28. Nígbà ìpọ́njú ńlá, ó máa ya àwọn èèyàn lẹ́nu gan-an tí wọ́n bá rí i pé gbogbo ohun tí wọ́n gbára lé bẹ̀rẹ̀ sí í dojú rú, wọ́n á sì rí i pé àwọn nǹkan yẹn ò láyọ̀ lé. “Ìdààmú” máa bá wọn, wọ́n á sì máa bẹ̀rù pé àwọn lè kú torí pé irú àwọn nǹkan yẹn ò ṣẹlẹ̀ rí. (Sef. 1:14, 15) Nǹkan máa nira gan-an fáwa ìránṣẹ́ Jèhófà nígbà yẹn. Torí pé a kì í ṣe apá kan ayé, wọ́n tún máa fojú pọ́n wa. Kódà, ó ṣeé ṣe ká má ní àwọn ohun ìgbẹ́mìíró àtàwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì.

11. (a) Kí nìdí tí wọ́n á fi dájú sọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà? (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká bẹ̀rù ìpọ́njú ńlá?

11 Bí ìpọ́njú ńlá yẹn ṣe ń bá a lọ, àwọn tí ẹ̀sìn wọn ti pa run máa kíyè sí i pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan la ṣẹ́ kù, ìyẹn sì máa múnú bí wọn. Wọ́n máa jẹ́ kí gbogbo ayé mọ̀ pé inú ń bí àwọn, kódà wọ́n á gbé e sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Inú máa bí àwọn orílẹ̀-èdè àti Sátánì tó ń darí wọn, wọ́n á sì kórìíra wa torí pé ẹ̀sìn tiwa nìkan ló kù. Ohun tí wọ́n ní lọ́kàn ni pé káwọn pa gbogbo ẹ̀sìn run, àmọ́ wọn ò ní ríyẹn ṣe. Torí náà, wọ́n máa dájú sọ wá. Ìgbà táwọn orílẹ̀-èdè bá kóra jọ láti bá wa jà ni Bíbélì sọ pé wọ́n jẹ́ Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù. * Wọ́n máa fi gbogbo agbára wọn gbéjà ko àwa èèyàn Jèhófà. (Ìsík. 38:2, 14-16) Ìyẹn sì lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn torí àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀, pàápàá torí pé a ò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bí nǹkan ṣe máa rí. Àmọ́ ohun kan dájú, a ò ní bẹ̀rù ìpọ́njú ńlá torí pé Jèhófà máa fún wa láwọn ìtọ́ni táá gbà wá là. (Sm. 34:19) A máa ‘nàró ṣánṣán, àá sì gbé orí wa sókè, torí a mọ̀ pé ìdáǹdè wa ti sún mọ́lé.’ *

12. Báwo ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ṣe ń múra wa sílẹ̀ de ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?

12 Ọjọ́ pẹ́ tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti ń múra wa sílẹ̀ ká lè jẹ́ olóòótọ́ jálẹ̀ ìpọ́njú ńlá náà. (Mát. 24:45) Onírúurú ọ̀nà ni wọ́n ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ ẹ jẹ́ ká wo ọ̀kan lára wọn, ìyẹn àwọn àpéjọ agbègbè tá a ṣe lọ́dún 2016 sí 2018. Láwọn àpéjọ yẹn, wọ́n gbà wá níyànjú láti túbọ̀ láwọn ànímọ́ táá jẹ́ kígbàgbọ́ wa lágbára bí ọjọ́ Jèhófà ṣe ń sún mọ́lé. Ẹ jẹ́ ká tún ṣàyẹ̀wò àwọn ànímọ́ náà ní ṣókí.

JẸ́ ADÚRÓṢINṢIN, MÁA FARA DÀ Á NÌṢÓ, KÓ O SÌ NÍGBOYÀ

Ìsinsìnyí ni kó o ti múra sílẹ̀ láti la “ìpọ́njú ńlá” já (Wo ìpínrọ̀ 13 sí 16) *

13. Kí la lè ṣe táá jẹ́ ká túbọ̀ jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, kí sì nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀ báyìí?

13 Ìdúróṣinṣin: Àkòrí àpéjọ agbègbè ọdún 2016 ni “Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Jèhófà!” Ní àpéjọ yẹn, a kẹ́kọ̀ọ́ pé tá a bá ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà, a máa jẹ́ adúróṣinṣin láìka onírúurú àdánwò tó lè dé bá wa. Wọ́n rán wa létí pé tá a bá ń gbàdúrà tó nítumọ̀, tá a sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ìyẹn á sì jẹ́ ká lè borí àwọn àdánwò tó le gan-an. Bí ètò Sátánì ṣe ń lọ sópin, a mọ̀ pé a máa kojú àwọn àdánwò tó lágbára táá fi hàn bóyá a jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀. Ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn túbọ̀ máa fi wá ṣẹlẹ́yà lásìkò yẹn. (2 Pét. 3:3, 4) Ọ̀kan lára àwọn ìdí tí wọ́n sì fi máa ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a kì í ṣe ara wọn, a ò sì dá sí ohunkóhun tí wọ́n ń ṣe. Torí náà, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ pinnu pé àá jẹ́ adúróṣinṣin báyìí, kó lè rọrùn fún wa láti jẹ́ adúróṣinṣin nígbà ìpọ́njú ńlá.

14. (a) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú lórí ilẹ̀ ayé? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ adúróṣinṣin nígbà yẹn?

14 Lásìkò ìpọ́njú ńlá, ìyípadà máa wáyé sí àwọn tó ń múpò iwájú láàárín àwa èèyàn Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé. Tó bá di àkókò kan, àwọn ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé máa lọ sọ́run kí wọ́n lè kópa nínú ogun Amágẹ́dọ́nì. (Mát. 24:31; Ìfi. 2:26, 27) Ìyẹn túmọ̀ sí pé Ìgbìmọ̀ Olùdarí ò ní sí pẹ̀lú wa mọ́ lórí ilẹ̀ ayé. Síbẹ̀, ogunlọ́gọ̀ èèyàn ìyẹn àwa èèyàn Jèhófà ṣì máa wà létòlétò. Àwọn arákùnrin tó kúnjú ìwọ̀n lára àwọn àgùntàn mìíràn lá máa múpò iwájú. A gbọ́dọ̀ jẹ́ adúróṣinṣin, ká máa ti àwọn arákùnrin yìí lẹ́yìn, ká sì máa tẹ̀ lé gbogbo ìtọ́ni tí Jèhófà ń gbẹnu wọn fún wa. Ìyẹn ló máa jẹ́ ká là á já!

15. Kí lá mú ká túbọ̀ ní ìfaradà, kí sì nìdí tíyẹn fi ṣe pàtàkì báyìí?

15 Ìfaradà: Àkòrí àpéjọ agbègbè ọdún 2017 ni “Má Sọ̀rètí Nù!” Àpéjọ yẹn jẹ́ ká túbọ̀ mọ bá a ṣe lè fara da àwọn àdánwò tá a máa kojú. A kẹ́kọ̀ọ́ pé nǹkan ò rọrùn fún àwa Kristẹni, Jèhófà ló ń jẹ́ ká lè fara dà á. Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, á túbọ̀ rọrùn fún wa láti ní ìfaradà. (Róòmù 12:12) Ká máa rántí ohun tí Jésù ṣèlérí pé: “Ẹni tó bá fara dà á dé òpin máa rí ìgbàlà.” (Mát. 24:13) Ohun tí Jésù sọ yìí fi hàn pé a gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ láìka àdánwò tó lè dé bá wa. Tá a bá ń fara da àdánwò báyìí, àá túbọ̀ lókun kí ìpọ́njú ńlá tó dé.

16. Kí ló máa pinnu bá a ṣe máa nígboyà tó, kí sì nìdí tó fi yẹ ká sapá láti túbọ̀ jẹ́ onígboyà báyìí?

16 Ìgboyà: Àkòrí àpéjọ agbègbè ọdún 2018 ni “Jẹ́ Onígboyà!” Ní àpéjọ yẹn, a kẹ́kọ̀ọ́ pé kì í ṣe ọgbọ́n tàbí agbára wa ló máa fi hàn pé a jẹ́ onígboyà, bí kò ṣe àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run. Bó ṣe jẹ́ pé a gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ká tó lè ní ìfaradà, ohun kan náà ló máa gbà ká tó lè nígboyà. Kí lá jẹ́ ká túbọ̀ gbára lé Jèhófà? Ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, ká sì máa ṣàṣàrò lórí bí Jèhófà ṣe gba àwọn èèyàn rẹ̀ là nígbà àtijọ́. (Sm. 68:20; 2 Pét. 2:9) Nígbà táwọn orílẹ̀-èdè bá gbéjà kò wá nígbà ìpọ́njú ńlá, ó máa gba pé ká nígboyà ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ju ti ìgbàkigbà rí lọ. (Sm. 112:7, 8; Héb. 13:6) Tó bá ti mọ́ wa lára láti máa gbára lé Jèhófà báyìí, a máa nígboyà láti kojú Gọ́ọ̀gù nígbà tó bá gbéjà kò wá. *

Ẹ MÁA FAYỌ̀ RETÍ ÌGBÀLÀ YÍN

Láìpẹ́, Jésù àtàwọn ọmọ ogun ọ̀run máa pa àwọn ọ̀tá Ọlọ́run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì! (Wo ìpínrọ̀ 17)

17. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká bẹ̀rù Amágẹ́dọ́nì? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

17 Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ọ̀pọ̀ wa ló jẹ́ pé inú àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí la ti ṣe kékeré, ibẹ̀ náà la sì dàgbà sí. Àmọ́, a tún nírètí láti la ìpọ́njú ńlá náà já. Ogun Amágẹ́dọ́nì ló máa rẹ́yìn ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Síbẹ̀, kò sídìí tó fi yẹ ká bẹ̀rù. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìjà Ọlọ́run ni. (Òwe 1:33; Ìsík. 38:18-20; Sek. 14:3) Tó bá tó àkókò lójú Jèhófà, ó máa fún Jésù láṣẹ láti ṣáájú àwọn ọmọ ogun ọ̀run lọ sójú ogun náà. Òun àtàwọn ẹni àmì òróró tó ti jíǹde sọ́run àti ẹgbàágbèje àwọn áńgẹ́lì ló máa ja ìjà náà. Gbogbo wọn ló máa gbógun ti Sátánì, àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀.​—Dán. 12:1; Ìfi. 6:2; 17:14.

18. (a) Kí ni Jèhófà fi dá wa lójú? (b) Kí ni Ìfihàn 7:9, 13-17 sọ tó jẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú?

18 Jèhófà fi dá wa lójú pé: “Ohun ìjà èyíkéyìí tí wọ́n bá ṣe sí [wa] kò ní ṣàṣeyọrí.” (Àìsá. 54:17) “Ogunlọ́gọ̀ èèyàn” tó jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà máa la “ìpọ́njú ńlá náà” já, wọ́n á sì máa ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Jèhófà. (Ka Ìfihàn 7:9, 13-17.) Ẹ ò rí bí Bíbélì ṣe fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé ká má bẹ̀rù àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú torí a mọ̀ pé “Jèhófà ń dáàbò bo àwọn olóòótọ́.” (Sm. 31:23) Inú gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì ń yìn ín máa dùn nígbà tó bá sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́.​—Ìsík. 38:23.

19. Ọjọ́ ọ̀la àgbàyanu wo là ń retí láìpẹ́?

19 Ǹjẹ́ ẹ mọ bí ọ̀rọ̀ inú 2 Tímótì 3:2-5 ṣe máa kà tó bá jẹ́ pé àwọn tó wà nínú ayé tuntun tó ti bọ́ lọ́wọ́ Sátánì là ń sọ̀rọ̀ ẹ̀? (Wo àpótí náà “ Bí Àwọn Èèyàn Ṣe Máa Rí Nígbà Yẹn.”) Arákùnrin George Gangas, * tó ti fìgbà kan rí jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ pé: “Ẹ wo bí ayé ṣe máa dùn tó nígbà tí gbogbo èèyàn bá jẹ́ arákùnrin àti arábìnrin ẹ. Láìpẹ́ ìwọ náà máa láǹfààní láti wà nínú ayé tuntun. Bí Jèhófà ṣe wà láàyè títí láé nìwọ náà máa wà láàyè. Gbogbo wa pátá la máa wà láàyè títí láé.” Ẹ ò rí i pé ìrètí àgbàyanu nìyẹn!

ORIN 122 Ẹ Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin

^ ìpínrọ̀ 5 A mọ̀ pé láìpẹ́ “ìpọ́njú ńlá” máa dé bá gbogbo aráyé. Torí náà, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwa ìránṣẹ́ Jèhófà lásìkò yẹn? Kí ni Jèhófà máa fẹ́ ká ṣe nígbà yẹn? Àwọn ànímọ́ wo ló yẹ ká ní báyìí ká lè jẹ́ olóòótọ́ nígbà ìpọ́njú ńlá? A máa rí ìdáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí.

^ ìpínrọ̀ 3 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Kristẹndọm ni àpapọ̀ gbogbo ẹ̀sìn tó sọ pé Kristẹni làwọn, àmọ́ tí wọn ò kọ́ àwọn èèyàn ní ìlànà Jèhófà.

^ ìpínrọ̀ 11 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù (tàbí Gọ́ọ̀gù tá a bá ké orúkọ náà kúrú) ni àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè tó máa gbéjà ko ìsìn tòótọ́ nígbà ìpọ́njú ńlá.

^ ìpínrọ̀ 11 Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìjíròrò nípa àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ títí wọ ogun Amágẹ́dọ́nì, wo orí 21 nínú ìwé Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso! Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i nípa ìgbéjàko Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù àti bí Jèhófà ṣe máa gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀ nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, wo orí 17 àti 18 nínú ìwé Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!

^ ìpínrọ̀ 16 Àkòrí àpéjọ agbègbè ọdún 2019 ni “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé!” Àpéjọ yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa dáàbò bò wá láìka ohun yòówù ká kojú, mìmì kan ò sì ní mì wá.​—1 Kọ́r. 13:8.

^ ìpínrọ̀ 19 Wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ìṣe Rẹ̀ Ń Tọ̀ Ọ́ Lẹ́yìn” nínú Ilé Ìṣọ́ December 1, 1994.

^ ìpínrọ̀ 65 ÀWÒRÁN: Nígbà ìpọ́njú ńlá, àwọn Ẹlẹ́rìí mélòó kan lo ìgboyà, wọ́n sì ń ṣe ìpàdé nínú igbó.

^ ìpínrọ̀ 67 ÀWÒRÁN: Ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà máa la ìpọ́njú ńlá náà já, wọ́n á wà láàyè, wọ́n á sì máa láyọ̀!